Ìgbẹ́jọ́ àwọn olùwọ́de ebi ń pa wá bẹ̀rẹ̀, àdájọ́ ní kí wọn máa najú lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ná

Ọpọ awọn oluwode to n pe fun fifi opin si isejọba buruku ni Naijiria ni wọn yọju sile ẹjọ giga ilu Abuja lonii ni ibẹrẹ ẹjọ idaluru ti ijọba fi kan wọn.
Saaju ni Dasuki Galandanchi, tii se igbakeji ọga agba ọlọ̀paa pata ni Naijiria ti kọkọ kede pe igbẹjọ awọn oluwọde naa yoo waye nilu Abuja, Kano, Kaduna ai Borno lonii ọjọ Aje.
Oluwọde mẹwa ni wọn ko lọ sile ẹjọ giga ilu Abuja naa, eyi ti Adajọ Nwite n dari.
Adajọ yii si lo jẹ ara adajọ meji to n sisẹ lasiko isinmi ile ẹjọ nitori awọn ile ẹjọ ni Naijiria wa lẹnu isinmi bayii.
Awọn oluwọde ni awọn ko jẹbi ẹsun onikoko mẹfa ti ijọba fi kan wọn
Gbogbo awọn oluwọde ti wọn fẹsun onikoko mẹfa kan si ni wọn ni awọn ko jẹbi ẹsun naa eyi to da lori idaluru, ete iditẹgbajọba ati biba dukia ilu jẹ pẹlu sise awọn agbofinro lese.
Orukọ awọn afurasi oluwọde naa ni Michael Adaramoye, ti ọpọ eeyan mọ si Michael Lenin, Adeyemi Abayomi, Suleiman Yakubu, Opaoluwa Simeon ati Angel Love Innocent.
Awọn yoku ni Buhari Lawal, Mosiu Sadiq, Bashir Bello, Nurudeen Khamis ati Abdulsalam Zubairu.
Ọkan lara awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ti wọn fi ẹsun kan ni wọn lo pawọpọ pẹlu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Andrew Martin Wynne to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika.
Wọn ni wọn n dete lati da omi alaafia Naijria ru nipa kike si awọn ologun lati ditẹ gba ijọba alagbada, labẹ Aarẹ Bola Ahmed Tinubuto wa lori aleefa lọwọ lorilẹede yii.
Wọn salaye pe se ni awọn afurasi naa n kọrin pe Tinubu gbọdọ lọ, Sọja ẹ gbajọba, Ijba ologun la n fẹ.

Adajọ ni kawọn oluwọde naa maa lọ naju na lọgba ẹwọn titi ọjọ Kọkanla osu kẹsan ti igbẹjọ yoo waye
Lẹyin ti awọn afurasi yii ni awọn ko jẹbi, ni agbẹjọro fun ijọba, Simon Long, wa rọ ile ẹjọ lati fi awọn oluwọde naa pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn.
Amọ Marshal Abubakar, tii se agbẹjọro fawọn afurasi adaluru naa tako agbẹjọro ijọba, to si sọ fun ile ẹjọ pe awọn eeyan naa ti pẹ ju ni atimọle tẹlẹ.
O wa rọ ileẹjọ naa lati gba oniduro awọn afurasi naa.
Bakan naa ni agbẹjọro fun Angel Love Innocent, tii se ọkan lara awọn afurasi naa, sọ fun ileẹjọ pe onibara oun ti fẹraku, to si rọ ile ẹjọ lati gba oniduro rẹ.
Lẹyin awọn ariyanjiyan yii ni adajọ Nwite sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kkanla osu kẹsan yii lati mọ boya yoo gba oniduro wọn tabi bẹẹ kọ.
O wa pasẹ pe ki wọn ko awọn afurasi naa lọ si ọgba ẹwọn Kuje titi di ọjọ ti igbẹjọ naa yoo tun waye.
Amọ o ni ki wọn fi obinrin to wa laarin wọn si ọgba ẹwọn Suleja titi di ọjọ ti yoo pada yọju sile ẹjọ.















