Ẹ̀yin aráa Palestine kọ́ ni à ń bá jà, ẹ kúrò ní Ariwa Gaza - Iléeṣẹ́ ológun Isreal

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ologun lorilẹede Israel ti jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni aawọ kankan pẹlu awọn olugbe agbegbe Gaza sugbọn ki wọn kuro ni Ariwa Gaza lọ si Guusu Gaza laarin wakati mẹrinlelogun.
Agbẹnusọ fun orilẹede naa, Jonathan Conricus ninu fọnran kan to gbe soju opo ayelujara X, ti ọpọ mọ si Twitter tẹlẹ salaye pe erongba awọn ni lati da bobo ẹmi ati dukia. “Awọn araalu kọ ni ọta wa.”
O ni Ileeṣẹ ologun fẹ ṣe idinku si ikọlu ti wọn si awọn araalu, ti wọn si pe lati ṣe ikọlu si apa Gaza Strip, eyi to ni o ba ofin ati ilana ogun agbaye mu.
“O ye wa pe yoo gba akoko,” o sọrọ nipa kiko awọn araalu kuro. “Ko ki n ṣe igbesẹ ti yo rọrun
O le ni milọnu kan eeyan, ti to jẹ idaji gbogbo eeyan to wa ni Gaza Strip ti wọn yoo gbe kuro.
‘Ẹ kuro ni agbegbe Ariwa Gaza laarin wakati mẹrinlelogun’
Ileeṣẹ ologun Isreal ti ṣe ikilọ fun awọn araalu Gaza paapa awọn to n gbe ni ariwa Gaza lati kuro nibẹ lọ si guusu Gaza laarin wakati mẹrinlelogun.
“Ẹ yoo ni anfani lati pada si ilu Gaza nigba ti a ba sọ fun yin pe o ṣeeṣe”. Awọn alasẹ sọ eyi ninu atẹjade kan ti wọn fi ba awọn araalu sọrọ.
Ikọ ologun IDF ni ikọ agbebọn Hamas wa ni ipamọ ni abẹ ilẹ ọpọ agbegbe to wa ninu ilu Gaza ati ọpọlọpọ ile ti awọn araalu n gbe.
O wa rọ awọn araalu lati kuro lẹkun ariwa Gaza Ilu lati le daabo bo arawọn ati mọlẹbi wọn, ki wọn si tun rin jina kuro lọdọ awọn ikọ agbebọn Hamas.
Ajọ isọkan agbaye ti wa rọ Isreal lati tun igbesẹ naa gbe yẹwo nitori bi wọn ṣe sọ, o ṣeeṣe ki igbesẹ naa tun fa ọpọlọpọ wahala.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ ma da Isreal lohun rara, ihalẹ ni- Hamas sọ fun awọn araalu
Ọmọ ikọ agbebọn Hamas ti sapejuwe asẹ Isreal to ni ki awọn araalu kuro ni ile wọn ni ariwa GAZA lọ si guusu Gaza gẹgẹ bi ihalẹ.
O ni ki awọn araalu kọ eti ikun si ọrọ na.
Ọdun 2006 ni Hamas gba agbara akoso Gaza lẹyin to bori eto idibo ile igbimọ aṣofin
Gbogbo ọmọ ogun Hamas tí a bá rí la ó pa - Netanyahu

