Amotekun Ondo mú àwọn ọ̀dọ́kùnrin 63, alùpùpù 25 tó ń bọ̀ láti Gombe sí Eko

Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Vibemusic_inc

Ikọ Amotekun ipinlẹ Ondo ti gbẹsẹle ọkọ tirela kan to n ko awọn ọdọ ti iye wọn ko din ọgọta lati iha Ariwa Naijiria lọ si ipinlẹ Eko.

Iṣẹlẹ naa waye ni ilu Iju, to wa laarin ilu Ado Ekiti si ilu Akure.

Awọn ọdọkunrin naa, ti wọn jẹ mẹtalalọgọta sọ pe ipinlẹ Gombe ni awọn ti n bọ ki ikọ Amotekun to da awọn duro lọna.

A gbọ pe ọkunrin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Salisu Ahmed ni awakọ tirela naa to ni nọmba iforukọislẹ "Kano AB234BDJ."

Wayi o, Amotekun ti wa ko awọn eeyan naa lọ si olu ileeṣẹ rẹ to wa niluu Akure lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣayewọ tirela naa finifini.

Àkọlé fídíò, Segun iberu

Adari ikọ ọhun, Adetunji Adeleye ni yatọ si awọn ọdọkunrin mẹtalelọgọta naa, tirela ọhun tun ko ojilenigba (240) àgbò, alupupu mẹwaa ti wọn fi orukọ rẹ silẹ ni orukọ ọmọ Yoruba, ati alupupu marundinlogun mii ti wọn ko fi orukọ rẹ silẹ rara.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Adeleye ni Amotekun yoo ri daju pe awọn ọdọkunrin naa pese ẹri to dantọ nipa awọn to ni awọn alupupu naa, lẹyin naa ni awọn yoo fi wọn silẹ ki wọn le maa ba irinajo wọn lọ.

O fi kun pe awọn yoo ṣe iwadii ni kikun lori iṣẹlẹ naa siwaju si.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Idi ti Amotekun fi mu awọn arinrinajo naa

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ikọ Amotekun ipinlẹ Ondo yoo mu awọn arinrinajo lati iha Ariwa Naijiria ni ipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

Gẹgẹ bii awọn iṣẹlẹ to ti ṣẹlẹ sẹyin pẹlu ẹri to dantọ, nigba mii awọn arinrinajo bẹẹ maa n ko awọn ohun ija oloro pamọ sinu ẹru wọn.

Fun apẹẹrẹ, lọjọ karun un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, ọwọ ikọ Amotekun Ondo tẹ awọ arinrinajo mejidinlogun pẹlu ẹẹdeẹgbẹta (500) ibọn, oniruru ọbẹ ti wọn ko pamọ sinu ẹru wọn.