Ọ̀fẹ́ ni ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga - Ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjọba àpapọ̀ ti tẹnumọ́ pé gbogbo àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọn kìí san owó ilé ẹ̀kọ́ kankan.
Agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu, Dele Alake nínú àtẹ̀jáde tó fi síta lọ́jọ́rú ní àwọn ìròyìn tó gba ìgboro kan lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí pé ìjọba ti fi owó kún àwọn owó ilé ẹ̀kọ́ kìí ṣe òótọ́.
Alake ní lóòótọ́ ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga kan kéde àlékún lórí owó tí akẹ́kọ̀ọ́ yóò san láti padà sí ẹnu ẹ̀kọ́ wọn.
Ó jí òun fẹ́ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn owó yìí kìí ṣe owó ẹ̀kọ́ láti ọwọ́ ìjọba bíkòṣe iye tí ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ń gbà lọ́wọ́ ara wọn fún àwọn ètò ìkẹ́kọ̀ọ́.
Ó ṣàlàyé pé àwọn nǹkan tí owó náà wà fún ni ilé ìgbé, ìforúkọsílẹ̀, yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Agbẹnusọ Ààrẹ náà ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí ti ṣáájú ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi mú àlékún bá àwọn owó yìí.
Alake là á mọ́lẹ̀ pé ọ̀fẹ́ ni àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ àti pé àwọn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń san yìí ló jẹ́ ti àwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí fúnra wọn.
Bákan náà ló tẹ̀síwájú pé Ààrẹ Tinubu ní ìfarajìn láti ri dájú pé gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà jẹ́ àǹfàní ètò ẹ̀kọ́ tó pójú owó.
Ó ní yàtọ̀ sí ètò ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí Tinubu buwọ́lu fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní sáà ètò ẹ̀kọ́ tó ń bọ̀, ìjọba yóò tún gbé àwọn ètò kalẹ̀ láti fi ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́.
O ṣàlàyé pé lára àwọn ìgbésẹ̀ tí ń ìjọba ń gbèrò láti fi ri pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń parí ẹ̀kọ́ wọn lásìkò tó yẹ ni ètò gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láàyè láti máa ṣiṣẹ́ bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, gbígbé ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ kalẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti ń bu ẹnu àtẹ́ lu ọ̀rọ̀ yìí pé owó náà ṣá ni àwọn ń ṣàn ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà














