"Ìjọba Naijiria ń fi ìyà jẹ ọmọdé lọ́nà àìtọ́, ó gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de tó wà látìmọ́lé sílẹ̀"

Amnesty International

Oríṣun àwòrán, Amnesty International

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International, ti ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko fi awọn ọmọde ti ijọba rẹ gbe lọ sile ẹjọ silẹ lẹyin to fẹsun kan wọn pe wọn kopa ninu iwọde ilu le ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2024.

Adari ajọ naa ni Naijiria, Malam Isa Sanusi, sọ fun BBC pe ijọba gbọdọ san owo gba mabinu fun awọn ọmọ naa latari iya to fi jẹ wọn lọna aitọ lati igba ti wọn ti wa ninu atimọlẹ lati oṣu Kẹjọ.

Sanusi sọ pe “O ṣeni laanu irufẹ ipo ti awọn ọmọde naa wa lọjọ Ẹti niluu Abuja.

“Ohun itiju nla gbaa ni bi wọn ṣe ṣe awọn ọmọde naa, a bu ẹnu atẹ lu fifi iya jẹ ọmọde.

“Eyi n fi han pe awọn ọmọde naa ko ni eeyan nitori pe awọn obi wọn ko rọwọ họri, idi ti wọn ṣe n fiya jẹ wọn ree.”

O ṣalaye pe ijọba n mọọmọ fi imu awọn ọmọde naa danrin lati ṣẹruba awọn mii ti wọn ba fẹ ṣewọde lọjọ iwaju ni.

O ni “Ohun ti ijọba ṣe fi han pe agbara ofin ni lati fi iya jẹ awọn ti ko lagbara atawọn ti ko ni eeyan.”

Olori ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan naa sọ siwajsu si pe ọrọ yẹyẹ ni ijọba sọ pe awọn ọmọde naa fẹ doju ijọba Naijiria bolẹ.

O ni “Awọn to fẹ doju ijọba Naijiria bolẹ wa ni Zamafara, Katsina, Sokoto, ati Kaduna nibi ti wọn ti n ji eeyan gbe ti wọn si n fi ipa ba awọn ọmọlọmọ lopọ.”

Ki ni ijọba sọ?

Ni bayii ti ọpọ araalu n bu ẹnu atẹ lu igbẹjọ awọn ọmọ naa, igbakeji Aarẹ ile aṣodin Naijiria, Barau Jibrin ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati gba itusilẹ awọn ọmọ naa.

Amọ ṣa, ṣaaju ni agbẹjọro ijọba apapọ, Emezonte Ezekiel, ti kọkọ sọ pe awọn ọhun kii ṣe ọmọde.

O ni irọ ni pe ọmọde ni awọn afurasi ọhun, koda o ni pupọ ninu wọn lo ti gbe iyawo silẹ, o si yẹ ki wọn jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Wayi o, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n sọko ọrọ si ijọba Naijiria lori igbẹjọ awọn ọmọ naa.

Àwọn ọmọdé tó dákú lásìkò ìgbẹ́jọ́ l'Abuja mọ̀-ọ́n-mọ̀ dákú ni - Ọlọ́pàá

Diẹ lara awon ọmọde naa ni kootu

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti sọ pe awọn ọmọde kan ti ọjọ ori wọn ko ti i pe ọdun mejidinlogunto ti wọn daku lasiko igbẹjọ ni kootu l’Abuja, lọjọ kin-in-ni, oṣu Kọkanla ọdun 2024 mọ-ọn mọ daku ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣapejuwe iwa awọn ọmọde yii bii ohun ti wọn ti pilẹ rẹ tẹlẹ, ti wọn si wa ṣe e nile ẹjọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ACP Olumuyiwa Adejọbi, sọ ninu atẹjade kan to fi sita lorukọ ọga agba pata fawọn ọlọpaa lorilẹede yii, Kayode Egbetokun, pe mẹfa ninu awọn ọmọ naa sare jade sita lati lọọ daku ni.

