Iléeṣẹ̀ ìfọpo Dangote kéde iye tó ń ta jálá epo kan èyí tó ní ó dínwó ju owó epo tó ń wá láti òkè òkun

Oríṣun àwòrán, X/DangoteGroup
Ileeṣẹ ifọpo Dangote ti kede iye owo to n ta epo bẹntiroolu fun awọn onibaara rẹ.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa fi lede sori ayelujara, o ni N990 ni awọn n ta jala epo fun awọn tanka epo, ti oun si n ta fun ọkọ oju omi ni N960.
Ọrọ yii lo jade sita lẹyin ọrọ kan ti awọn ẹgbẹ alagbata epo bẹnitiroolu lorilẹede Naijiria, IPMAN ati PETROAN sọ pe gbigbe epo wọle lati oke okun ko gbe owo lori to ti Dangote.
Awọn alagbata ninu ifọrọwerọ kan ti wọn ṣe, wọn ni awọn n ra epo bẹnitiroolu lati oke okun ni owo ti ko ga ju ara lọ, ti wọn si rọ Dangote lati awọn eekan ninu iṣẹ naa sọrọ.
"Ti ẹnikẹni ba sọ pe wọn ra epo ni owo kekere ju ohun ti a n ta lọ, epo ti ko da rara ni wọn gbe wọle fun awọn araalu"
Nigba ti yoo fesi pada, ileeṣẹ ifọpo Dangote, ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Anthony Chiejina gbe sita sori ayelujara ṣalaye pe awọn epo ti ko koju oṣuwọn nikan ni wọn n ta fun awọn alagbata ni owo kekere.
Chiejina ni gbogbo ilana NNPC ti wọn gbEkalẹ ni awọn tẹle, ti awọn si tun mu adikun ba iye owo epo naa.
“Awọn ẹgbẹ mejeeji yii ni awọn n ra epo ni owo ni oke okun yatọ si iye ti Dangote n ta.
“Ti ẹnikẹni ba sọ pe wọn ra epo ni owo kekere ju ohun ti a n ta lọ, epo ti ko da rara ni wọn gbe wọle fun awọn araalu, ti wọn ko si ro akoba to le se fun ilera awọn araalu ati si ọkọ ayọkẹlẹ wọn.
“O se ni laaanu pe orilẹede Naijiria ko ni ẹrọ to n se iwadi epo lati mọ eyi to da ti wọn ba n gbe wọle si orilẹede Naijiria.
“Pẹlu igbagbọ rere ati ifẹ ti a ni si orilẹede Naijiria, a n ta epo wa ni owo to yẹ lai wo iye owo ilẹ okere ti a fi n ra awọn elo epo bẹntiroolu yii.
“A o tẹsiwaju lati san ta epo to dara, ti a si rọ awọn araalu lati yago fun awọn iroyin ẹlẹjẹ ti awọn eeyan kan n gbe kiri
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















