Báyìí ni ìkọlù tó ń wáyé láàárín Israel àti Gaza ṣe bẹ̀rẹ̀

Ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni ikọ̀ Hamas ti or;ilẹ̀ èdè Palestin ṣe ìkọlù tuntun sí orílẹ̀ èdè Israel.
Ìkọlù yìí ló bí wàhálà tuntun láàárín orílẹ̀ èdè méjéèjì yìí ni èyí tí wọ́n ti máa ń fà láti ọ̀pọ̀ ọdùn sẹ́yìn.
Láti ìgbà tí ìkọlù tuntun yìí bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ènìyàn ti ń fẹ́ mọ̀ ohun tó máa ń fa ìjà gbogbo ìgbà láàárín àwọn orílẹ̀ èdè yìí.
Lẹ́yìn tí Hamas ṣe ìkọlù sí Israel náà ni Israel ti bẹ̀rẹ̀ sí ní da padà fún wọn tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sì ti bá ìkọlù náà lọ.
Oluileeṣẹ aṣoju ijọba Israel lorilẹede Amẹrika ni iye awọn eeyan Israel to ti ba wahala yii rin jẹ ẹgbẹrun kan ati mẹjọ.
Iye awọn ọmọ orilẹede Palestine to ti ku sinu ikọlu yii bayii ti le ni ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta eeyan.
Àwọn ohun tí ìgbàgbọ́ wà pé ó ṣokùnfà ìkọlù yìí ni a ṣe àkójọ sínú fídíò yìí.






