Gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, kò wù mí kí n máa gbé nínú ìbẹ̀ru ogun

Aworan ọmọde lati Gaza

Awọn ọmọde lagbegbe Gaza ti n sọrọ sita lori oun ti wọn n foju wina bi irọkẹkẹ ada oloro ṣe n wa lati orilẹede Israel lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ Hamas kan ṣe ikọlu si Israel lọjọ Satide.

Gẹgẹ bi ajọ agbaye UN ṣe sọ, o to ẹgbẹrun mejila eeyan to ti di alarinkiri ati alainilelori nitori wahala naa.

Fọnran kan ti Ileeṣẹ BBC gbe jade ṣe afihan bi awọn araalu Gaza ṣe n gbe ninu ibẹru, ti ọpọlọpọ dukia si ti bajẹ.

Ọkan lara awọn ọmọde to ba BBC sọrọ sọ pe o wu oun pupọ ko jẹ wi pe ko si ogun ni awujọ ti oun n gbe.

“Ti ko ni si ado oloro lori ile wa, ki gbogbo wa le pada si ile wa ninu alaafia “

Baba onisowo, ẹni ọdun marundinlọgọta, kan pẹlu salaye bi nnkan ṣe n lọ niluu Gaza lẹyin ikọlu Israel.

“Ki ni wọn tun fẹ ṣe? Ẹ saanu wa, o to gẹ.

“Ẹni ọdun marindinlọgọta ni mi bayi, mo ti lo gbogbo akoko aye mi kuro lati ogun kan si kan”, eyi ni ọrọ ti ọkunrin naa sọ lẹyin ti ado oloro ṣe ijamba si ile itaja rẹ niluu Rafah ni Gaza.

“Wọn ba ile wa jẹ ni Albarazeel, ni Abu Halawa, igba meji ni wọn ba ile wa jẹ.

“Bayii, ile itaja mi, ti mo fi n tọ ọmọ okunrin marun un lo ti dawo yii, Ọlọrun lo ko wọn yọ, meji ninu wọn fi ẹsẹ paa”

Kò sí iná mọ̀nàmọ́ná , omi, epo bẹntiro àti oúnjẹ fún Gaza mọ́ - Israel

Orilẹede Israel ti kede pe awọn yo fopin si gbogbo awọn anfani ti Gaza n jẹ lati ọdọ awọn bi ina mọnamọna, Omi, Epo bẹntiro, ati ounjẹ.

Gẹgẹ bi awọn olugbe Gaza ṣe salaye pe awọn ko ti ri ohun iranwọ lati ọjọ Satide ti ikọlu ọhun ti waye.

Fọnran ti BBC gbe jade se afihan awọn ijamba to waye lẹyin ikọlu ado oloro lati orilẹede Israel.

O to eeyan ẹẹdẹgbẹrin to ti jade laye nitori awọn ikọlu yii, ti ogunlọgọ si farapa yanayana.