Ohun tá a mọ̀ nípa bí àwọn ọmọ ológun ṣe gba ìjọba lorílẹ̀èdè Niger rèé

Awọn ọmọ ologun lorilẹede Niger ti iditẹgbajọba lọwọ Aarẹ Bazoum.
Isẹlẹ naa lo waye ni ana lẹyin ti awọn olori ikọ ologun orilẹede naa bọ sori ẹrọ momaworan lati kede ijọba tuntun naa, ti wọn si tun wọgile iwe ofin orilẹede Niger.
Bakan naa ni awọn olori ologun kede pe ki gbogbo ẹnu ibode lorilẹede naa wa ni titi pa.
A ko le fi idi rẹ mulẹ ibi ti Aarẹ Bazoum wa bayii.
Aarẹ Benin, Patrice Talon, to wa soju ajọ ECOWAS ti balẹ si orilẹede naa sugbọn ko ni anfani lati ba awọn ọmọ ologun to n sọ aarẹ sọrọ.
Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé lorílẹ̀-èdè Niger,wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ọmọ ogun ti gbegidina ẹnu ọna abawọle aafin aarẹ ati pupọ ninu awọn ileeṣẹ ijọba ni Niamey gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ.
A gbọ pe iro ibọn n dun ni kikan kikan amọ ko daju boya awọn ẹsọ aarẹ lo n gbiyanju lati gba ijọba.
Ileeṣẹ aarẹ kọ ọrọ soju opo Twiter pe awọn ẹsọ wọnyi ko ribi bori pẹlu bi wọn ṣe n wa atilẹyin lọdọ awọn ọmọ ogun.
AFP jabọ pe aarẹ Mohamed Bazoum wa ninu ile pẹlu awọn mọlẹbi rẹ.
Eeyan kan sọ fun ileeṣẹ iroyin kanna pe inu lo bi awọn ọmọ ogun ati pe wọn ti n jiroro lori ọrọ naa.
Iroyin sọ pe aarẹ tẹlẹ Mohammed Issoufou ati awọn aarẹ mii to jẹ ṣaaju ti ko si ijiroro ki ọrọ nma kọja bo ṣe wa.
Ileeṣẹ aarẹ sọ pe ''aarẹ ati awọn mọlẹbi rẹ wa lalaafia.Ileeṣẹ ologun ati awọn ẹsọ aarẹ ṣetan lati koju ẹnikẹni to wa nidi iṣẹlẹ yi''
Orileede Niger wa lara awọn ilẹ ti iditẹgbajọba ti gbogo julọ lagbaye.
Lati igba ti wọn ti gba ominira o kere tan iditẹgbajọba mẹrin ni wọn ti koju lati dun 1960.
Aaarẹ Bazoum, ti araalu dibo yan ni 2021 jẹ wọlewọde orileede France.
Ọdun 2010 ni iditẹgbajọba waye kẹyin ni ilẹ naa loṣu Keji ti wọn si fi yọ aarẹ Mamadou Tandja kuro nipo.
Niger n koju awọn alakatakiti ẹsin Islaam lọna meji ọkan lapa iwọ oorun Guusu ilẹ naa to sunmọ Mali lọdun 2015.
Ikeji si jẹ eleyi ti wọn koju lati ila oorun Guusu pẹlu awọn agbesunmọmi ti wọn fi ariwa Naijira ṣe ibujoko.
Awọn agbesunmọmi alatilẹyin al-Qaeda ati Islamic State fẹsẹ rinlẹ daada lagbegbe yi.
Awọn orileede alamuleti Niger meji iyẹn Mali ati Burkina Faso koju iditẹgbajọba ti awọn alakatakiti ẹsin Islaamu ṣagbatẹru rẹ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Digbi la wa lẹyin orileede Niger-Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat
Olori ajọ ECOWAS to tun jẹ aarẹ Naijiria,Bola Tinubu sọ pe ajọ naa ko ni faaye gba igbesẹ kankan ti yoo da iṣejọba taraalu finufẹdọ yan ni Niger tabi lorileede mii ni iwọ oorun Afrika.
Ikede yi n waye pẹlu bi awọn ọmọ ogun kan ṣe gbegi dina aafin aarẹ ati awọn ileeṣẹ ijọba kan ni Niamey.
Aarẹ Ecowas,Bola Tinubu sọ ninu atẹjade pe awọn foju wo bi nkan ṣe n lọ lorileede naa.
O ni ''emi ati awọn olori orileede lagbegbe wa jijọ n jiroro a si ṣetan lati daabo bo ijọba awarawa ni ibamu pẹlu ohun ti gbofgbo aye faramọ nipa titẹle iwe ofin''
Tinubu fi kun pe digbi ni Naijiria wa lẹyin ijọba ti araalu dibo yan ni Niger












