Yoruba Nation: Sunday Igboho kò le wà ní àhámọ́ kí èmi máa ṣe wẹ̀jẹ-wẹ̀mu - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye, Olórí Ẹgbẹ̀ ìlànà ọmọ Oòduà

Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye, Olórí Ẹgbẹ̀ ìlànà ọmọ Oòduà ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, other

Olori ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede Yoruba, iyẹn Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ke sawọn ọmọ Yoruba lati maṣe sọ ireti nu lori iwasi imuṣẹ alaa rere naa.

Ọjọgbọn Akintoye sọ eyi di mimọ ninu ọrọ ajọdun ọjọ ibi rẹ to fi sita.

Ọjọgbọn Akintoye ṣalaye pe ilepa ti ko ṣai ni wa si imuṣẹ ni idasilẹ orilẹede Yoruba, ati pe ki gbogbo awọn ọmọ Yoruba to n foju ọna fun un o maa sọ ireti nu.

Ki tun ni Akintoye so?

O ni bi oun ṣe n wo o yii, ọna ti n la fun ominira ẹya Yoruba kuro labẹ orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Oja Odan nibi ti wọn ti dáná sún afurasi meji ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn

Akintoye ni lootọ gbogbo ijọba lorilẹede Naijiria le e maa lẹdi apo pọ lati sọ ijijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba lorukọ ti ko jẹ sibẹ, iduro ko si, bẹẹ ni ibẹrẹ ko si mọ o.

Àkọlé fídíò, Oyetola, Aregbesola àti Tinubu ni ọ̀rọ̀ náà wa láàrin wọn

Akintoye ni lootọ awọn eekan ọmọ Yoruba kan gbiyanju ati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi fun oun ṣugbọn oun kọ jalẹ ni nitori pe oun ko lee maa ṣe wẹjẹwẹmu nigba ti ọkan gboogi lara awọn to n ja ija naa, iyẹn oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho wa ni ahamọ.

Àkọlé fídíò, Aeroplane House: Látọdún 1999 ni mo ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí fún ìyàwó mi ọ̀wọ́n

Akintoye: "A ko ni sinmi ija naa, koda bi ijọba Naijiria tẹsiwaju pẹlu wahala ibanilorukọ rẹ lori ijijagbara wa.

A ko ni gba ijọba Naijiria laaye lati sọ ijijagbara wa lorukọ daran.

Ki gbogbo ọmọYoruba lagbaye o ma sọ ireti nu lori rẹ."

Àkọlé fídíò, Segun iberu