Ibadan Bullion Van Robbery: Àwọn aráàlú sọ bí ìdigunjalè ṣe wáyé ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì ọdún 2022 jẹ́ fún àwọn olùgbé ìlú Ibadan pàápàá àwọn ara Idi-Ape.
Ní ọ̀sán ọjọ́ yìí ni àwọn ìgárá ọlọ́ṣà, alọ kólóhun kígbe, ní nǹkan bí aago méjì ọ̀sán kú ìṣẹ́jú márùndínlọ́gbọ̀n, ṣe ìkọlù sí ọkọ agbówórìn ilé ìfowópamọ́ kan ní oríta Idi Ape, Iwo road, Ibadan.
Ọlọ́pàá méjì àti ara ìlú kan àti ọ̀kan nínú àwọn adigunjalè, ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí lọ.
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ àgbáyé ṣé ní kí Uganda sàn $325m fún DR Congo
- Fásìtì yóò fí $250m gbára torí aṣemáṣe dókítà rẹ̀ pẹlu obìnrin
- TAMPAN ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Tafa Oloyede bí ètò ìsìnkú rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ lónìí
- Ìjọba Oyo gba adé lórí àwọn baálẹ́ àti Mogaji tí Ajimọbi sọ di ọba ní Ibadan
- Mo ní ẹ̀ṣọ̀ ara tó lé ní ₦300m láyé àkọ́kọ́, ti mo ń gbé òògùn olóró
- Àìsàn wo ló ń ṣe Opeyemi Ayeola tó tún fi dèrò ilé ìwòsàn?
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣe ojú wọn ṣe wí, iná adarí ọkọ̀ tó wà ní Idi Ape ló dá ọkọ̀ agbówórìn tó ń gbé owó lọ láti ilé ìfowópamọ́ kan lọ sí òmíràn ní agbègbè Géètì dúró lásìkò tí àwọn adigunjalè náà fi rí ààyè ṣe ìkọlù sí wọn.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ọwọ́ adigunjalè dun àwọn ọlọ́pàá torí wọn pọ ju àwọn ọlọ́pàá lọ:
Lára àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sọjú rẹ̀ sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọkọ̀ Toyota Sienna ni àwọn adigunjalè náà fi dẹ́bùrú ọkọ̀ agbówórìn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dáná ìbọn yá àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà láì bèṣù gbẹ̀gbà.
O ní àwọn adigunjalè àti àwọn ọlọ́pàá tó tẹ̀lé ọkọ̀ agbówórìn náà kojú ìbọn síra wọn, ṣùgbọ́n tí ọwọ́ àwọn adigunjalè náà dun àwọn ọlọ́pàá nítorí àwọn adigunjalè náà pọ̀jù àwọn ọlọ́pàá lọ.
Nígbà tí wọ́n kojú ara wọn yìí, ní ìbọn ba ọlọ́pàá méjì tí wọ́n sì bá ibẹ̀ lọ sọ́run àrèmabọ̀, tí ọlọ́pàá mìíràn sì tún farapa.
Ina lo da ọkọ agboworin duro, ti awọn adigunjale fi raye kọ lu u:
Bákan náà ló ní àwọn adigunjalè náà kàn ń yìbọn sókè láti lé dẹ́rù ba àwọn ènìyàn láì bìkítà, àwọn ara ìlú tí ìbọn sì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tó wà nínú ọkọ̀ wọn, tí iná dá dúró papọ̀ mọ́ ọkọ̀ agbówórìn náà.
Lára àwọn tí ìbọn bá ni ọlọ́kadà kan tó fẹ́ gbìyànjú à ti tètè gba ìwájú ọkọ̀ àwọn adigunjalè náà láì mọ̀ pé àwọn ìgárá ọlọ́ṣà, alọ kólóhun kígbe ló wà nínú ọkọ̀ náà tí wọ́n sì dáná ìbọn yá a tó sì gbabẹ̀ rọ̀run alákeji.