Adejobi sọ pe bi wọn ṣe sare lọọ daku lo mu ki awọn oniroyin tẹle wọn lẹyin, to si dohun ti wọn n gbe kiri.

“Lonii, iṣẹlẹ ti a ko rokan ṣẹlẹ ni kootu. Mẹfa ninu awọn afurasi sare jade lojiji, wọn si daku. Eyi mu kawọn oniroyin maa gbe e kiri, to si n jẹ ki oriṣiiriṣii ọrọ maa jade.

‘’A tete pese itọju fun wọn lẹsẹkẹsẹ, eyi to n ṣafihan pe ọlọpaa ko fọwọ yẹpẹrẹ mu ilera wọn, bo ti le wu ki ẹsun ti wọn n jẹjọ rẹ le to.’’

Atẹjade naa fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ko fiya jẹ awọn afurasi naa bi wọn ṣe wa ni ahamọ ijọba.

Wọn ni gbogbo ohun to jẹ mọ igbaye-gbadun wọn labẹ ofin ni awọn n tẹle, ko too di pe wọn foju ba ile ẹjọ.

‘’Òfin kò sọ pé ká má mú ẹni tí kò tí ì pé ọdún méjìdínlógún tó bá hùwà ọ̀daràn’’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ eeyan lo n koro oju si kiko tawọn ọlọpaa ko ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ti i pe mejidnlogun lọ si kootu ni Naijiria.

Nigba to n ṣalaye eyi ninu atẹjade naa, Alukoro ọlọpaa Naijiria sọ pe:

“ Labẹ ofin, ẹnikẹni to ba ti pe ọjọ ori ti eeyan fi le dahun si iwa ọdaran to ba hu, gbọdọ foju wina ofin, eyi ko kan ọjọ ori wọn.

‘’Ofin yii ki i ṣe fun Naijiria nikan, bo ṣe wa kaakiri agbaye, nibi ti wọn ti maa n ni ki ẹnikẹni to ba huwa to buru waa ṣalaye ohun to ri niyẹn.

“Bo ṣe wa niyẹn, koda ni United Kingdom, wọn ko yọ ọmọde silẹ lati ma jiya ofin. Ohun ti a kan maa n tẹle ninu iru ẹjọ bẹẹ ni pe a ko ni i fi ẹtọ won dun wọn labẹ ofin gẹgẹ bii ọmọniyan.

“ Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi da araalu loju pe, ọna akọṣẹmọṣẹ la o gba yanju ọrọ yii pẹlu ofin.

‘’A rọ araalu lati ma ṣe fi ojuṣaaju tabi aikunju oṣuwọn wo ohun to ṣẹlẹ yii, akoyawọ ti ko ni abawọn la fi n ṣiṣẹ tiwa.”

Bẹẹ ni atẹjade awon ọlopaa naa ṣalaye.

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ko olujẹjọ mẹrindinlọgọrin wa si kootu, niwaju Adajọ Egwuatu.

Wọ́n gba onídùúró àwọn olùjẹ́jọ́ kan

Adajọ Egwuatu to gbọ ẹjọ naa pada fi aaye gbigba oniduuro awọn mẹtadinlaadọrin (67) ninu awon ọmọde naa silẹ pẹlu miliọnu mẹwaa naira ẹni kọọkan

Awọn ti ọjọ ori wọn ko ti i pe mẹẹẹdogun ni wọn fi aaye beeli silẹ fun, pẹlu aṣẹ pe wọn gbọdọ mu oniduuro kan to jẹ oṣiṣẹ ijọba wa.

Ẹsun mẹwaa to ni i ṣe pẹlu idaluru, igbimọpọ, iditẹmọ ijọba atawọn mi-in ni wọn fi kan awọn ọmọde yii.

Iroyin sọ pe ọwọ ebi ti ba awọn kan ninu wọn nigba ti wọn farahan ni kootu, ati pe nigba ti wọn ko le da duro mọ ni wọn daku.

