Alága ìjọba ìbílẹ̀ Onigbongbo l’Eko Tant’olorun jáde láyé lẹ́ni ọdún 54, Sanwo-Olu ń ṣèdárò

Aworan Họnọrebu Oladotun Olakunle

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Alaga ijọba ibilẹ LCDA Onigbongbo nipinlẹ Eko, Họnọrebu Oladotun Olakunle, ti jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaadọta.

Alaga ọhun ti ọpọ eeyan mọ si Tant’olorun ni a gbọ pe o dagbere faye lọjọ Abamẹta, ọjọ keji oṣu Kọkanla yii lẹyin aisan ranpẹ.

Ọkunrin yii ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe o faye silẹ nigba ti ọjọ ibi ọdun karunlelaadọta rẹ n bọ lọna.

Ni nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin ni alaga ijọba ibilẹ Onigbongbo tẹlẹ, Họnọrebu Babatunde Oke jẹ Ọlọrun nipe lẹyin to lugbadi arun covid-19 ti Tant’olorun si rọpo rẹ.

Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko ti ranṣẹ ibanikẹdun sawọn eeyan ijọba ibilẹ Onigbongbo lori iku Họnọrebu Olakunle.

Ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ lọjọ Abamẹta, Sanwo-Olu ṣapejuwe iku Tant’olorun gẹgẹ bi adanu foun gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Eko ati fawọn eeyan ijọba ibilẹ LCDA Onigbongbo.

Sanwo-Olu ni oloṣelu to jẹ olufọkansin ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Ọgbẹni Olakunle jẹ nigba aye rẹ.

Gomina sọ pe ijọba ibilẹ Onigbongbo, ẹgbẹ oṣelu APC ati gbogbo ipinlẹ Eko ni yoo mọ iku Tant’olorun lara.

Sanwo-Olu fikun ọrọ rẹ pe Họnọrebu Olakunle ṣiṣẹ takun takun lati mu idagbasoke ba ijọba Onigbongbo nigba to wa lori oye.

O ni awọn iṣẹ to ṣe silẹ yii lawọn eeyan ijọba ibilẹ naa yoo fi maa ranti rẹ lẹyin to lọ tan.

Gomina ipinlẹ Eko wa gbadura pe ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post