Kókó mẹ́rin tó jẹyọ nínú àbẹ̀wò olóòtú ìjọba India, Narenda Modi, si Tinubu

Olootu ijọba India, Narenda Modi ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, X/Presidency

Àkọlé àwòrán, Olootu ijọba India, Narenda Modi ati Aarẹ Bola Tinubu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orilẹede Naijiria ati India ti ṣeleri lati jọ ṣiṣẹ pọ fun idagbasoke ọrọ aje, eto aabo, ilera ati anito ounjẹ.

Ilu Abuja ni ọrọ ileri naa ti waye laaarin Aarẹ Bola Tinubu ati Olootu ijọba ilẹ India, Narenda Modi, ẹni to ṣabẹwo si Naijiria ati Tinubu.

Lati oṣu Kẹwaa, ọdun 2007, ọdun kẹtadinlogun sẹyin ti Olootu ijọba India tẹlẹ, Manmohan Singh, ti ṣabẹwo si Naijiria, ko si olori kankan to tun wa lati India si Naijiria mọ ju Narenda Modi to ṣẹṣẹ wa yii lọ.

Ṣugbọn lapapọ, Modi ni Olootu ijọba India kẹrin to wa si Naijiria.

Lasiko abẹwo naa, awọn olori mejeeji tun fi ẹnu ko lati jọ ṣiṣẹ lẹka irinna oju omi ati bi wọn yoo ṣe dena awọn agbesunmọmi.

Mẹ́rin rèé nínú àdéhùn náà

Ètò ààbò

Nitori idunkooko to n waye laaarin Guinea ati agbami okun India, India Gulf, orilẹede Naijiria ati India ni awọn yoo jọ wa ọna ti aabo to peye yoo fi wa fun awọn arinrin ajo oju omi naa, ati ọna ti wọn yoo fi dẹkun iṣẹ awọn ole ori omi.

Atẹjade to ti ọfiisi Aarẹ Tinubu jade, ṣalape pe, awọn olori orilẹ-ede mejeeji koro oju si idunkooko mọni ati bi awọn agbebọn ṣe n kọja lati orilẹede kan si omiran.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

'' Wọn pe fun ajọṣepọ awọn ajọ UN, lilo imọran UNGA ati ti UNSC lati ṣẹgun agbesunmọmi ati iwa ipa ọlọkan-o-jọkan."

Bakan naa ni wọn sọrọ nipa lilo afẹfẹ gaasi fun ọkọ ati ti LNG.

Naijiria ati India tun fẹnu ko lori ipese epo LNG, CNG ati LPG, to jẹ gaasi idana.

Ọrọ̀ ajé àti okòòwò

Aarẹ Tinubu ati Narenda jọ gba, pe orilẹede India ati Naijiria yoo jọ bẹrẹ okoowo ti yoo tun ọrọ aje ṣe.

Wọn ṣalaye bi India ṣe jẹ ọkan gboogi ninu awọn to n da ileeṣẹ silẹ ni Naijiria yii, ti ilu naa si n kopa tirẹ ninu idagbasoke ọrọ aje wa.

Naijiria gboriyin fun India, pẹlu bo ṣe jẹ pe ileeṣẹ wọn to wa lorilẹede yii le ni igba (200).

"Awọn ileeṣẹ naa n pese iṣẹ ati ọna atijẹ fun awọn eeyan Naijiria, o si n ṣe tiẹ ninu idagbasoke ọrọ aje."

Atẹjade ti India ati Naijiria buwọ lu lo kede bẹẹ.

Wọn fi ẹnu ko lati yanju awọn ajọsọ to wa nilẹ tẹlẹ nipa Economic Cooperation Agreement (ECA), Double Taxation Avoidance Agreement (DTAA), ati di Bilateral Investment Treaty (BIT), lati gbe okoowo larugẹ.

Olori ilẹ India ati Aarẹ Tinubu ati awọn meji miran lasiko ipade naa.

Oríṣun àwòrán, X/Presidency

Ètò ọ̀gbìn àti ìpèsè ànító oúnjẹ

Naijiria ati India, nipasẹ awọn olori wọn, gba lati ṣiṣẹ pọ lẹka ọgbin, wọn mu ẹnu ba awọn ẹka ọgbin to nilo ẹrọ igbalode ati ipese rẹ.

Bakan naa ni wọn sọrọ nipa bi wọn yoo ṣe pese awọn nnkan ọgbin ati fifi awọn imọ nipa ọgbin ṣọwọ sira ẹni.

Ètò ìlera àti ẹ̀kọ́

Orilẹede India ati Naijiria pa ẹnu pọ pe, awọn yoo ṣiṣẹ lorii bawọn ṣe le jọ kọ ileewosan, ibudo ayẹwo aisan abi ibi ti wọn yoo ti maa lo awọn irinṣẹ igbalode, fun ilera.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ilu mejeeji buwọ lu ṣe wi, " Igun mejeeji lo gba pe iṣẹ nla ni awọn ọsibitu India to n ṣiṣẹ ni Naijiria n ṣe. Wọn si foju sọna lati tun jọ maa ṣiṣẹ ju bẹẹ lọ."

Ijọba India gba lati pese eto ti yoo ran ẹka ilera Naijria lọwọ.

Lẹka ẹkọ iwe, India ati Naijiria ni awọn yoo jọ ro ẹka naa lagbara to yẹ ti yoo si pẹ.

Tinubu ati Modi sọrọ lori ẹkọ ọfẹ, ati bi yoo ṣe dara ju bayii lọ.

Awọn olori ilu mejeeji sọrọ nipa awọn ẹkọ ọfẹ ti India maa n fi sita.

Wọn panupọ gba awọn akẹkọọ Naijiria nimọran lati mu anfaani ẹkọ ọfẹ yiI ni koko, ki wọn si ṣisẹ debi ti anfaani naa ko fi ni i bọ mọ wọn lọwọ.

Lasiko ipade naa ni Aarẹ Tinubu fi oye Grand Commander Order of Niger, (GCON) da Olootu ijọba India Modi lọla.

Lẹyin to ba kuro ni Naijiria, Modi yoo morile Brazil, fun ipade G20 Summit ti yoo waye ni Rio De Janeiro, laaarin ọjọ kejiidinlogun ati ikọkandinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024.