Ìwádìí BBC rèé lórí ìdí tí ilé fi ń dàwó léra léra l'Eko

Awọn eeyan to n gbiyanju lati doola awọn to ha sabẹ ile to wo l'Eko lọdun 2022.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan to n gbiyanju lati doola awọn to ha sabẹ ile to wo l'Eko lọdun 2022.
    • Author, Mansur Abubakar
    • Role, BBC News, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Iṣẹlẹ ile wiwo niluu Eko ti di nnkan to n waye lẹẹkan laarin ọsẹ meji meji lati ibẹrẹ ọdun 2024.

Ọpọ dukia ati ẹmi lo si ti ṣofo ninu awọn iṣẹlẹ yii.

Oriṣii igbimọ to n ri si ọrọ ile kọkọ, ṣugbọn iṣẹ wọn ko yọ pẹlu bi ile ṣe n wo lera lera niluu Eko.

O kere tan, akọsilẹ fihan pe ko din ni aadọrun ile to ti dawo niluu Eko laarin ọdun mejila, ninu eyi ti ọdunrun un eeyan le ni aadọta ti padanu ẹmi wọn.

Ara awọn iṣẹlẹ ile wiwo to rinlẹ julọ leyi to ṣẹlẹ lọdun 2021.

Sunday Femi ko jinna si ibi ti ile ori oke alaja mọkanlelogun ti dawo ni Ikoyi, niluu Eko nibi ti eeyan mejilelogoji ti padanu ẹmi wọn.

Lẹyin ariwo ile to dawo yii ni eruku bo Femi nibi to wa.

"Ni ṣe ni mo sare lọ si ibi ti ile naa ti wo lati doola awọn eeyan to ha si abẹ paguluntu ile to wo.

Mo mọ awọn kan lara awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ, mo si maa ronu nipa wọn lojoojumọ," Femi lo sọ bẹẹ.

Awọn eeyan to n gbiyanju lati doola awọn to ha sabẹ ile to wo l'Eko lọdun 2021.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan to n gbiyanju lati doola awọn to ha sabẹ ile to wo l'Eko lọdun 2021.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ awọn eeyan to n ta ọti ẹlẹrindodo lo maa n ba awọn oṣiṣẹ to n kọle sọrọ.

Wọn ti paanu ṣe ogiri yika ibi ti ile naa ti dawo, ṣugbọn eeyan si le ri awọn kan-n-kere ile to wo ọhun nibi alafo to wa lẹnu geeti ile naa.

Bi ijọba ṣe ti ibi ti ile naa ti wo pa ni ijọba ko tii sọ abajade iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Igbimọ oluwadii ti gba ijọba ni imọran lati gbe awọn igbesẹ kan, amọ, ijọba ko tii gbe e sita.

BBC ti beere lọpọ lọwọ awọn alaṣẹ ipinlẹ Eko lori abajade igbimọ to ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa, amọ, ijọba ko tii da BBC lohun.

Amọ, adajọ Majisreeti Oyetade Komolafe sọ lọdun 2022 pe iṣẹlẹ ile wiwo naa waye latari iwa aibikita awọn ajọ ijọba to yẹ ki wọn buwọlu ati ṣe amojuto ile naa.

Lojoojumọ leeyan n pọ si niluu Eko, koda, akọsilẹ fihan pe awọn olugbe ipinlẹ Eko ti pe ogun miliọnu eeyan bayii.

O fẹẹ jẹ pe gbogbo agbegbe ni ile kikọ ti n lọ lọwọ tori ọpọ eeyan lo n wa ile.

Ki iṣẹ ile kíkọ to le bẹrẹ, ajọ ipinlẹ Eko to n ri si erongba lati kolẹ gbọdọ buwọlu erongba naa.

Ajọ LASBCA to ṣakoso ile kikọ naa gbọdọ ṣayẹwo ibi ti eeyan fẹ kọlẹ si ki wọn si tun maa ṣe amojuto bi ile ọhun ṣe n lọ.

