Òkú ìyá mi ṣì wà ní ilé ìgbókúpamọ́ sí – Sunday Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Gbajumọ ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti ṣalaye pe oun o ti ri aye sin oku iya oun to ku laipẹ yii.

Sunday Igboho sọ ọrọ yi lasiko to fi n ki awọn eeyan to ṣe eto adura ọjọ mẹjọ oku iya rẹ.

“Iya mi ṣi wa ni ile igbokupamọsi, n ko tii sin oku rẹ gẹgẹ bi ilana kristẹni nitoripe mọlẹyin kristi ni mi.”

Ni ọjọ Satide ọjọ kejilelogun oṣu keje ọdun 2023 ni iya Sunday Igboho, jade laye.

Gbajumọ ajafẹtọ idasilẹ orilẹede Yoruba naa ko lanfani lati wa pẹlu iya rẹ lawọn akoko ikẹyin rẹ.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Sunday Igboho wa lorilẹede Benin lẹyin ti awọn agbofinro kọlu ile rẹ loṣu keje ọdun 2022 to si sa lọ si Benini pẹlu igbiyanju ati gba ibẹ lọ si orilẹede Germany ki ọwọ awọn agbofinro to tẹ ẹ.

Amọṣa ijọba orilẹede Benin gba a silẹ ti wn si ṣe pe e lẹjọ pe o gba orilẹede naa kọja laigbaṣẹ.

Lọjọ Aiku lawọn ẹlẹsin Musulumi kan ko ara wọn jọ lati ṣe adura ọjọ mẹjọ fun iya gbajumọ naa.

Ninu ọr to fi si oju opo Instagram rẹ, Oloye Sunday Igboho dupẹ pupọ lọwọ awọn eeyan naa fun ifẹ ti wọn fi han oun ati oku ọrun.