Àwọn agbébọn dáná sun oko, wọ́n tún jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé lọ

Àgbàdo tí wọ́n dáná sun

Oríṣun àwòrán, ALMUSTAPHA TUBALINMAGAMI

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn agbébọn ní ìpínlẹ̀ Zamfara ti dáná sun oko àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n sì tún jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn gbé lọ ní àwọn ìlú kan ní ìpínlẹ̀ náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, ìlú Farin Ruwa ní ìjọba ìbílẹ̀ Maru ní ìkọlù náà ti bẹ̀rẹ̀, táwọn agbébọn náà sì dáná sun oko àwọn àgbẹ̀ ọ̀hún.

Bákan náà ni wọ́n tún ṣèkọlù sáwọn èèyàn ní ìlú Wanke àti Zargada.

Àwọn olùgbé ìlú náà tó wà lẹ́bàá ẹnubodè ìpínlẹ̀ Kebbi ní àdánù ńlá ni àwọn agbébọn ọ̀hún kó bá ọrọ̀ ajé àwọn tó sì jẹ́ káwọn pàdánù èrè oko bíi àgbàdo, òwú, ẹ̀wà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Lára àwọn àgbẹ̀ tó bá BBC sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé agbébọn náà ló wá lọ́pọ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dáná sun àwọn oko tí àwọn gbin iṣu, ẹ̀wà, àgbàdo àtàwọn oúnjẹ mìíràn sí.

Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn agbébọn náà tún jí àwọn èèyàn gbé lọ lẹ́yìn tí wan jó oko àwọn tán.

“Ìyà ńlá ló ń jẹ wá níbí yìí, nígbàkígbà tí ìkọlù bá wáyé báyìí ni wọ́n máa ń ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn.”

Ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó bá BBC sọ̀rọ̀ sọ pé ìwà tí àwọn agbébọn náà ń hù sáwọn ní gbogbo ìgbà jẹ́ kí àwọn máa rí ara àwọn bí ẹni wí pé àwọn kìí ṣe ọmọ Nnàìjíríà.

Ó tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn agbébọn ọ̀hún tún jẹ gbogbo ẹran àwọn láì ní ìdí kan pàtó, táwọn kò sì ní nǹkan tí àwọn lè ṣe ju kí àwọn máa wòran ìgbèkùn táwọh agbébọn náà ń fi àwọn sí.

Ó fi kun pé èèyàn méje ni wọ́n jí gbé lọ lẹ́yìn tí wọ́n dáná sun oko àwọn.

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni àwọn agbébọn tún bẹ̀rẹ̀ sí ní dáná sun oko ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Ní àwọn agbègbè mìíràn, àwọn gbébọn náà máa sọ fún àgbẹ̀ láti dáwọ́ iṣẹ́ dúró, tí wọ́n yóò sì máa gba owó lọ́wọ́ wọn kí wọ́n tó lè tẹ̀síwájú iṣẹ́ wọn.

Láìpẹ́ yìí ni iú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní ìlú Birnin Gwarin, ìpínlẹ̀ Kaduna níbi tí àwọn agbébọn ti dáná sun oko tí iye rẹ̀ tó ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló ṣeéṣe kó fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ lẹ́kùn náà.

Pẹ̀lú gbogbo ìlérí àwọn ìjọba láti gbógunti ìwà lẹ́kùn náà, ojoojúmọ́ ni àwọn agbébọn túnbọ̀ ń ṣe ìkọlù pàápàá láwọn ìpínlẹ̀ bíi Zamfara, Katsina, Sokoto àti Kaduna.