Anti-vaccine mandate protests: Canada ṣetán láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáùntì àwọn tó ń ṣẹ ìwọ́de táko abẹ́rẹ́ covid-19

Awọn oluwọde ni Canada

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olootu ijọba orilẹede Canada, Justin Trudeau ti kede pe ijọba yoo gbẹsẹ le akaunti gbogbo awọn to n ṣe iwọde tako gbigba abẹrẹ ajẹsara covid-19.

Trudeau ṣalaye pe awọn ile ifopamọ le gbẹsẹ le akaunti awọn to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde tako abẹrẹ covid-19.

Ọgọọrọ awọn olouwọde ni wọn ti n fi ẹhonu han tako gbigba abẹrẹ coronavirus.

Awọn agbofinro lo tu awọn oluwọde naa ka ni Windsor lọjọ Aiku to kọja.

Iwọde to bẹrẹ lati tako ikede ijọba pe gbogbo awọn to wa ọkọ akẹru nla ti wọn n gba ibode Canada ati Amẹrika kọja gbọdọ gba abẹrẹ covid-19.

Amọ ifẹhonuhan naa ti di ohun ti wọn n fi tako gbogbo eto ijọba lati dẹna coronavirus bayii.

Àkọlé fídíò, Kong Thong: Àwọn òbí máa ń súfèé kọrin tàbí hu láti pe ọmọ tó bá dàgbà

Trudeau ni ''igbesẹ yii wa lati ri pe awọn eeyan Canada ko si ninu ewu.

Bakan naa ni a tun n ṣe eleyii lati daabo bo iṣẹ awọn eeyan ni Canada.''

Olootu ijọba ilẹ Canada ni ijọba yoo fawọn ọlọpaa ni irinṣẹ ti wọn nilo lati ju awọn oluwọde si atimọle ati lati daabo bo ohun amayedẹrun.

Ọpọ koro oju si Trudeau lori igbesẹ rẹ lẹyin ti wọn lo ṣe atilẹyin fawọn agbẹ ti wọn di ọna mọrosẹ ni India lọdun 2021 lasiko ti wọn n ṣe iwọde.

Wọn ni Trudeau lo fẹnu ara rẹ sọ pe Canada ko le ṣalai ṣe atilẹyin fawọn to n ba ṣe iwọde wọọrọwọ.

Àkọlé fídíò, Ìdíje ata tútù: Jẹ ata 50, ko gba góólù gírámù mẹ́ta

Igbakeji olootu ijọba Canada naa, Chrystia Freeland sọ pe awọn banki le gbẹsẹ le akaunti ẹnikẹni to ba kopa ninu ifẹhonuhan ọhun.

Freeland fikun ọrọ rẹ pe iwe adojutofo ọkọ ẹnikẹni to ba ni ohun kan ṣe pẹlu iwọde naa le ni idaduro fun igba diẹ.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Freeland ni ijọba n lo eleyii lati mọ awọn to n pese owo fawọn oluwode.

O sọrọ yii lẹyin tawọn onijibi ori ayelujara sọ pe eeyan ẹgbẹrun lọna mẹtalelaadọrun lo ṣe irawọn owo to le ni miliọnu mẹjo ($8.4m) fawọn awakọ nla akẹru.

Àkọlé fídíò, Yinka Ayefele: Ìrọ́ ni pé ń kò le ṣe bíi ọkùnrin, mò ń ta pútú dàadáa