Kano female vigilante: Wo àwọn obìnrin ''fijilanté" tí wọ́n ṣetán à ti kojú ẹnikẹ́ni ní Kano

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ló máa ń sọ wí pé kò sí ohun tí ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin pàápàá jùlọ lóde òní.
Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn kan tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn iṣẹ́ kan kìí ṣe ohun tí obìnrin le ṣe ṣùgbọ́n èyí ti ń yí padà lóde òní nítorí a ti ń rí obìnrin tó ń tún ọkọ̀ ṣe, obìnrin tó ń kanlé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ à ti pe àìrìn jìnà làìrí abuké ọ̀kẹ́rẹ́.
Ní ìlú Kano, àwọn obìnrin kan ti ń ṣe bẹbẹ bí wọ́n ṣe darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọladẹ fìjilanté lójúnà à ti pọn kún ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ náà.
- Àwọn aláṣẹ UK ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn nítorí ìjì líle
- Ó ṣe! tọkọtaya yìí papòdà láàrín oṣù mẹ́sàn-án síra wọn
- Sunday Igboho kò le wà ní àhámọ́ kí èmi máa ṣe wẹ̀jẹ-wẹ̀mu - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye
- Wo ìlú tí wọ́n ti fòfin dé yíya àwòrán ṣaájú ìgbéyàwó ìyẹn "pre wedding picture" àti ètò ìgbéyàwó mìíràn
- Gboyega Oyetola, Moshood Adeoti àti Lasun Yusuf ni yóò jọ ná an tán bí owó lónìí láti mọ ẹni ti yóò dupò gómìnà Osun
- Wo àwòrán lóríṣìíríṣìí tó jádé níbí ètò ìsìnkú Adebayo Alao Akala
- Só lè jẹ búrẹ́dì tí wọ́n fi Aáyán se?
Nígbà tó ń sọ ipa tí wọ́n ń kó sí ríri pé àdínkù bá ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Kano, Aisha Abubakar, ọ̀kan lára àwọn obìnrin fijilanté náà ní àwọn kìí bẹ̀rù láti nawọ́ gán ẹnikẹ́ni tó bá tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.
Aisha Abubakar ní ohun tó mú òun darapọ̀ mọ́ fijilanté ni láti kó ipa tirẹ̀ lórí mímú àdínkù bá ìwà ọ̀daràn àti pé àwọn obìnrin ní ipa tó lóòrìn tí wọ́n ń kó sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.
Ó ní iṣẹ́ àwọn dàbí ti àwọn ológun tí kò sí pé ọkùnrin tàbí obìnrin ló le ṣe iṣẹ́ kan, gbogbo àwọn ni àwọn jọ ní àfojúsùn kan náà.
Kini awọn akọni fijilante yii tun sọ?
Bákan náà ló ní àwọn kìí bẹ̀rù láti mú ọ̀daràn ìbáà ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin ní wọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti hu ìwà ọ̀daràn, àti pé wọ́n máa ń bẹ̀rù àwọn nítorí ọ̀daràn máa ń bẹ̀rù ẹni tí tó bá jẹ́ agbófinró.
Ẹlòmíràn tí òun náà jẹ́ fijilanté obìnrin tó bá BBC Pidgin sọ̀rọ̀, Hadiza Tanko ní nítorí bí àwọn ọ̀dọ̀ ṣe ń ṣàmúlò egbògi olóró ló mú òun darapọ̀ mọ́ fijilanté.
Tanko ní ó máa ń rọrùn fún àwọn obìnrin láti ṣe ìwádìí lábẹ̀nú ju ọkùnrin lọ nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn máa ń finú tán obìnrin púpọ̀.
Ẹni kẹta wọn, Zuwaira Abdullahi ní ohun tó fún òun ní ìwúrí láti ṣiṣẹ́ òun bí iṣẹ́ ni àtìlẹyìn tí ọkọ̀ òun fún òun láti darapọ̀ mọ́ fijilanté.
Abdullahi ní ọjọ́ tí òun kò le gbàgbé lẹ́nu iṣẹ́ náà ni ọjọ́ tóun ká ọkùnrin kan mọ́ ilé àkọ́kù tó fẹ́ bá ọmọdébìnrin kan tó ń kiri oúnjẹ ní ìbálòpọ̀.
Abdulahi ṣàlàyé pé ọmọdébìnrin náà ń bẹ̀rù à ti padà sílé nítorí ó ní ìyá òun máa na òun wí pé òun kò ta oúnjẹ tí òun kiri lọ tán.
"Ọkùnrin náà wá ṣèlérí fún un láti fun ní gbogbo oúnjẹ tó kiri owó tó bá gbà láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú òun, níbẹ̀ láti nawọ́ gan.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, sgá àgbà fijilanté ní Kano, Shehu Rabiu ní ìdí tí àwọn fi dá ẹ̀ka ti àwọn obìnrin sílẹ̀ ni pé àwọn obìnrin ní ipa to pọ̀ láti kó sí mímú àdínkù bá ìwà ọ̀daràn láwùjọ.
Rabiu ní gbogbo ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó yẹ àti èyí tí wọ́n nílò láti ṣe iṣẹ́ wọn dójú àmì ni àwọn ti fún wọn pẹ̀lú èròńgbà pé ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin yóò tún darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ náà.
Fijilanté ní Nàìjíríà
Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ètò ààbò, Isa Hashidu ṣe wí, ó ti lé ni ogún ọdún tí wọ́n dá fijilanté sílẹ̀ láti máa dọdẹ àdúgbò tí wọ́n sì forúkọ lábẹ́ òfin.
Àwọn ará àdúgbò tí wọ́n ń dọdẹ ló sábà máa ń jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ wọn.
Gbogbo ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ sí.
Bákan náà ni wọ́n ní ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́nrán pẹ̀lú àjọ ọlọ́pàá láti dá ààbò bò àwọn ará ìlú.
Ènìyàn tó bá ti pé méjìdínlógún ló le darapọ̀ mọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí òfin wọn ṣe làá kalẹ̀.






















