Jihadist attack in Mali: Àwọn alákatakíti pa ọmọ-ogun Mali lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ti France kéde kíkó ọmọogun rẹ̀ kúrò níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ologun lorilẹede Mali ti sọ pe ṣọ̀]ja mẹta lawọn ọmọ ogun ọlọtẹ pa lẹkun ila oorun ariwa Archam lorilẹede naa
Bẹẹ naa ni wọn ni awọn ọmọogun marun un miran ti di awati bayii.
Ija naa waye lẹyin jọ diẹ ti orilẹede France atawọn alatilẹyin rẹ kede pe awọn n ko ọmọogun awọn kuro lorilẹede Mali.
- Àwọn aláṣẹ UK ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn nítorí ìjì líle
- Só lè jẹ búrẹ́dì tí wọ́n fi Aáyán se?
- Wo ìlú tí wọ́n ti fòfin dé yíya àwòrán ṣaájú ìgbéyàwó ìyẹn "pre wedding picture" àti ètò ìgbéyàwó mìíràn
- Fọ́tò àǹkóò oyún ọmọ ìyá mẹ́ta gbòde kan
- Ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀ rí jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀
Atẹjade kan ti ileeṣẹ ọmogun lorilẹede Mali fi sita ṣalaye pe, awọn naa ko maa kawọ gbera o nitoripe awọn ọmọogun ọlọtẹ mẹtadinlọgọta lawọn ọmọogun ofurufu pa nibẹ.
O ni awọn ọmọogun naa n wa awọn ibuba awọn ọmọogun ọlọtẹ naa ni, lawọn agbebọn kan fi ṣina ibọn bolẹ fun wọn.
Akaimọye awọn onwoye lẹkun agbegbe Afrika ati kaakiri agbaye ti wọn ti n kọminu lori ipo ti eto abo wa ni Mali lẹyin ti wọn ko awọn ọmọogun France kuro, pẹlu gulegule awọn ajagunta lati orilẹede Russia to fidi kalẹ lagbegbe ọhun.
Lọsẹ yii nikan, awọn olugbe agbegbe naa ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin AFP pe ogoji araalu ni wọn ti pa lagbegbe Archam yii kan naa nibi tawọn ẹgbẹ alakatakiti ẹsin Islam, ninu eyi ti ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State wa, ti n gbe ina woju ara wọn.
Wo awọn igbesẹ to ti waye sẹyin lati pa ina ogun awọn alakatakiti ẹsin lorilẹede Mali:
Aimọye ọdun ni ina ogun alakatakiti ẹsin ti n jo orilẹede Mali labẹ aṣọ, eleyi to si fa iwọde nla kan tako aarẹ orilẹede naa nigba naa, Ibrahim Boubacar Keita lọdun 2020.
Iwọde awọn araalu yii si lo se okunfa ki awọn ologun wa fi ipa gba ijọba lọwọ rẹ pẹlu ileri pe awọn yoo da eto abo to dantọ pada.

Ṣugbọn pẹlu bi awọn alaṣẹ ijọba ologun lorilẹede naa ṣe kuna lati fi ẹnu ko pẹlu awọn ologun orilẹede France, ti wọn si yẹ adehun ti wọn ṣe lati da ijọba pada fun alagbada nipa ṣiṣeto idibo lọdun yii.
Eyi si ni yoo mu ki wọn ni aṣoju ijọba orilẹede Mali nibẹ amọ wọn faake kọri lori ipinnu wọn naa.
Eyi lo fa a ti orilẹede Mali fi paṣẹ pe ki gbogbo awọn ọmọogun France fi orilẹede naa silẹ, lẹyin nnkan bii ọdun mẹwaa ti wọn ti n koju awọn ọmọogun alakatakiti ẹsin nibẹ.
Pẹlu atilẹyin awọn orilẹede agbaye, paapaa lagbegbe Yuroopu, eto ipẹtu si wahala lorilẹede Mali ti wọn da pe ni 'takuba Task Force’ yoo ko ara rẹ lọ si orilẹede Niger.
Aarẹ orilẹede Niger ṣalaye ljọ Ẹti pe o daju pe aarẹ orilẹede naa pẹlu Mali, yoo kun fun ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ alakatakiti lẹyin ti orilẹede France atawọn alatilẹyin rẹ ti ko awọn ọmọogun rẹ kuro nibẹ.
Ṣaaju ni ọsẹ yii, awọn adari orilẹede lẹkun iwọ oorun Afrika ṣe ipade pẹlu aarẹ orilẹede France, Emmanuel Macron ṣaaju ikede kiko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Mali.
Nibẹ ni wọn si ti fohun ṣọkan pe ki awọn ọmọogun naa ko lọ sawọn orilẹede miran lẹkun ọhun.
