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olotu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ti ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ Hamas lawọn yoo ri pe awọn ran lọ sọrun.
Netanyahu sọ eyi lẹyin ipade akọkọ to ṣe pẹlu igbimọ iṣejọba pajawiri ti wọn gbe kalẹ n Israel latari yanpọnyanrin to n waye laarin awọn ọmọ ogun ikọ Hamas ati orilẹede Isreal.
Bakan naa, olori ẹgbẹ alatako lorilẹede Israel, Benny Gantz pẹlu ti sọ pe, ija ṣẹṣẹ bẹrẹ ni bayii larin Israel ati Hamas.
Sugbọn Aarẹ Amẹrika, Joe Biden ni oun ti ba Netanyahu sọrọ, oun si ti jẹ ko ye e pe orilẹede Israel gbọdọ tẹlẹ ilana lamẹ gbogbo to de ogun jija lagbaye.
Iye awọn eeyan ti rogbodiyan tuntun to bẹẹlẹ laarin Hamas ati Israel naa ti ran lọ sọrun ti le ni ẹgbẹrun kan ati igba. Ẹgbẹrun kan ọti ọgọrun ninu wọn lo jẹ wi pe ojo ado oloro ti Israel n rọ si Gaza lo gbẹmi wọn.
Aarẹ Biden ni ibinu awọn eeyan Israel ye oun sugbọn o rọ wọn lati tẹle ofin ati ilana Geneva . Bakan naa lo tun kilọ fun orilẹede Iran lati tọwọ ọmọ rẹ bọṣọ - nitori bi o ṣe n ṣe kan sara si ikilọ Hamas si Israel.
Saaju lọsẹ yii, Netanyahu ati Gantz pinnu lati gbe ọrọ ipinya oṣelu wọn ti si ẹgbẹ kan na, eyi to ti fa ọpọlọpọ iwọde.
Gantz sọ fun awọn eeyan Israel pe ijba tuntun lorilẹede naa ṣetan lati gbe igbesẹ to tọ ki o si dẹkun gbogbo gulegule ikọ Hamas lorilẹ aye.
Adó olóró Israel tí ṣekúpa èèyàn tó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárun(900) ní Gaza

Oríṣun àwòrán, GETTY IMAGES
Orileede Israel tẹsiwaju pẹlu ikọlu ti wọn n ṣe si ilu Gaza mojumọ ti awọn ọmọ ikọ ologun rẹ si lawọn ti yin ado oloro lu o kere tan ọna igba ni Gaza.
Gẹgẹ bi iroyin taa gbọ nipa ikọlu naa, ọkan ninu ado oloro ti wọn yin ba ile baba ọkan lara awọnbalogun ikọ HamasMohammed Deif to si pa ọpọ ninu awọn ẹbi rẹ.
Awọn alaṣẹ Palestine sọ pe o le ni eeyan ẹẹdẹgbaarun ti ikọlu yi ti mu ẹmi wọn lọ bayii.
Hamas naa ko dawọ yiyin ado oloro si Israel duro nibi ti wọn ti n yin ado oloro si ilu Ashketon.
Ẹwẹ ikọlu mii to lagbara n waye ni aala ibode laarin Israel ati Lebanon.
A gbọ pe awọn ọmọ ogun Israel sọ pe wọn yin ado oloro lati Syria si agbegbe ibi tawọn Jew n gbe.
Ninu iwe kan to fi ṣọwọ si igbimọ aabo ajọ isọkan agbaye aṣoju orileede Palestine si UN fẹsun kan Israel pe o n fiya ebi jẹ awọn eeyan ilẹ Palestine labẹ pe ogun n waye.
O ni bi Israel ṣe n yin ado oloro si Palestine lo buruju julọ ninu iwa ọdaran ti eeyan le hu lasiko ogun.
Lọwọlọwọ ọpọ awọn orileede ilẹ larubawa lo ti gbe igbesẹ lati ṣe alekun iye iranwọ ti wọn fi n ṣọwọ si Palestine tohun ti bi nkan ṣe n buru si ni agbegbe Gaza.
Aarẹ United Arab Emirates, Mohammed bin Zayed,ti paṣẹ ki wọn ṣeto iranwọ pajawiri miliọnu ogun dọla to jẹ nkan eto ilera ati awọn nkan mii.
Ọba Abdullahi ti orileede Jordan naa paṣẹ eto ipese iranwọ pajawiri bakan naa.
Hozayfa al Yazji,to jẹ oṣiṣẹ iranwọ pajawiri sọ fun BBC pe awọn eeyan to n gbe ni agbegbe Gaza ti sọ ireti nu.
''Nkan ti mo le sọ ni pe awọn kan lo da gbe igbesẹ yi.Mi o faramọ ikọlu sawọn araalu lati ọdọ ẹnikẹni.Ikọlu ti wọn ṣe si Gaza yi n mu ẹmi awọn eeyan n lọ ni to si ba ọpọ nkan jẹ.Inu ibẹru bojo lawọn eeyan wa mi o si mọ nkan taa le ṣe''
Ṣugbọn oludamọran si Olootu ijọba Israel Mark Regev sọ peIsrael ni lati gbe igbesẹ lati fesi pada lori ikọlu ti wọn ṣe si wọn yi ki wọn si ma ṣojo rara.