Bakan naa, ajọ SON gbọdọ ri pe ojulowo nnkan ikọlẹ ni wọn lo fun ile ti ẹnikẹni ba fẹ kọ.

Amọ, lọpọ igba ni wọn kii tẹ le awọn alakalẹ yii.

Ọpọ ti ṣe iwọde lati ke pe awọn to n kọle wi pe ki wọn maa tẹle ofin lori ile kikọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ti ṣe iwọde lati ke pe awọn to n kọle wi pe ki wọn maa tẹle ofin lori ile kikọ.

Agbẹnusọ ajọ LASBCA, Olusegun Olaoye, ti sọ pe irọ ni ahesọ ọrọ kan tawọn eeyan n gbe kiri wi pe àwọn oṣiṣẹ ajọ naa gba riba ti wọn si fáwọn to fẹ kọle iwe ofege.

O ṣalaye pe bii ọdunrun un awọn alamojuto to n ṣayẹwo ile kikọ lo wa nipinlẹ Eko, amọ, o ni wọn o to.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ile kikọ awọn to n ṣe amojuto ile kikọ yii ti kere ju.

Muhammad Danmarya to jẹ ayaworan ile sọ pe o yẹ k'awọn to n ṣiṣẹ yii to ẹgbẹẹgbẹrun.

Ọpọ awọn ileeṣẹ to n kọ ile ni a gbọ pe wọn ko tẹle awọn alakalẹ lori ile kikọ yii.

Ọpọ lo n lo ohun elo ikọlẹ ti kii ṣe ojulowo, bakan naa ni wọn tun n lo oṣiṣẹ ti ko ni iriri to lẹnu iṣẹ.

Habu Isah to jẹ birikila sọ pe awọn agbaṣẹṣe kan maa ṣadeedee wa ko awọn lọ síbi iṣẹ ti wọn si maa fawọn lowo t'awọn bi ti parí iṣẹ.

Isah loun o kẹkọọ ile kikọ ri labẹ enikan kan, o ni lẹnu iṣẹ naa loun ti n kọ bi wọn ṣe n kọlẹ.

Agbẹnusọ LASBCA, Ọgbẹni Olaoye ni lero ti toun, ko tii si igbẹjọ kankan to waye nipinlẹ Eko lori awọn ile to ti wo.

O ni lootọọ ni awọn iṣẹlẹ ile wiwo to n ṣẹlẹ bani lọkan jẹ, amọ, iṣẹ n lọ lati dẹkun awọn iṣẹlẹ naa.

Ogun eeyan lo ku nibi iṣẹlẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ to niluu Eko lọdun 2019.
Àkọlé àwòrán, Ogun eeyan lo ku nibi iṣẹlẹ ile ẹkọ alakọbẹrẹ to niluu Eko lọdun 2019.

Oloṣelu kan ti ko fẹ darukọ ara rẹ sọ fun BBC wi pe "ẹni to ba ti mọ eeyan ni ijọba, koda, ti o jẹbi ẹsun lori ile kikọ, ko si nnkan to maa ṣẹlẹ si i.

O ti ṣẹlẹ ni ọpọ igba, awọn ti iru nnkan bayii ṣẹlẹ si wọn, ko si ẹni to ṣe nkan kan tori wọn mọ eeyan ni ijọba."

Ni bayii, o ti pe iṣẹlẹ ile wiwo mọkandinlogun to ti waye bayii lọdun yii nipinlẹ Eko.

Adari ajọ awọn akọṣẹmọṣẹ amoju ẹrọ to n to n ṣamojuto ile kikọ ni Naijiria sọ laipẹ yii ni pe orilẹede Naijiria ko lagbara to lati ṣe iwadii gbogbo nkan to n lọ lori ile kikọ.

O ni ko si ọpọ akọṣẹmọṣẹ to ni iriri to pọ to lati ṣiṣẹ naa.

Ohun to wa nibẹ ni pe awọn to n ṣiṣẹ lori ile kikọ at'awọn lebira yoo maa tẹsiwaju nipa pipadanu ẹmi wọn.