Ataoja ìlú Oṣogbo, Ọba Jimoh Olanipekun, sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó ṣe ìwọ́de pé kó fi ipò sílẹ̀

Oba Jimoh Olanipekun

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ataoja ilu Oṣogbo, Ọba Jimoh Olanipekun, ti sọrọ lori iwọde kan to waye niluu Osogbo, pe ko fi ori itẹ silẹ gẹgẹ bi ọba.

Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ, ti wọn si ṣe iwọde kaakiri ilu, pẹlu oriṣiriṣi akọle lọwọ wọn.

Ninu awọn akọle naa lati ri eyi ti wọn kọ ọrọ si pe, awọn ko nii gba ki Ọba Olanipekun ba ọjọ iwaju ilu Oṣogbo jẹ.

Ṣugbọn ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, Ọgbẹni Bello Wasiu to jẹ akọwe fun Ọba Jimoh Olanipekun sọ pe, awọn ọlọtẹ, ti ko fẹ ijọba kabiyesi, lo wa nidii iwọde.

O ni lootọ ni awọn gbọ nipa ẹsun naa ṣáaju akoko yii, ṣugbọn awọn ti ọrọ kan ti jawe olubori nile ẹjọ.

O ṣalaye pe nigba ti kabiesi fi awọn eeyan kan jẹ oye, ni ọrọ naa kọkọ bẹrẹ, ti awọn ti inu n bi si lọ sile ẹjọ.

Ọgbẹni Bello sọ pe irọ patapata ni, pe kabiesi n fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu Osogbo joye tabi fi wọn jọba awọn ilu keekeeke to wa labẹ Osogbo, lẹyin to ba ti gba owo lọwọ wọn.

Awọn ẹsun ti wọn tun fi kan Ataoja, Ọba Jimoh Olanipekun

Awọn to n ṣe iwọde

Awọn eeyan naa to jẹ ọmọ ile ọba niluu Osogbo, wa lati ile bii marun un, lo pariwo sita pe ki araalu o gba wọn lọwọ Ọba Jimoh Olanipekun Ataoja ilu Osogbo, lori ẹsun pe o n fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu naa jẹ oye.

Wọn ni ki Ọba Olanipekun lati da wọ iwa ibajẹ ati iwa aijoniloju duro.

Awọn eniyan naa to wa lati awọn idile n to ma n jẹ ọba niluu Osogbo ni kabiyesi n wuwa ko si ẹni to le mu mi n to wu lati ma fi awọn ti kii ṣe ọmọ ilu ati awọn ti kii se ọmọ oye jẹ ọba ati oye miran lai fi to awọn leti rara.

Ẹnikan lara awọn eeyan naa, Ọmọọba Agboola Adejobi to jẹ arole oluawo, sọ fun BBC pe awọn ko ni laju awọn silẹ ki Ọba Jimoh Olanipekun, ba iluOsogbo jẹ patapata pẹlu iwa ibaje ti o n hu kaakiri lati ma fi alejo jọba lori onile.

Awọn to n ṣe iwọde

Ọgbẹni Adejobi tun tẹsiwaju wi pe, gbogbo owo n to wọ aafin Ataoja lati ọwọ ijọba ati lati oke okun fun atunṣe ilu ati aafin, ni kabiyesi da si apo ara rẹ ti ko sí lo bo se tọ.

Ọmọ ọba Abdullatifu Akinyemi ni oun ti awọn fẹ ni ki ọba Jimoh Olanipekun fi ipo Ọba silẹ fun ẹni ti yoo tun iluu Osogbo ṣe, tabi ko dawọ iwa ibajẹ duro.

Akinyemi tun fi kun ọrọ wi pe, ọba naa ko tọ si ipo ọba rara.

"Ọba Jimoh Olanipekun dojuti gbogbo ọmọ bibi ilu Osogbo nipa iwa buruku to n hu lawujọ lati maa fi ori ade sagbe kaakiri.