Iléẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa Amòfin Bolanle Raheem lọ́jọ́ kérésìmesì

Ileẹjọ giga to n joko nipinlẹ Eko ti dajọ iku fun ọlọpaa to yinbọn fun agbẹjọro obinrin, Bolanle Raheem lọjọ keresimesi ọdun 2022.
Adajọ Ibironke Harrison to gbọ ẹjọ naa ni ki wọn yẹgi fun ga ọlọpaa Dambri Vandi titi ẹmi yoo fi bọ lẹnu rẹ.
Onidajọ Harrison gbe idajọ naa kalẹ lẹyin to ni afurasi ọhun jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
Saaju, Dambri Vandi ni oun ko jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun .
Oṣu mẹwaa ni wọn fi ṣe ẹjọ yii ki adaj to gbe idajọ rẹ kalẹ lọjọ Aje.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, agbẹjọro Babajide Martins ni ijọba ni ninu ijọba pupọ si idajọ ti ileẹjọ gbe kalẹ, ti gbogbo mọlẹbi si dupẹ lọwọ pupọ.
Òní ni ìdájọ́ afurasí ọlọ́pàá, Dambri Vandi lórí ikú Bolanle Raheem

Oríṣun àwòrán, Others
Ileẹjọ giga ni Ipinlẹ Eko yoo gbe idajọ kalẹ ọlọpaa Drambi Vandi to ṣekupa Agbẹjọro obinrin, Bolanle Raheem lọjọ keresimesi, ọjọ kẹdọgbọn oṣu kejila ọdun 2022.
Lọjọ Keresimesi ni ọlọpaa kan ti orukọ rẹ n jẹ DSP Drambi Vandi yinbọn pa Agbẹjọro Bolanle ni agbegbe Ajah.
Awọn ọlọpaa mẹta lo wa nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pẹlu ẹbi Bolanle.
Vandi fi arahan ileẹjọ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa buwọlu idaniduro lẹnu isẹ rẹ fun igba diẹ nitori ẹsun pe o ṣe ka Iyafin Raheem.
Ohun to ti waye tẹlẹ
Lọjọ ọdun keresimesi ọdun 2022 ni iroyin jade pe agbẹjọro kan, Bọlanle Kareem ti jade laye lẹyin ti ọlọpaa kan yinbọn fun un ninu mọto ọkọ rẹ.
Gẹgẹbi ohun ti ọkọ rẹ ọ nigba naa, o ni awọn n bọ lati ile ijọsin ni awọn ọlọpaa naa da wọn duro fun ayẹwo ti awọn si duro.
Ṣadede lo ni iro ibọ dun ti oun si ri i pe ibọn ti ba iyawo oun, to joko siwaju ọkọ ni aya.
Ṣaaju lawọn ijoko igbẹjọ yii to ti waye, ọga ọlọpaa DSP Drambi Vandi to yinbọn naa sọ pe oun jẹbi ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan oun.
Vandi sọ eyi lasiko to foju bale ẹjọ giga to wa ni Tafawa Balewa Square nilu Eko lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.
A yọ ọta ibọn lara Bolanle Raheem, a si ri ile ọta ninu ọkọ rẹ - Ẹlẹrii
Ọlọpaa to wa nidi ẹjọ naa si jẹri lori iwadii ti wọn ṣe lẹyin iku agbẹjọro obinrin, Bolanle Raheem.
Ọlọpaa ọhun, Adeyemo Olubummi ni lati ibi ọdun mọkanlelogun ni oun ti darapọ mọ ileeṣẹ orilẹede Naijira.
O ni iwadii oun fihan pe Vandi Drambi lọwọ ninu iku agbẹjọro obinrin naa.
Agbẹjọro agba nipinlẹ Eko, Moyosore Onigbajo lo lewaju ninu fifi ọrọ wa Ọlọpaa naa lẹnu wo, bo ṣe n jẹri ni ileẹjọ.
Tani Bolanle Raheem ti wọn yinbọn pa?
Agbẹjọro ni Bolanle Raheem to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ Croston Homes Consulting ni ilu Eko.
O jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ awọn agbẹjoro ni Naijiria, ti o si jẹ ogunna kan ṣoṣo lọwọ iya rẹ.
Ileẹkọ Olabisi Onabanjo University ni Ago Iwoye, ni ipinlẹ Ogun.
Arabinrin naa jẹ onimọ nipa eto ile gbigbe to si ti lamilaaka, ti awọn eniyan si ma lọ gba imọran lọwọ rẹ.













