Ṣé lóòtọ́ ní Sunday Igboho ti gba ìtúsílẹ̀? Ohun tí á mọ̀ réè

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1
Se gbajugbaja ajafẹtọ idasilẹ ilẹ Yoruba nii Oloye Sunday Adeyemọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti gba ominira lati kuro ni orileede Benin?
Ibeere yi lọpọ ọmọ Naijiria n beere bayii lori ọrọ Sunday Igboho lẹyin ti iroyin jade pe gbajumọ ajafẹtọ ọmọ ilẹ Yoruba naa ti gba ominira.
Ko si ṣẹyin awọn iroyin kan ti a ri eleyi to sọ pe Igboho ti gba ominira to si ti lanfaani lati tẹsiwaju lọ si orileede Germany lati Benin Republic to wa lati ọjọ yi.
Agbẹjọro fun Sunday Igboho lorilẹede Naijiria, Amofin agba, Yọmi Aliyu SAN pẹlu ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Sunday Igboho fi idi iroyin yii mulẹ un BBC News Yoruba pe lootọ ni Sunday Igboho ti gba itusilẹ.
Niwọn igba ti Benin republic ti tu Igboho silẹ ko si ohun to di i lọwọ ati wọ Naijiria - Amofin Yomi Aliyu SAN
Ninu ọr rẹ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹjọro fun Sunday Igboho, Amofin Yọmi Aliyu SAN ṣalaye pe ko si ohun to di Sunday Igboho lọwọ ati wọ NAijiria bayii niwọnn igba ti ijọba orilẹede Benin to fi si ahamọ ti tu u silẹ ko si ohun kan to n da iwọlewọde rẹ duro lorilẹede Naijiria.
"Ti Benin ba ti ṣi i silẹ pe ko ṣẹ awọn Naijiria ko ni ko maa wọ Naijiria. Oun lo kan wu bẹẹ funra rẹ. O le wọle, o dẹ le jade gẹgẹ bi ọmọ Naijiria."
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, Sunday Igboho lo di ero ahamọ lorilẹede Benin lọdun 2021 lẹyin ti ajọ DSS se ikọlu si ile rẹ lori ẹsun pe o n pe fun Idasilẹ orilẹede Ilẹ Yoruba.
Nibo ni Igboho wa bayii?

Oríṣun àwòrán, others
Ohun ti a ri gbọ lẹnu awọn to sun mọ Sunday Igboho ati irinajo rẹ lati ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021 ni pe titi di alẹ ọjọ Aiku, ilu Coutonou ni Sunday Igboho wa.
Ọgbẹni Ọnaọlapọ Omiyale fi idi eyi mulẹ pẹlu.
Amọṣa o ni laarin oru ọjọ Aiku mọju ọjọ Aje ni Sunday Igboho tẹkọ leti lọ si orilẹede Germany.
Orilẹede Germany yii naa lo n lọ ki awọn agbofinro to de e lọna ni papakọ ofurufu ni Benin ti wọn fi fi si ahamọ.
“Ahamọ onigbele ni wọn wa ni Benin republic; wọn ti wa tu wọn silẹ bayii pe wọn ko lẹjọ kankan lati jẹ, ṣugbọn ijba Naijiria ko tii tu wọn silẹ eyi to tumọ si pe wọn ko tii le wọ orilẹede Naijiria.”
Ki ni Igboho sọ loju opo rẹ?
A kan si oju opo Sunday Igboho eleyi t fi n ba araye sọrọ ni Instagram lati ri boya o fi ikede yi si ibẹ.
Ninu ohun taa ba bọ nibẹ si ni pe Sunday Igboho fi fọnran fidio idupẹ kan sita nibi to ti dupẹ lọwọ ọpọ eeyan lori ''ọjọ pataki yi''
Ko sọ pato ohun ti o n waye lọjọ pataki to darukọ boya o ti lanfaani lati kuro ni Benin Republic lọ si Germany nii tabi ko si pada wa sile ni Naijiria.
Lara awọn to dupẹ fun ni aarẹ Benin Patrice Tallon awọn eekan ni ilẹ Yoruba bi Ọjọgbọn Wole Soyinka, awọn ọba ilẹ Yoruba ati awọn alatilẹyin rẹ to duro ti ninu itẹsiwaju idasilẹ orileede Yoruba.
Ko si ohun to jọ pe o darukọ gbigba itusilẹ patapata ninu fọnran yi bẹẹ si ni Sunday Igboho ko tọka ninu ọrọ rẹ wipe ibi ti oun n lọ ree.
Yala ohun to kọ taa si ri ninu oju opo rẹ ni pe fidio yi da lori idupẹ fawọn to baa kẹdun lasiko iku iya rẹ to si tun fi fidio naa ki ara rẹ ku oriire ayajọ ọjọ ibi rẹ to n bọ lọna
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Irinajo Igboho titi di akoko yi

Orileede Naijiria ni Oloye Sunday Igboho ti bẹrẹ irinajo rẹ to si pada wa kangun si orileede Benin.
Bi a ba ni ka ka ni meni meji bayii, o ti le ni ọdun meji ti awọn agbofinro mu Sunday Igboho lorileede Benin nibi to fẹ gba sa kuro ni Naijiria lọ si Germany pẹlu iyawo rẹ.
Idi to fi sa kuro ni Naijiria ko ṣẹyin bi awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Naijiria ṣe ṣe ikọlu si ile rẹ loru mọju ti wọn si mu awọn ọmọ ẹyin rẹ .
Ikọlu yi waye lẹyin ti ijọba Naijiria sọ pe o n pepe si ipinya orileede Naijiria nipa idasilẹ Yoruba Nation to n polongo ni igba naa.
Wọn si ni ikọlu tawọn ṣe si ile rẹ waye tori pe o ko nkan ija olori pamọ si ile.
Kaakiri agbaye ni iroyin nipa rẹ gbode ti ọpọ nilẹ Naijiria ati lẹyin odi si lawọn ṣetan atilẹyin fun Igboho.
Lati igba ti wọn ti mu ni orileede Benin ni ile ẹjọ ti ni ki wọn fi si ahamọ labẹ aabo ijọba Benin.
Ibẹ lo wa lati ọjọ yi titi di asiko yi taa gbọ pe o gba ominira lati kuro labẹ aabo ijọba Benin ko si lọ si ibikibi to ba wu u.
Ni kete ti a ba ri idi ọrọ yi fi mulẹ a o maa fi to yin leti boya lootọ ni wọn tu silẹ ati ibi ti o kan bayii to fẹ gbera lati maa lọ.















