A ní agbará láti figagbága pẹ̀lú àwọn òyìnbó – Akẹ́kọ̀ọ́ FUTA tó ṣe ẹ̀rọ́ sátáláìtì

Àkọlé fídíò, Akẹ́kọ̀ọ́ FUTA ṣe ẹ̀rọ́ sátáláìtì CanSAT
A ní agbará láti figagbága pẹ̀lú àwọn òyìnbó – Akẹ́kọ̀ọ́ FUTA tó ṣe ẹ̀rọ́ sátáláìtì

Awọn akẹkọọ fasiti imọ ẹrọ to wa niluu Akure, FUTA, ti ṣe ifilọlẹ imọ ẹrọ kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni CanSAT.

Ẹrọ satẹlaiti naa ni wọn ṣe lẹyin ti wọn lọ si idije CanSAT USA nilẹ Amẹrika.

Eto naa ti ajọ American Astronautical Society (AAS), ṣe onigbọnwọ rẹ ni wọn ti yege.

Awọn akẹkọọ FUTA mẹjọ ọhun ni akẹkọọ alawọ dudu akọkọ ti yoo kopa ninu rẹ ti wọn tun jẹ akẹkọọ to pegede julọ ninu idije ọhun.

Orukọ awọn akẹkọọ naa ni Alfred kareem; Oluwafemi Daramola, Oluwatosin Babalola, Ibrahim Lawal, Elijah Oyeleke, Oluwatimileyin Olowoyemo, Oluwadamilola Sunday ati Abolade Adetunji.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, ẹni to gbẹnusọ fun awọn akẹkọọ naa, Adetunji Ambode, sọ pe aṣeyọri naa fi han pe awọn ọmọ Naijiria ni ọpọlọ lati figagbaga pẹlu awọn alawọ funfun ni ẹka imọ ẹrọ.

O fi kun pe aṣeyọri naa tun fun Naijiria lanfani lati fi han pe Naijiria ni awọn ọmọ ti ori wọn pe daadaa.

Iṣẹ wo ni ẹrọ CanSAT naa n ṣe?

Gẹgẹ bii ohun ti akẹkọọ naa sọ, CanSAT naa wulo lati mu eto ibaraẹnisọrọ dara si.

Yatọ si eyii, wọn le maa lo o lati tubọ fun ẹrọ GPS lagbara lati mọ pato ibi ti nnkan ba wa.

Adetunji tun sọ siwaju si pe ẹrọ CanSAT ọhun wulo lati fun ẹrọ ayelujara lagbara si.

O pari ọrọ rẹ pe ẹrọ CanSAT ti wọn ṣe naa yoo wulo gẹgẹ bii ẹri fun awọn ti wọn ba pari ẹkọ wọn tan ti wọn si n wa iṣẹ.