Ọmọ Yorùbá tó bá fẹ́ ṣoríire kò gbọdọ̀ máa bọ òrìṣà kankan - Oluwo

Oluwo ti ilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hope for Iwo

Ọluwo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, Telu akọkọ ti rọ gbogbo ọmọ kaarọ ojire lati yago fun bibọ orisa kankan tabi titọ ipasẹ bibọ orisa lati fi sin Ọlọrun nitori Olodumare ko fẹ orogun rara.

Ọba Akanbi sọ eleyi ninu fọnran kan to wa lori ayelujara, o ni baba nla gbogbo eeyan iyẹn Adamọ ko fi igba kan foribalẹ fun orisa kankan ayafi Olodumare to da saye nikan.

"Baba nla gbogbo eeyan, Adamọ ko foribalẹ fun orisa kankan, ko si awọn orisa kankan lasiko ti Ọlọrun da Adamọ.

"Olodumare lo da awa eeyan, awa ọmọ Yoruba lo si kọkọ da saye, koda ọmọ Adamọ lo yẹ ka ma jẹ sugbọn a ti gba pe ka ma jẹ Yoruba.

"Olodumare yii ni isẹnbaye, abalaye, oun lo ni gbogbo nnkan oun lom seda gbogbo rẹ.

"Ẹyin ọmọ Yoruba, Olodumare jowu pupọ, ẹ si n wa ibinu rẹ"

Oba Akanbi tẹsiwaju pe bi awọn ọmọ Yoruba se n mu orisa mọ sinsin Olodumare ni ko yẹ ko jẹ bẹ nitori Olodumare jowu pupọ, ti ko si fẹ ki orisa kankan ba dẹgbẹ ati pe oun lo da gbogbo nnkan ati orisa gan.

Kabiyesi fikun pe bibọ orisa tabi eeyan le fa ibinu Olodumare.

"Ẹyin ọmọ Yoruba, ti ẹ ba n bọ orisa, ti ẹ n bọ eeyan, ẹ n wa ibinu Olodumare

"N ko sọrọ ẹsin Kristẹni, n ko sọrọ ẹsun Islam ti ẹ n sọ, Olodumare ni Ọlọrun Baba nl;a ti wa, wọn ko ki bọ Ogun tabi Sango

"Awọn Ogun, Osun, Ọya ati Sango sẹsẹ de ni "

Oluwo salaye siwaju pe pupọ awọn orisa ti awọn ọmọ Yoruba ni wọn sẹsẹ de

"Ọmọ Ekiti ni Ogun, oro idile, Sango, Osun, Ọya ati awọn mii sẹsẹ de ni, koda Oduduwa ju wọn lọ pupọ.

"Ọlọrun awọn baba nla wa ni wọn n pe ni Kabiyesi Olodumare

"Iwọ ọmọ Yoruba, ma ba wọn ma bọ orisa yẹn mọ, ma ro pe awọn kan ni owo, itanjẹ ni gbogbo rẹ

"To ba fẹ nnkan a n pe ni ọgbọn, o jẹ nnkan ti Kabiyesi Olodumare ma n fun eeyan, ti ọgbọn naa si ju owo lọ nitori ninu ọgbọn naa ni owo ti jade

"Owo sẹsẹ de ni, awọn baba nla wa, owo ko ti de, awọn ẹbo lo mu owo wa."

"Yoruba ko ki se ẹgbẹ awọn Chiness, India"

Ọba Adewale Akanbi tun tẹnubọ ọrọ pe yoo soro lati fi iran Yoruba we iran kankan lagbaye nitori ni gbogbo ọna ni iran Yoruba fi jẹ asiwaju. sugbọn mimu nnkan pọ mọ Olodumare n se akoba pupọ

"A ko si n se ẹgbẹ awọn Chiness, India tabi iran kankan lagbaye, Yoruba ko wa lati iran Arab nitori awọn ni wọn wa lati ọdọ wa,

"Awọn Jew naa ninu ẹjẹ wa ni wọn ti wa, ti ẹri wa fun gbogbo nnkan ti mo n sọ yi

Ọba Yoruba ko gbọdọ bọ orisa

Kabiyesi ni Ọba ilẹ Yoruba ko gbọdọ bọ orisa nitori iran Yoruba ni Olodumare kọkọ fun ni oreọfẹ lati Ọba.

"Awọn ti ẹ ri ti wọn n bọ orisa yii, oro idile wọn ni wọn n se.

"Ti wọn ba fẹ jẹ Ọba ilu, awọn ko mọ awọn fẹ gba igbekalẹ Olodumare ni

"Sugbọn ọpọ wọn ti wọn n bọ oprisa kan ni ile wọn ni wọn yoo wa mu mọ ti wọn fi jẹ Ọba ilu wọn

"Ẹ ti n ba bọ Sango, yoo lo Sango lati fi jẹ Ọba, pẹlu awọn ologboni naa, oro idile orikaluku ni wọn n lo fi jẹ Ọba ati pe nnkan ti o n jẹ Ọba yatọ

Omo Yoruba to ba fẹ sorire, ko pe Olodumare nikan

Oba Akanbi ni ko si ẹnikẹni to ni anfani lati fi oju kan Kabiyesi Olodumare ati pe oun gan kọ ni Ọba sugbọn ninu ọla Olodumare ni wọn fi ki oun ni Ọba ilẹ Yoruba

O wa rọ awọn ilẹ Yoruba to ba fẹ sorire, to ba fẹ ọgbọn nla lati da bi awọn eeyan nla lagbaye ko ri pe oun n pe Olodumare nikan.

"Iwọ to ba fẹ lọgbọn to ju ti awọn bi Mark Zuckerberg, Warren Buffett, Elon Musk, iwo pe Olodumare nikan lati oni lọ, ma gba ọdọ orisa kankan, iwọ kan pe Olodumare, ogun aye ko le bori rẹ

"To ba pe Olodumare, ko ti si ogun naa, Ọlọrun awọn baba nla wa, lọkan, ni iwọ nikan, gba ori rẹ mu

"To ba ri aafin ti wọn ko gbe orisa sibẹ tabi ti wọn ko ki n bọ orisa, lọ si ibẹ, yoo ma jẹ o ni

"Gbogbo ohun to ba fẹ ni o ma ri sugbọn to ba bọ orisa ati pe ofin ni pe iwọ ko gbọdọ foribalẹ fun Ọlọrun miiran lẹyin oun nikan

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post