Osun APC Primary: Àwọn jàndùkú da ìdìbò rú ní Ede àti Osogbo, wọ́n ṣá èèyàn ládàá - Adelani Baderinwa

Aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Osun, Adelani Baderinwa, ti sọ pe inu oun ko dun si bi eto idibo abẹnu sipo gomina ninu ẹgbẹ ọhun ṣe n lọ.
Adelani lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba.
O ni ọpọlọpọ eeyan ni ko le dipo bo tilẹ jẹ pe wọn ni kaadi lọwọ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ, amọ orukọ awọn eeyan naa ko si ninu iwe iforukọsilẹ ti awọn to n ri si eto idibo naa gbe lọwọ.
- Kìí ṣe ẹ̀bi àwa òṣèré tíátà pé àwọn ọ̀dọ̀ ń kánjú wá owó - Mr Latin
- Wo àwọn obìnrin ''fijilanté" tí wọ́n ṣetán à ti kojú ẹnikẹ́ni ní Kano
- Ó ṣe! tọkọtaya yìí papòdà láàrín oṣù mẹ́sàn-án síra wọn
- Sunday Igboho kò le wà ní àhámọ́ kí èmi máa ṣe wẹ̀jẹ-wẹ̀mu - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Wo ìlú tí wọ́n ti fòfin dé yíya àwòrán ṣaájú ìgbéyàwó ìyẹn "pre wedding picture" àti ètò ìgbéyàwó mìíràn
Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo orukọ awọn alatilẹyin fun igun gomina lo wa ninu iwe iforukọsilẹ naa, amọ orukọ awọn to n ṣatilẹyin fun awọn oluije mii nikan lo poora.
Adelani sọ siwaju si pe awọn janduku kan tun kọlu awọn eeyan lawọn ibudo idibo kan bii "Ward 2" to wa niluu Ede, atawọn ibudo idibo mii.
O ni "Kii ṣe iyẹn nikan ni, aimoye awọn janduku ti wọn n ko kaakiri."
"Ni ijọba ibilẹ Ori Ade, wọn ṣa eeyan lada nibẹ, bakan naa ni wọn ṣe ni ijọba ibilẹ Osogbo amọ ọga wa ti sọ fun wa pe ki a ma ba ẹnikẹni ja."
"Bi eto idibo yii ṣe n lọ bayii ko tẹ wa lọrun."
Adelani tun fẹsun kan awọn alatilẹyin gomina to wa lori alefa, iyẹn Gboyega Oyetola pe awọn gan ni eku ẹda to n da omi alafia eto idibo ọhun ru.
Ki ni ọlọpaa sọ
Nigba ti BBC Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, wọn ni lootọ ni awọn kudiẹ-kudiẹ kan waye ninu eto idibo naa.
Alukoro ileeṣẹ ọhun, Yemisi Opalola sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni awọn idojukọ kan waye ni Ede, amọ awọn ti yanju rẹ.
O fi kun pe asiko ti eto idibo naa ṣẹṣẹ bẹrẹ ni awọn dojukọ awọn kudiẹ-kudiẹ naa amọ awọn ti panọ wahala ọhun bayii.
Ẹwẹ, Opalola ko sọ ohunkohun nipa pe boya wọn ṣa ẹnikẹ ni ada tabi boya ẹnikẹni farapa nibi eto idibo naa.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ìdìbò abẹ́nú APC bẹ̀rẹ̀ l'Osun

Eto idibo abẹnu lati yan oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Ọṣun ti bẹrẹ.
Gẹgẹ bi ab awọn aṣojukọroyin BBC nipinlẹ Ọṣun.
Iroyin atawọn aworan to jade kaakiri awọn ibudo idibo to wa nibẹ fihan pe kẹtikẹti lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC jade wa dibo fun ẹni to wu wọn lọkan lati gbe aṣia ẹgbẹ oṣelu naa lasiko ti idibo sipo gomina ni ipinlẹ naa yoo fi waye ni loṣu keje ọdun 2022.
Awọn oludije mẹta lo n lakaka lati di aṣia ẹgbẹ oṣelu na mu nibẹ - Lasun Yusuf, Moshood Adeoti ati gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetla.
Ki lo ṣẹlẹ ni ibudo idibo awọn oludije?

