MC Oluomo di alága ẹgbẹ́ NURTW káàkiri Naijiria

MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, MC Oluomo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ awọn awakọ ero ni Naijiria, NURTW, ti dibo yan Musiliu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ naa ni Naijiria.

Ṣaaju ipo tuntun yii ni Oluomo ti kọkọ ṣe alaga ẹgbẹ ọhun nipinlẹ Eko fun ọpọ ọdun, ti irawọ rẹ si kan kaakiri Naijiria.

Ninu eto idibo ti wọn ti yan an sipo alaga gbogbogbo yii to waye lọjọ Abamẹta niluu Eko, oun nikan ṣoṣo ni oludije to dije du ipo naa ti ẹlomiran ko s iba figagbaga.

Awọn aṣoju ẹgbẹ awakọ nilẹ Yoruba lati ipinlẹ Eko, Ogun, Ondo ati Ekiti lo kopa ninu eto idibo naa.

Asiko ti wọn n ṣe ipade ẹgbẹ naa to maa n waye lẹẹkan laarin ọdun meorin ni eto idibo naa waye, ti Aarẹ fidihẹ ẹgbẹ ọhun, Aliyu Issa-Ore, si boju to o.

Nigba to n sọrọ, Issa-Ore sọ pe gẹgẹ bii ofin ẹgbẹ naa ṣe sọ, awọn eeyan ẹkun ti ipo a”laga ba kan lo maa dibo ti wọn yoo si fa ẹni ti wọn ba dibo yan le gbogbo ẹgbẹ naa lọwọ lati maa dari wọn.

O ni “Awọn ọmọ ẹgbẹ wa ni ekun iwọ oorun ti ṣe ohun to tọ gẹgẹ bii alakala ofin ẹgbẹ wa.”

Nibi eto idibo naa ni wọn tun ti yan Tajudeen Agbede, gẹgẹ bii igbakeji Aarẹ ni ẹkun iwọ oorun.

Ni kete ti wọn burawọle fun tan ni MC Oluomo, ti awọn ololufẹ rẹ rọgba yika sọ fun awọn eeyan naa ki wọn ṣiṣẹ papọ, ki wọn si gba alaafia laaye ninu ẹgbẹ ọhun.

O ni “Mo ti dariji gbogbo awọn to ṣẹ mi, mo si ke si gbogbo awọn ti mo ti ṣẹ ki awọn naa dariji mi.”

Lẹyin naa lo dupẹ lọwọ Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, fun atilẹyin rẹ, o tun dupẹ lọwọ awọn gomina ipinlẹ Eko, Ondo ati Ekiti fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu.