Mr Latin sọ pé ìjọba àtàwọn òbí ló lẹ̀bi bí àwọn ọ̀dọ̀ ṣe ń ṣe oògùn owó

Oríṣun àwòrán, mrlatin1510
Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, Bolaji Amusan, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mr Latin ti sọ pe kii ṣe ẹbi awọn oṣere tiata ni bi awọn ọdọ ṣe n ṣe oogun owo laye ode oni.
Ọrọ naa lo jẹyọ lẹyin ti awọn iroyin bi awọn ọdọkunrin kan ṣe ge ori eeyan lọna fi ṣe oogun owom bẹrẹ si n fa ori ayelura ya.
Ninu atẹjade kan loju opo TAMPAN lori Instagram, Mr Latin sọ pe ẹbi ijọba ati awọn obi ti ko tọju awọn ọmọ wọn lọna to tọ ati eyii to yẹ ni, kii ẹbi awọn oṣere.
- "Bí ìdìbò abẹ́nú APC Osun ṣe ń lọ kò tẹ́ wa lọ́rùn... Wọ́n ṣá èèyàn ládàá ní Oriade"
- Wo ọ̀nà mẹ́sàn án tí o lè fi dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ewu epo bẹntiróòlù lásìkò yìí
- Wo àwọn obìnrin ''fijilanté" tí wọ́n ṣetán à ti kojú ẹnikẹ́ni ní Kano
- Wo àwòrán lóríṣìíríṣìí tó jádé níbí ètò ìsìnkú Adebayo Alao Akala
- Ó ṣe! tọkọtaya yìí papòdà láàrín oṣù mẹ́sàn-án síra wọn
- Sunday Igboho kò le wà ní àhámọ́ kí èmi máa ṣe wẹ̀jẹ-wẹ̀mu - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Wo ìlú tí wọ́n ti fòfin dé yíya àwòrán ṣaájú ìgbéyàwó ìyẹn "pre wedding picture" àti ètò ìgbéyàwó mìíràn
- Só lè jẹ búrẹ́dì tí wọ́n fi Aáyán se?
Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo oogun owo ti wọn maa n ṣe ninu ere lo maa n ni atubọtan, eyii ti yoo jẹ arikọgbọn fun awọn to ba wo ere naa.
O ni "Fun awọn to n da wa lẹbi, ibi ti wọn le ronu mọ niyẹn, mi o tii ri ere kankan ti ẹni to ṣoogun owo ninu rẹ ti lọ lai jiya ri."
"Lẹyin naa, a maa n sọ iye ọjọ ori awọn to le wo awọn ere wa, bii ẹni ọdun marundinlogun, tabi mejidinlogun, to n tumọ si pe ẹni ti ọjọ ori rẹ ko ba tii to ọdun marundinlogun ko gbọdọ wo irufẹ ere bẹẹ."
"A ko le sọ pe iwa ipa pọ nilẹ Amẹrika nitori bi wọn ṣe maa n yinbọn ninu awọn fiimi wọn, rara o! Ẹbi awọn obi ati ijọba ni."
Awọn obi ti kuna
Mr Latin tẹsiwaju pe "Awọn obi mii ko tilẹ ki n tọju awọn ọmọ wọn, ọmọ ọdun mẹtadinlogun mii yoo gbe ọkọ wa sile awọn obi rẹ ko si ni bere ibi to ti ri ọkọ ọhun."
Mr Latin sọ pe ko tọ ki awọn eeyan maa wo fiimu lai wo irufẹ fiimu bẹẹ pari ki wọn to maa da awọn lẹbi."
Lẹyin naa lo ṣeleri pe awọn gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣere yoo bẹrẹ si ṣe awọn ere ti yoo maa sọ nipa igba aye rere.














