Storm Eunice: Àwọn aláṣẹ UK ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn nítorí ìjì líle

Oríṣun àwòrán, PA Media
Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà bí ìjì líle, "Storm Eunice" ṣe ń ṣọṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Ìgbà kèjì rèé tí ilé iṣẹ́ Di Met ń ṣèkìlọ̀ lórí ìjì líle fún ìlú London, gúúsù ìlà oòrùn, ìlà oòrùn England, àwọn apá kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn England àti gúúsù Wales.
Ìkìlọ̀ yìí ni Di Met ní ó túmọ̀ sí pé àwọn nǹkan tí ìjì yìí le gbé le ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn.
- Èèyàn mẹ́tàdínlógún jóná nínú ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Algeria yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san N41,000 fáwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lóṣù tó ń bọ̀
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Wo àwọn ibùdó mánigbàgbé tó wà ní Ajaṣe ni orilé-èdè Benin Republic níbi tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ti lọ ṣàbẹ̀wò
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè
- Ṣé lóòtọ́ ni abẹ́ Venus Williams ẹni ọdún 41 ṣì dí pa, tí kò tíì bá ọkùnrin kankan lájọṣepọ̀ rí?
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n ti tì pa, gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú irin ní Wales kò ṣiṣẹ́ mọ́ báyìí, tí àwọn ọmọ ogun náà sì ti wà ní sẹpẹ́.
Ẹ̀ka tó ń rí sí ìwòye ojú ọjọ́ BBC ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ ìjì tí yóò burú júlọ fún UK láàárín ọgbọ̀n ọdún.
Ìjì Eunice ni ìjì líle kejì tó ń wáyé ní UK lẹ́yìn tí ìjì Dudley ṣọṣẹ́ ní àwọn apá kan Scotland, àríwá England àti àríwá Ireland, níbi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ti níná ní ilé mọ́.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Irú ìkìlọ̀ yìí sábà wáyé nítorí ó túmọ̀ sí pé òrùlé ilé le ṣí, òpó iná le wó, tí àwọn igi sì le hú.
Nínú oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá ní irúfẹ́ ìkìlọ̀ báyìí fún ìjì Arwen ti wáyé.
Awòṣakun ojú ọjọ́ BBC, Ben Rich ní ìjì líle Eunice yóò fa wàhálà ṣùgbọ́n òun kò mọ bí ó ṣe le pọ̀ tó.
Derek Brockway ní ìjì Eunice kìí ṣe hurricane ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí ọwọ́ rẹ̀ yóò bá ti hurricane.
Di Met ní kí àwọn ènìyàn ṣọ́ra fún rínrin ìrìnàjò.
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ṣáájú ìdìbò abẹ́nú gómìnà ẹgbẹ́ APC ní ìpínlẹ̀ Osun lọ́la
- Ìyá ẹni ọdún 102 kéde ìpinnu rẹ̀ láti díje du ipò Ààrẹ Naijiria lọ́dún 2023
- Ẹnikẹ́ni tó bá tún fi ìyà jẹ òṣìṣẹ́ LASTMA l'Eko yóò fojú winá òfin- Ọ̀gá LASTMA
- Wo ohun tí ìjọba ṣe fún akẹ́kọ̀ọ́ kílààsì SS 2 tó gbá Olùkọ́ létí ní Ibadan
- Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji
- Amotekun Ondo gbẹ́sẹ̀lé ọkọ̀ àjàgbé tó ń kó àwọn ọ̀dọ́ 63 láti Gombe lọ sí Eko
- EFCC gbẹ́sẹ̀lé dúkìá ọ̀gá olọgun tí iye rẹ̀ tó ₦10.9b