Lati Wọọdu Gidigbo II, unit 003, ilu Iwo nipinlẹ Ọṣun. Nibi ti akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun tẹlẹri, Alhaji Mọṣhood Adeoti yoo ti dibo.
Awọn alatilẹyin rẹ ti kun inu ọgba ibi ti idibo naa yoo ti waye, ayẹwo oludibo ṣi n lọ lọwọ.
Adeoti ni ẹni ti igun Aregbẹṣọla fa ọwọ rẹ soke lati dije dupo gomina ipinlẹ Ọṣun.
Bakan naa ni ẹni to jẹ igbakeji olori ile aṣofin-ṣoju nigbakan ri, Họnọrebu Lasun Yusuf naa ti gunlẹ si ibudo idibo tirẹ pẹlu ni nnkan bii agogo mọkanla owurọ nibi ti omilẹgbẹ awọn ọmọẹgbẹ ti wa nikalẹ lati dibo wọn.
ki lawọn iṣẹlẹ to ti n waye ṣaaju idibo abẹnu yii?
Ẹgbẹ oṣelu 'All Progressives Congress', APC ipinlẹ Ọṣun ti n gbaradi lati yan ọmọ oye ti yoo gbe asia ẹgbẹ ninu eto idibo si ipo gomina ti yoo waye ninu oṣu keje ọdun yii.Awọn oludije mẹta ọtọọtọ ti yoo fi iga gbaga ninu eto idibo abẹnu naa ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun tẹlẹri, Alhaji Mọshood Adeoti, ati igbakeji alaṣẹ ile igbimọ aṣoju-ṣofin
tẹlẹri, Họnọrebu Lasun Yusuf.Awọn mẹtẹẹta sini wọn pejupesẹ sibi ipade awọn alẹnuọrọ to waye ni ile ẹgbẹ oṣelu naa l'ọjọ Ẹti nilu Oṣogbo.
Ohun ti ipade naa da le lori ni ijiroro laarin awọn oludije ati atupalẹ bi eto idibo naa yoo ṣe lọ.
- Ẹnikẹ́ni tó bá tún fi ìyà jẹ òṣìṣẹ́ LASTMA l'Eko yóò fojú winá òfin- Ọ̀gá LASTMA
- Ìyá ẹni ọdún 102 kéde ìpinnu rẹ̀ láti díje du ipò Ààrẹ Naijiria lọ́dún 2023
- Yàtọ̀ sí Bimbo Success àti Kemi Korede, wo àwọn míì tí wọ́n ń pariwo Funke Akindele kiri
- Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ láti yé da àlááfíà ìlú láàmú- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun sí Aregbesola
- Ǹjẹ́ ó mọ̀ nípa Álífábẹ́ẹ̀tì Oduduwa àti bí o ṣe lè lòó fi gbé èdè Yorùbá ga?
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Àwọn tọ́ọ̀gì Aregbesola ló da wàhálà sílẹ̀ l'Osun - Ọlọ́pàá
Tani yoo ṣeto naa bii konkaari eleto idibo ẹgbẹ APC Osun lonii?Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRazak AbdulRahmon ti o jẹ alaga igbimọ ti yoo tukọ eto idibo naa fi idi ọrọ mulẹ pe gbogbo awọn oludije ni yoo ni anfani lati dije ti ko sini si ojusaaju kankan bo ti n wu ki o mọ.
Bakan naa ni akọwe igbimọ naa, Sẹnetọ Julius Ucha ṣe alaye pe ilana ti awọn oludibo yoo fi maa to si ẹyin ẹni ti wọn ba fẹ dibo fun, iyẹn 'Direct Primary' ni wọn yoo ṣe amulọ rẹ ninu eto idibo naa.
Nibo ni eto idibo a ti waye?
Awọn oriko ti eto idibo naa yoo ti wa jakejado ipinlẹ Ọṣun jẹ ọọdunrun ati mejilelọgbọn(332).
Awọn oludije yoo maa to fun ibo ni wọọdu onikaluku wọn. Aworan ati aṣoju wọn yoo si jẹ gbigbe kalẹ ni awọn oriko idibo mii.

Bawo ni eto idibo naa yoo ṣe lọ?Iforukọ awọn oludibo yoo waye laarin aago mẹsan owurọ si mejila ọsan.
Lẹyin eyii sini eto idibo yoo bẹrẹ ni pẹrẹu.

Alaga ọgbẹ oṣẹlu naa, Ọmọọba Gboyega Famoodun ṣe alaye fun akoroyin wa pe onikaluko lo ni ẹtọ lati dibo fun ẹnikẹni ti o ba wuu ninu idibo abẹnu naa.
O ni awọn ẹṣọ aabo yoo maa duro wamuwamu jakejado awọn oriko idibo lati rii dadju pe wahala kankan ko ṣẹlẹ.















