'Ẹ fura o! Àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ rèé tí Dangote bá di aláṣẹ epo rọ̀bì'

Aliko Dangote

Oríṣun àwòrán, Aliko Dangote @X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ileeṣẹ mẹta kan ti wọn jẹ alagbata epo ni Naijiria, ti bẹ kootu lọwẹ lati ma ṣe gba fun ileeṣẹ ifọpo Dangote lati di apaṣẹ lẹka epo rọbi ilẹ wa.

Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ni awọn alagbata epo bii AYM Shafa Limited, A. A. Rano Limited ati Matrix Petroleum Services Limited ti fesi fun Dangote.

Wọn ni wahala nla ni yoo ba ẹka epo orilẹede yii, bi Dangote nikan ba n ta epo.

Wọn fi kun un pe ere ti ileeṣẹ Dangote yoo jẹ lo jẹ ẹ logun, bẹẹ ọrọ epo Naijiria kuro ni ohun ti ileeṣẹ kan ṣoṣo yoo da aya kọ.

Ṣe ṣaaju ni ileeṣẹ elepo Dangote ti fẹsun kan awọn alagbata yii, pe wọn ko lẹtọọ lati maa ta epo nigba ti ki I ṣe pe ileeṣẹ Dangote ko ni epo to.

Bakan naa ni Dangote pe NNPC ati NMDPRA, (Nigeria Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority) lẹjọ, pe wọn fun awọn alagbata yii laṣẹ lati maa ta epo.

Kí ni iléeṣẹ́ Dangote ń fẹ́?

ileeṣẹ ifọpo

Oríṣun àwòrán, Others

Ninu ẹjọ ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/1324/2024, ni ileeṣẹ elepo Dangote ti sọ fun kootu pe ko yẹ ki NNPC ati NMDPRA fun awọn alagbata yii ni iwe aṣẹ epo tita ni Naijiria.

Awijare Dangote ni pe anito ati aniṣẹku epo loun n pese, oun ko ja araalu kulẹ ki epo ma si ri.

Fun idi eyi, o ni ki kootu gba iwe aṣẹ ita epo awọn alagbata yooku.

Iwe ipẹjọ Dangote sọ ọ di mimọ, pe NMDPRA ti lodi si ofin 317, abala kẹjọ ati ikẹsan-an to de gbigbe epo wọ Naijiria, pẹlu bi wọn ṣe tun fun awọn mi-in ni iwe aṣẹ lati maa gbe epo wọle lati oke okun.

Ileeṣẹ Dangote sọ pe boun ṣe n pese epo AGO ati eyi ta a mọ si Jet-A1 to, to tiẹ pọ ju ohun ti Naijiria nilo lọ, sibẹ, wọn tun lọọ n fun awọn mi-in laṣẹ tita epo.

Dangote waa loun fẹ ki kootu paṣẹ pe ki NMDPRA san ọgọrun-un kan biliọnu naira (N100billion) owo itanran.

O ni eyi wa fun bi wọn ṣe fun NNPCL ati awọn mi-in laṣẹ ati maa ta epo mọto ati eyi ti baaluu n lo.

Bakan naa ni ileeṣẹ Dangote fẹ ki kootu fofin de awọn olujẹjọ lati ma ṣe sọ iwe aṣẹ wọn di ọtun (renew).

O ni ki kootu si di awọn tanki epo ati aaye ti wọn n ko epo si pa pẹlu.

‘Orí ọmọ Naijiria yóò wà lábẹ́ Dangote ni tí ohun tó ń fẹ́ bá fi wá sí ìmúṣẹ’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaa, nigba ti wọn n tako ẹbẹ Dangote, awọn alagbata naa sọ fun kootu pe ọmọ Naijiria ko ni i bọ lọwọọ Dangote, to ba fi le di alaṣẹ epo nikan.

Ninu ẹjọ naa ti wọn gbọ lọjọ karun-un, oṣu kọkanla ọdun 2024, awọn alagbata ṣalaye pe epo ti Dangote n pese ko to ohun ti ọmọ Naijiria nilo.

Wọn ni ko si id ikan fun un ti yoo fi fẹẹ maa da ta epo fun gbogbo ilu, nigba ti agbara rẹ ko gbe e.

Wọn ni loootọ ni ko si alakara to n fẹ ki ẹnikeji din, ṣugbọn bii ti epo rọbi Naijiria kọ.

Awọn olujẹjọ sọ pe ko ni i si aaye fun idunaa-dura bi Dangote ba di alaṣẹ epo bo ṣe n fẹ.

Wọn ni iye to ba wu u ni yoo maa ta a, awọn eeyan ko si ni I ri ibo mi-in lọ lati ra epo.

Bi wahala kan ba ṣẹlẹ si ileeṣẹ ileepo kan ṣoṣo ti Dangote ni, idaamu ti ko lẹgbẹ ni yoo ko ba awọn eeyan Naijiria, gẹgẹ bi awọn alagbata epo naa ṣe ṣalaye fun kootu.

Wọn ni Dangote ko le da ẹru naa gbe fun ọgbọn ọjọ, ti yoo fi mọ pe kekere kọ ni ọrọ epo rọbi lorilẹ-ede yii.

Wọn ni iwe aṣẹ awọn ko di ti Dangote lọwọ, ki kaluku ṣe tiẹ lai ni ẹnikan lara.

Adajọ Inyang Ekwo, sun igbẹjọ si ogunjọ, oṣu Kin-in-ni ọdun 2025.

Adajọ ni oun ṣe eyi ki olupẹjọ ati awọn olujẹjọ le ba ara wọn sọrọ, boya yoo ṣee ṣẹ ki wọn yanju rẹ laarin ara wọn lai jẹ pe kootu da si i.