Yàtọ̀ sí àwọn tó kú wọ̀nyìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn ló tún farapa tí wọ́n ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn lọ́wọ́ látàrí ìbọn tó bà wọ́n níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Awọn adigunjale gbe owo tabua lọ ninu ọkọ adigunjale:
Ẹlòmíràn tí òun náà bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí kò dá orúkọ ara rẹ̀ ní owó tabua ní àwọn ìgárá ọlọ́ṣà náà gbé lọ, ṣùgbọ́n títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn jọ, a kò le fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé iye báyìí ni owó náà jẹ́.
Ohun tí ikọ̀ ìròyìn BBC Yorùbá tún le fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ ni pé, lẹ́yìn tí àwọn adigunjalè yìí ṣọṣẹ́ ní Idi Ape tán, Onípẹ́pẹ́yẹ lọ́nà Old Ife road ni wọ́n morile.
Ibẹ si ni wọn gbà já sí òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan, nibi tí wọ́n gbà sá lọ.
Lásìkò tí wọ́n dé òpópónà Onípẹ́pẹ́yẹ lọ́nà Old Ife road yìí, tí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ mú wọn níbẹ̀, ni wọ́n tún dàbọn bolẹ̀ tí àwọn ènìyàn sì tún fara gbọta níbẹ̀, tí wọ́n sì ṣèṣe gidi.

Ọlọ́pàá méjì kú sílé ìwòsàn lẹ́yìn ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn tó wáyé n'Ibadan - Ọ́lọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti fọrọ sita pe ọlọpaa meji lo pada jade laye lẹyin ikọlu idigunja ọkọ agboworin to waye nilu Ibadan l'Ọjọbọ.
Atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ fi sita ṣalaye pe igba ti wọn gbe awọn ọlọpaa mẹfa ati araalu meji de ileewosan ni meji ninu awọn ọlọpaa naa pada wa jade laye nileewosan.
Ṣaaju ni kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ Ngozi Ọnadẹkọ ti kede lasiko abẹwo rẹ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lagbegbe Idiapẹ nilu Ibadan pe ko si ọlọpaa kankan to tii ku nigba naa.
Awọn adigunjale kan kọlu kọ agboworin kan to n gbe owo lati banki kan lagbegbe Idi- Apẹ nilu Ibadan ni nnkan bii agogo meji ku iṣẹju marundinlogun lọsan Ọjọbọ.
Pẹlu ikede yii, eeyan mẹrin lo ti ba iṣẹlẹ idigunjale yii l bayii- ọlọpaa meji, araalu kan, ati ọkan ninu awọn adigunjale naa ti awọn ọlọpaa yinbọn pa ṣugbọn ti awn akẹgbẹ rẹ gbe oku rẹ salọ.
ọlọpaa meji ataraalu meji lo n gba itọju bayii nile iwosan fun ọgbẹ ọta ibọn.
A o tubọ jawe sobi ijafafa si ipe pajawiri- Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Bakan naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti kan sara sawọn agbofinro to n fi ẹmi wọn la iku nigba gbogbo fun idaabo bo araalu.
O ṣeleri pe ijọba yoo tubọ maa jawe sobi ijafafa si ipe pajawiri ni ipinlẹ naa.
O gboṣuba fawọn araalu to pe nọmba ipe pajawiri 615 ipinlẹ naa lasiko ti idigunjale naa fi bẹrẹ.
O fi kun un pe awọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa eleyi to la ẹmi lọ.
Ki lo ti waye sẹyin:
Isẹlẹ idigunjale kan lo waye ni Ọjọbọ ladugbo Idi-Ape nilu Ibadan.
Awọn adigunjale naa ni wọn n gbinyanju lati ja ọkọ banki kan to n gbe owo rin, lẹyin o rẹyin, wọn ko owo inu mọto naa, ti wọn si fi ẹsẹ fẹ.
Se ni awọn adigunjale naa n yinbọn laibikita, ti ọpọ ọta ibọn si wa ni ara ọkọ ọlọpaa to n tẹle ọkọ banki agboworin naa.
Asiko yii si ni ọta ibọn ba ọlọpaa meji to wa ninu ọkọ agboworin, ti wn si pada ku sile iwosan.
Bakan naa ni ẹmi araalu bọ, ti ọpọ eeyan si fara pa lasiko isẹlẹ naa.


















