Ìdí tí ìjọ Katoliiki ní Kenya ṣe kọ $40,000 tí Aarẹ Ruto fun wọn

Alufaa Philip Anyolo to ni ijọ yoo da owo ijọba pada.

Oríṣun àwòrán, @NAIROBIARCHDIO

Àkọlé àwòrán, Alufaa Philip Anyolo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọniloju nla lo ṣi n jẹ fun ọpọ eeyan to gbọ nipa bi ṣọọṣi Katoliiki lorilẹede Kenya, ṣe kọ owo to to ẹgbẹrun lọna ogoji dọla ( $40,000 ) ti Aarẹ William Ruto to ndari orilẹede naa fun wọn.

Bi a ba ṣi owo yii ni pọn-un, iye rẹ ni (£32,000). To ba si jẹ Naira, o din diẹ ni aadọrin miliọnu ni, #66,721,200.00 lo jẹ.

Aarẹ Ruto to fun ṣọọṣi lowo naa, sọ pe ki wọn fi kọ ile ti alufaa kan yoo maa gbe, ko si tu jẹ ẹbun fun awọn akọrin ijọ ni.

Asiko ti wọn n ṣe isin lọjọ Aiku, ni ijọ Aguda ti a tun mọ si Katoliiki, ni Soweto, Nairobi ti i ṣe olu ilu Kenya ni Aarẹ Ruto fi ẹbun naa ta wọn lọrẹ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹbun owo nla naa wọle lẹyin ti ijọ yii ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu ijọba pe wọn ko mu ileri ti wọn ṣe lasiko ipolongo ibo ṣẹ.

Bakan naa ni ẹnu ti n kun ọpọlọpọ ṣọọṣi ṣaaju asiko yii ni Kenya.

Awọn ajafẹtoọ lo n fẹsun kan wọn, pe wọn ti n sunmọ ijọba ju ṣiṣe iṣe Oluwa ti wọn gbe dani lọ.

Lẹyin owo nla ti Aarẹ Ruto fun ijọ yii, ọpọ ọmọ Kenya lo rọ ṣọọṣi lati da a pada sibi to ti wa.

Owo kiṣi to to 2.6m shillings ($20,000, £16,000) ti wọn n na ni Kenya, ni Aarẹ Ruto ko kalẹ ni ṣọọṣi lasiko isin ọhun, o si ṣeleri pe oun yoo fi iyooku ranṣe.

Bẹẹ lo tun ṣeleri ọkọ bọọsi fun ijọ bii afikun ọrẹ.

Ṣugbọn Alufa agba ijọ Katoliiku ni Nairobi, Philip Anyolo, ti sọ pe awọn yoo da owo naa pada nitori ẹtọ awọn ko gba a.

Alufaa Anyolo sọ pe bawọn ba tọju owo yii sapo, awọn oloṣelu yoo maa lo awọn fun iṣẹ oṣelu ni.

Bakan naa lo ni awọn ko ni i gba awọn ẹ̀jẹ́ yooku ti Aarẹ jẹ́.

O lawọn yoo tun da 200,000 shillings, owo Kenya ti Gomina ipinlẹ Nairobi, Johnson Sakaja, fun ijọ pada pẹlu.

Gomina Sakaja naa ba Aarẹ Ruto kọwọrin wa sibi isin ọhun, wọn si jọ ṣe isin naa ni.

Àwọn ìdí mírán tí Katoliiki fi kọ owó ìjọba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ijọ Katoliiki lodi gan-an si lilo ile Oluwa fun ikowojọ tabi ikojọpọ awọn oloṣẹlu." Alufaa agba Anyolo lo ṣalaye bẹẹ.

O ni gbigba owo yii tako ikọni ile ijọsin Katoliiki, o si lodi si ofin ilẹ Kenya pẹlu.

O tilẹ tun jọ pe ibaṣepọ awọn oloṣelu ati awọn ṣọọṣi Kenya ti dinku ni pẹlu, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ida ọgọrin (80%) ninu ọgọrun-un (100%) ọmọ orilẹede Kenya ni wọn jẹ Kristẹni.

Ọdun kẹta sẹyin ni wọn fofin de awọn oloṣelu lati yee lo ori pẹpẹ ijọ nitori owo ti wọn fẹẹ fun sọọṣi.

Ṣugbọn awọn awoye kan sọ pe ajọṣepọ ṣọọṣi ati awọn oloṣelu Kenya ko dinku kankan.

Wọn ni eyi ni awọn ọdọ ajijagbara ṣe maa n bu ẹnu atẹ lu awọn ijọ naa.

Ti wọn n fẹsun kan wọn pe ṣọọṣi n ṣe ọrẹ ijọba to n fi kun owo ori ti araalu n san.

Akọle kan tiẹ wa lori ayelujara, eyi ti wọn pe ni #OccupyChurch, nibi ti ọpọ eeyan ti n koro oju si awọn ile ijọsin naa pe wọn ko gbeja araalu.

Ariwo naa lo mu Aarẹ Ruto fagile aba kan to ni i ṣe pẹlu iṣuna owo loṣu Keje.

Awọn ọdọ Kenya fi ẹdun ọkan wọn han lori ajẹbanu, aisi-ibalẹ-ọkan, owo ori gọbọi, aisi iṣe niluu, aile sọ ero ọkan ẹni sita ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bakan naa ni wọn n koro oju sijọba lori aisi eto ilera to peye, eto ẹkọ to mẹhẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn nnkan wọnyi ni iroyin sọ pe ijọ Katooliki ro papọ, ti wọn fi gbe igbesẹ ati da owo ti wọn gba lọwọ ijọba pada fun un.

Pupọ ninu awọn Kristẹni Kenya ni wọn jẹ ọmọ ijọ Katoliiki, wọn fẹrẹ to miliọnu mẹwaa bi akọsilẹ ṣe sọ.

Wọn si to ida ogun (20%) ninu ọgọrun-un, bi a ba wo onka wọn lapapọ lorilẹede naa bi iwe ijọba wọn ṣe fidi ẹ mulẹ.