Àwọn kókó ọ̀rọ̀ Tinubu lórí ìgbógun ti ebi àti ìṣẹ́ níbi àpérò ‘G20 Summit' ní Brazil

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
Aarẹ Bola Tinubu, ti gbe idanilẹkọọ kan kalẹ lori gbigbogun ti ebi ati iṣẹ.
Nibi ipade awọn olori orilẹ-ede 'G 20 Summit' to n waye niluu Rio de Janeiro, ni brazil, ni Tinubu ti ṣe bẹẹ, to si fi iwe idanilẹkọọ ọhun si oju opo X rẹ.
Ninu ọrọ apilẹkọ ọhun ni aarẹ ti lu ijọba orilẹede Brazil lọgọ ẹnu lori ifilọlẹ eto to ṣe lati gbogun ti ebi ati iṣẹ lagbaaye.
Koko ọrọ Tinubu nibi apero ‘G20 Summit’ ni Brazil

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X
- Aarẹ Tinubu sọ nibi ipade naa wi pe igbesẹ ijọba orilẹede Brazil lati gbogun ti ebi ati iṣẹ lagbaaye jẹ ọna kan gboogi lati wa ojutuu si ọkan lara iṣoro to n koju gbogbo agbaye bayii.
- Tinubu ni ifilọlẹ eto yii jẹ aṣeyọri nla lori akitiyan awọn orilẹede agbaye lati jẹ ki ebi ati iṣẹ di ohun igbagbe.
- Bakan naa ni aarẹ Naijiria tun sọ pe ifilọlẹ eto ọhun yoo tun fawọn eeyan ti iṣẹ ati oṣi n ba a finra lagbaaye ni ireti.
- Aarẹ Naijiria ni ibasẹpọ ti eto naa yoo mu wa laarin awọn ijọba orilẹede, awọn ajọ ti kii ti ṣe ti ijọba atawọn ajọ mii yoo ṣe iranwọ lati wa ojutuu si ebi ọpagba to n ba ọpọ eeyan finra laye.
- Tinubu fikun ọrọ rẹ pe eto naa yoo tun ṣe iranwọ lati ṣe iwadii ohun to n ṣokunfa ebi ati iṣẹ gan an lagbaaye.
- Tinubu ni ‘’eto gbigbogun ti ebi ati iṣẹ ti ijọba orilẹede Brazil ṣe ifilọlẹ rẹ wa ni ibamu pẹlu awọn oniruuru eto ti ijọba Naijiria n ṣe fun itaji ọrọ aje rẹ.
- Koko nnkan mẹjọ ni mo ṣe agbekalẹ rẹ nigba ti mo de ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.
- Ẹkẹta ninu awọn nnkan mẹjọ yii da lori igbelarugẹ eto ọgbin ki ounjẹ le pọ si ni Naijiria.’’
- Tinubu ni labẹ eto yii naa ni ijọba oun ti gbero lati pese ohun amayedẹrun fawọn agbẹ.
- Aarẹ Naijiria tun sọ nibi apero ‘G20 Summit’ niluu Rio de Janeiro pe nnkan kẹfa ti ijọba oun gbajumọ ni ipese eto ẹkọ to ye koororo, eto ilera to peye ati eto iranwọ fawọn ti ko rọwọ họri lawujọ.
- Tinubu ni igbesẹ ijọba oun lati tẹle ifilọlẹ eto gbigbogun ti ebi ati iṣẹ ti Brazil ṣe jẹ ọna kan gboogi lati wa ojutuu si oṣi to n ba ọpọ ọmọ Naijiria finra.
- Aarẹ Tinubu ni kikopa oun ninu ipade awọn olori orilẹede G20 ni Brazil wa ni ibamu pẹlu erongba lagbaaye lati fopin si ebi ati iṣẹ eyi to si jẹ ọkan lara afojusun ijọba orilẹede Naijiria naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Kí ni G20 tumọ si?
G20 ni ẹgbẹ kan ti eeyan ogún wa ninu rẹ.
Wọn jẹ orilẹede ogún ti wọn maa n pade, ti wọn maa n jiroro lorii ọrọ aje agbaye.
Awọn ọmọ ẹgbẹ G20 ni: Argentina, Australia, Brazil, Canada, China, France, Germany, India, Indonesia, Italy, Japan, Mexico, Russia, Saudi Arabia.
Awọn yooku ni South Africa, South Korea, Turkey, UK ati US, African Union ati European Union.
Wọn maa N pe Spain naa wa bi alejo.
Lọdun yii, Aarẹ Bola Tinubu lọ si ipade naa pẹlu ipe ẹni pataki lati ọhun, iyẹn Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva,to ri gba lati wa.
Awọn orilẹede kan naa wa ti wọn kora wọn jọ ni kẹjẹbu lati ara G20 yii, ti wọn pe ara wọn ni G7.
Awọn kan lara G20 yii naa tun kora wọn jọ, wọn pe ara wọn ni Brics.
Awọn wọnyi ni- Brazil, Russia, India, China ati South Africa.












