Ṣé lóòótọ́ nílé ẹjọ́ fagilé ìbò MC Oluomo gẹ́gẹ́ ààrẹ ẹgbẹ́ NURTW ní Naijiria?

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo/Instagram
Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ni iroyin kan jade pe ile ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja ti fagile eto idibo to gbe Alhaji Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo wọle gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ onimọto, NURTW ni Naijiria.
Iroyin naa tun sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu Alhaji Tajudeen Ibikunle Baruwa gẹgẹ bi ojulowo aarẹ ẹgbẹ naa.
Gẹgẹ bi iroyin naa ṣe sọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu idajọ ile ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ eyi to kede Alhaji Baruwa gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ NURTW.
Ile ẹjọ kotẹmilọrun dajọ pe ẹjọ ti Ọgbẹni Najeem Usman Yasin, Tajudeen Agbede atawọn mii pe tako idajọ ile ẹjọ to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ ko lẹsẹ nlẹ.
Ṣaaju ipo tuntun yii ni Oluomo ti kọkọ ṣe alaga ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Eko fun ọpọ ọdun, ti irawọ rẹ si kan kaakiri Naijiria.
Awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ nilẹ Yoruba lati ipinlẹ Eko, Ogun, Ondo ati Ekiti lo kopa ninu eto idibo naa.
Asiko ti wọn n ṣe ipade ẹgbẹ naa to maa n waye lẹẹkan laarin ọdun merin ni eto idibo naa waye, ti Aarẹ fidihẹ ẹgbẹ ọhun, Aliyu Issa-Ore, si boju to o.
"Irọ nla ni pe ile ẹjọ fagile ibo MC Oluomo gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ NURTW’"
Ẹwẹ, adari ajọ awọn agbaagba ati oludamọran fun MC Oluomo ni ẹkun iwọ-oorun guusu Naijiria, Alhaji Moshood Ajao, ti sọ pe irọ nla ni iroyin to ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti fagile ibo MC Oluomo gẹgẹ bi aarẹ ẹgbẹ NURTW.
Alhaji Ajao fọrọ naa lede loju opo Instagram MC Oluomo ni irọlẹ ọjọ Abamẹta.
O ṣalaye wi pe awọn aṣoju ẹgbẹ onimọto lo dibo yan Alhaji Akinsanya lọjọ kẹsan an, oṣu Kọkanla ninu eto idibo to waye niluu Osogbo.
Alhaji Ajao fikun ọrọ rẹ pe ko si ẹni kankan to pẹjọ kotẹmilọrun lori eto idibo naa.
O ni MC Oluomo funra rẹ ko lọ sile ẹjọ kankan.
Alhaji Ajao ni ọjọ kẹjọ oṣu Kọkanla ni ile ẹjọ kotẹmilọrun gbe idajọ rẹ kalẹ, nigba tawọn aṣoju ẹgbẹ onimọto dibo yan Alhaji Akinsanya gẹgẹ bi aarẹ NURTW tuntun lọjọ kẹsan an.
Oludamọran MC Oluomo sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW, papaa julọ awọn aṣoju to kopa ninu eto idibo naa ti fi mọ MC Oluomo funra rẹ ko mọ ohun kan nipa idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lasiko eto idibo naa.
Alhaji Ajao ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ẹgbẹ NURTW ni ẹjọ kan nile ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ṣaaju ninu ọdun 2024 yii, amọ, o ni ẹjọ naa ko kan MC Oluomo rara.
Oludamọran MC Oluomo ṣalaye pe igbesẹ lati dibo yan Alhaji Akinsanya gẹgẹ aarẹ ẹgbẹ NURTW da lori ọna lati wa alaafia sinu ẹgbẹ naa tori MC Oluomo ko si lara awọn to n fa aawọ pẹlu ara wọn nile ẹjọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















