Wo bí o ṣe lè fi èso yìí ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ, ìtọ̀ ṣúgà àti àwọn míràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yatọ si ka lo oogun oyinbo lati kapa awọn aisan aṣekupani to wọpọ laye ode oni, awọn iṣẹ Ẹlẹdaa kan wa ti wọn jẹ ohun jijẹ ti wọn si kun fun iwosan.
Lara awọn nnkan ti Iṣẹda gbe kalẹ bẹẹ ni eso kan ti oyinbo n pe ni Soursop.
Awọn kan n pe e ni eso Ibobo nilẹẹ Yoruba, ẹya Igbo n pe ni ‘Shawansop.
Awọn kan tun mọ ọn si African custard-apple, bẹẹ ni awọn mi-in n pe e ni Wild custard apple tabi Wild soursop. Awọn ẹya yooku naa ni orukọ ti wọn fun un.
Awọ ewe ni eso yii ni, bẹẹ ni ara rẹ ṣe ṣukuṣuku.
Awọ funfun lo wa ninu rẹ ti eeyan ba la a, o dun, o si ni awọn horo ninu.
Eso Soursop ni awọn onimọ nipa ounjẹ ti fidi rẹ mulẹ, pe o daa fun awọn eeyan to ba ni jẹjẹrẹ, itọ ṣuga, ifunpa giga ati bẹẹ bẹẹ lọ lati maa jẹ.
Bẹẹ ni wọn sọ pe o tun daa fun ẹni ti ko ni awọn aisan yii naa, lati dena awọn aisan aṣekupani.
Àǹfààní Soursop

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onimọ nipa ounjẹ, Gideon Bassey, ṣalaye fun BBC pe eso Soursop da fun awọn eeyan to ba ni jẹjẹrẹ ati itọ ṣuga lati maa jẹ.
O ni wọn le se ewe rẹ gẹgẹ bi agbo pẹlu, ki wọn maa yọ ọ mu.
Bassey ṣalaye pe ṣuga ko si ninu eso yii, bo tilẹ jẹ pe o maa n dun yungba lẹnu.
Eyi lo ni o ṣe daa ti ko si lewu fun awọn to ba ni aisan itọ ṣuga.
‘’Eso Soursop n ṣiṣẹ fun ibi to ba wu ninu ara (tumor).
Yoo gbẹ apa ibẹ, ko si ni i jẹ ki jẹjẹrẹ maa tan kalẹ ninu ara.
‘’Eroja Vitamin C wa ninu rẹ, o n ṣiṣẹ fun ki oju egbo tete san.
Bẹẹ lo tun ni ohun ti a mọ si ‘anti-oxidants’, to n daabo ba ara to si n tun awọn iṣan ara ṣe.
‘’Bi eeyan ba ni aisan ọgbẹ inu(ulcer) soursop daa fun un lati maa jẹ.
Bi eeyan ko ba ni jẹjẹrẹ tabi itọ ṣuga, eeyan le maa jẹ Soursop pẹlu lati ro ara lagbara.
Awọn fitamin aṣaraloore bii Vitamin B ati awọn mi-in ni wa ninu rẹ.’’
Onimọ nipa ounjẹ, Gideon Bassey, lo ṣalaye bẹẹ.
Àwọn nǹkan mí-ìn tí èso yìí tún dáa fún
*Ifunpa to ṣe deede
* Dida aabo bo inu
*Riro awọn ṣọja ara lagbara.
*Gbigbogunti airi igbọnsẹ ṣe.
*Iriran kedere.
*Didena awọn aisan bii ara riro,ikọ, aisan awọ ara, ai-le-mi daadaa ati bẹẹ bẹẹ lọ.














