Wo fídíò bí ìkọlú Israel ti ṣe ba nǹkan jẹ́ ní Gaza
Wo fídíò bí ìkọlú Israel ti ṣe ba nǹkan jẹ́ ní Gaza

Eyi ni aworan bi agbegbe Gaza ṣe ri bayii lati ofurufu.
Aworan naa eyi ti a fi ẹrọ ayaworan drone ya ṣe afihan idibajẹ to ti de ba Gaza nipasẹ ikọlu Israel.
Oluileeṣẹ aṣoju ijọba Israel lorilẹede Amẹrika ni iye awọn eeyan Israel to ti ba wahala yii rin jẹ ẹgbẹrun kan ati mẹjọ.
Eyi si ni ikọlu to ṣi lagbara julọ lati ọdun marundinlọgọrin ti yanpọnyanrin ti bẹrẹ laarin awọn orilẹede mejeeji.
Iye awọn ọmọ orilẹede Palestine to ti ku sinu ikọlu yii bayii ti le ni ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta eeyan.