Díẹ̀ nínú orúkọ àwọn olùjẹ́jọ́ náà

Nura Ibrahim, Abdulbasi Abdusalami, Ahmed Yusuf, Awolu Abdulahi, Umar Musa, Muhammadu Mustapha, Umar Muhammed, Umar Inusa, Abdullahi Sani, Abba Usman, Ibrahim Rabiu, Abubakar San, Abubakar Abdullahi, Amir Muhammed, Umar Ali, Saminu Sani, Muhammed Musa, Suleiman Dauda, Ismail Abdullah, Haruna Suleiman ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọmọdé mẹ́rin dákú lásìkò tí ìjọba kó wọn lọ sílé ẹjọ fẹ̀sùn ìdìtẹ̀gbàjọba l'Abuja

Àwọn ọmọdé tí wọ́n fẹ̀sùn kàn

Ìjọba Nàìjíríà ti wọ́ èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin lọ sílé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Abuja fẹ́sùn pé wọ́n ń da ìlú rú àti ṣíṣe ọ̀tẹ̀ ìjọba.

Àwọn tí wọ́n fẹ́sùn kan náà wà lára àwọn tó ṣe ìfẹ̀hónúhàn lásìkò ètò ìwọ́de #EndBadGovernance tó wáyé láàárín ọjọ́ Kìíní sí ọjọ́ Kẹwàá, oṣù Kẹjọ ọdún 2024.

Lára àwọn afurasí ọ̀hún tí wọ́n wọ́ lọ síwájú adájọ́ Obiora Egwuatu ni wọ́n jẹ́ ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì pé ọdún méjìdsínlógún.

Ìwé ìpejọ́ tó wà níwájú adájọ́ tí òṣìṣẹ́ BBC fojú rí ṣàfihàn rẹ̀ pé lára àwọn ọmọ náà ni ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́rìnlá lọ.

Mẹ́rin nínú àwọn ọmọ náà ni wọ́n ní ó dákú nílé ẹjọ́ nígbà tí adájọ́ pé ẹjọ́ náà léyìí tó mú kí adajọ́ dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró fún ìgbà díẹ̀ ná.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n pè wọ́n ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan láti wá tẹnu wọn lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n tí gbogbo wọn sì ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wan kà sí àwọn lọ́rùn.

Ẹ ó rántí pé ṣáájú ni ìjọba ti kọ́kọ́ wọ́ èèyàn mẹ́wàá kan, tí wọ́n pè ní adarí ìwọ́de #EndBadGovernment ọ̀hún, tí wọ́n nawọ́ gán lásìkò ìwọ́de náà lọ sílé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn yìí bákan náà.

Ilé ẹjọ́ gba béèlì wọn pẹ̀lú mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà tí ìgbẹ́jọ́ wọn sì ń tẹ̀síwájú.

Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn kan sọ fún BBC pé láti oṣù Kẹjọ tí ìwọ́de náà ti wáyé ni àwọn ọmọ náà ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá, èyí tó ti lé ní ọgọ́rin ọjọ́.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí wan ń kojú ni pé wọ́n wọ fílààgì orílẹ̀ èdè Russia, tí wọ́n sì ń kọrin ọ̀tẹ̀ lásìkò ìwọ́de náà àti pé wọ́n ní kí ìjọba Russia wá dojú ètò ìjọba àwaarawa délẹ̀ ní Nàìjíríà.

Lásìkò ìwọ́de náà, onírúurú àwọn fídíò ló ṣàfihàn àwọn olùwọ́de tó fi mọ́ àwọn ọmọdé tí wọ́n gbé fílàgì Russia lọ́wọ́ pàápàá ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà.

Àwọn olùwọ́de náà ń ké sí ìjọba Russia láti wá gba àkóso Nàìjíríà bí ó ṣe wáyé ní Niger.

Lẹ́yìn náà ni àwọn aláṣẹ Nàìjíríà ní ọwa àwọn ti tẹ ẹni tó wà nídìí ìpè ọ̀hún àti pé àwọn máa fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀-mọ́-ìjọba kàn-án.