Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yarí pé òun yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódí, bí Hamas ṣe ju okú ọmọ Israel mẹ́fà tó wà ní àhámọ́ síta

Orilẹede Israel ti n palẹmọ lati gunle iyansẹlodi gbogbo gboo nibayii ti iwọde n tẹsiwaju.
Ohun to fa rogbodiyan naa ko sẹyin bi awọn ọmọ ilẹ Israel se n fariga lori bi ijọba se kuna lati gba idande awn eeyan to wa ni ahamọ ikọ Hamas.
Se ni orilẹede Israel n gbona jainjain lati igba tawọn ologun ilẹ naa ti ri oku awọn eeyan mẹfa to wa ni ahamọ Hamas lọjọ Satide, eyi to mu ki ọpọ araalu wa ẹkun mu.
Lana ọjọ Aiku, ẹgbẹlẹgbẹ awọn araalu lo se iwọde, ti wọn si n naka aleebu si Olootu ijọba ilẹ naa, Benjamin Natanyahu ati ijọba rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Israel n tẹwọgba gba apo oku awọn to wa ni ahamọ dipo adehun itusilẹ wọn - Ẹgbẹ osisẹ
Ẹsun tawọn araalu fi kan ijọba ni pe ko sa ipa to yẹ lati se adehun lori idande awọn eeyan to wa ni ahamọ ikọ Hamas ọhun lati ọjọ Keje osu Kẹwa ọdun 2023.
Arnon Bar-David tii se asaaju awọn asaaju ẹgbẹ osisẹ to ga julọ nilẹ Israel, Histadrut salaye pe se ni orilẹede naa n tẹwọgba gba apo oku dipo adehun itusilẹ.
Ijọba ilẹ Israel ti wa fesi si ikede iyansẹsẹlodi atawọn ẹsun tawọn araalu fi kan wn ọhun.
Ijọba Israel fi ibinu fesi pada...
Ijọba si ti fi ibinu fesi pada pe se ni wọn n gbe igbesẹ ti yoo mu ki orilẹede naa tun pada ko sọwọ ikọ Hamas.
Amọ a ko le sọ boya iwọde naa yoo waye nitori ọpọ awọn ilu nlanla ati agbegbe lo ti kede pe wọn ko ni kopa ninu iyansẹlodi naa.















