Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Labour, ADP kọ èsì ìbò ìjọba ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Ogun State Govt
Awọn ẹgbẹ oṣelu alatako ni ipinlẹ Ogun ti ni awọn ko faramọ esi ibo ijọba ibilẹ ti ajọ eleto idibo ipinle naa, OGSEIC kede rẹ pe awọn oludije lẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ni gbogbo ìjọba ibilẹ ogún ti o waye ni ọjọ Abameta, ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla.
Akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP ni Ipinlẹ Ogun, Ọmọwe Sunday Solarin tí o fi aidunnu rẹ han nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe bí ẹni fowo ṣofo laasan ni eto idibo tí ajọ OGSEIC ṣe naa.
Ọmọwe Solarin ni ẹgbẹ́ oṣelu PDP kọ esi idibo naa, o bẹnu atẹ lu ẹgbẹ́ oṣelu APC ati eto iṣejọba gomina Dapo Abiodun ti o si fẹsun kan pe gomina Abiodun lẹdi apo pọ pẹlu ajọ OGSEIC lati ṣe eeru ninu eto idibo ijọba ibilẹ naa.
Bakan naa ni ọmọ ṣori nigba ti alaga ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Onimọ ẹrọ Lookman Jagun pe fun atundi eto idibo ijọba ibilẹ naa latari aiṣe dede latọwọ ajọ OGSEIC lasiko eto idibo ọhun.
Oludije sipo alaga ijọba ibilẹ Guusu ipinlẹ Ogun lẹgbẹ oṣelu ADP, Oloye Alexander Olalekan shoyinka ni tirẹ woye pe esi idibo ti ajọ OGSEIC kede ko si ni ibamu pẹlu eto idibo to waye lọjọ Abamẹta.
Shoyinka ṣapejuwe eto idibo ijọba ibilẹ naa bii igba ti ole ba ja eeyan mọjumọ.
Ẹ̀wẹ̀, oludamọran fun gomina ipinlẹ Ogun lori eto iroyin ati ọrọ ara ilu, Ọgbẹni Rotimi Akinmade sọ fun BBC News Yoruba pe ijawe olubori ẹgbẹ oselu APC ni gbogbo ijọba ibilẹ ogun to wa ni ipinlẹ naa ko ṣẹyin awọ iṣẹ ribiribi ti gomina Dapo Abiodun n gbe ṣe lati igba ti o ti de ori ipo.
O rọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako lati fọwọsowọpọ pẹlu iṣejọba gomina Dapo Abiodun atawọn alaga ijọba ibilẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati mu ipinlẹ Ogun de ileri ogo.
APC ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò alága ìpínlẹ̀ Ogun ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun/X
Ajọ eleto idibo ipinle Ogun, OGSEIC, ti kede ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu ibo alaga ati kansilọ ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ naa.
Alaga ajọ OGSEIC, Ọgbẹni Babatunde Oshinbodu, kede pe awọn oludije sipo alaga ati kansilọ ẹgbẹ APC lo bori ni gbogbo wọọdu 236 ti eto idibo naa ti waye lana ọjọ Abamẹta nipinlẹ Ogun.
Alaga OGSEIC ti wa sọ pe APC gba ẹyẹ lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu mii bii PDP, Labour LP, ADC, NNPP ati awọn ẹgbẹ mii tawọn naa kopa ninu eto idibo ọhun.
Alaga ajọ OGSEIC ti wa kede wi pe lonii ọjọ Aiku ni ajọ naa yoo fun gbogbo awọn alaga ayi kansilọ to jawe olubori ninu eto idibo naa ni iwe ẹri moyege ni olu ileeṣẹ ajọ ọhun to wa niluu Abeokuta.















