Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Gbajumọ akọ̀rin taka n sufe nni, Olorunyomi Oloruntimileyin Timothy, ti ọpọ eeyan mọ si Bad Boy Timz ti saalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ ọlọpaa.

Bad Boy, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lo salaye bo se bọ si ọwọ ọlọpaa ati awọn ohun ti oju rẹ ri ko to bọ nibẹ.

Ninu akanse ifọrọwanilẹnuwo naa lo tun ti sọ nipa igbe aye rẹ, bo se de idi isẹ orin kikọ atawọn ohun to n gbero lọjọ iwaju.

Bad Boy Tims yii lo kọ orin takansufe ‘Gbẹsẹ lọọkọkan’ to lu igboro pa.

Orin yii si lo jẹ itẹwọgba gidi laarin awọn ọdọ ati agbaagba pẹlu, ti wọn maa n kọ tabi jo si ni gbogbo igba.

Bawo ni Bad Boy Timz se se kongẹ ọlọpaa:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Bad Boy ni ọjọ ti oun ko le gbagbe laye oun ni ọjọ ti awọn ọlọpaa gbe oun.

O ni ọrọ oun ati awọn tawọn jọ n gbe orin jade ni ko ye ara wọn.

O ni lootọ ni oun lo ọdun meji pẹlu ileesẹ naa, amọ wọn ko ri oun ti oun ri, idi si ree ti oun se ni ki awọn maa lọ ni ọtọọtọ.

Bad Boy ni isẹlẹ naa ko oun ni aya soke amọ gbogbo rẹ ti pari bayii.

Akọrin naa tii se ọmọ bibi ilu Ondo ati ọmọ kẹta fun awọn obi rẹ ni oun ko le ro iru isẹlẹ bi ọlọpaa se gbe oun naa, kan ọta mi laelae.

Bawo ni orukọ Bad Boy Timz se waye?

Akọrin taka n sufe naa, nigba to n salaye ibi to ti ri orukọ Bad Boy Timz ati idi to se n jẹ orukọ naa ni nibẹrẹ pẹpẹ, Timz nikan ni orukọ ti oun maa n lo.

Akọrin naa, ti wọn bi, to si tun dagba silu Ikorodun ni oun fi Bad Boy kun orukọ naa nitori ọpọ eeyan lo n lo Timz.

O ni orukọ oun meji, eyiun Timileyin ati Timothy ni oun papọ sọ di Timz.

Bawo ni Bad Boy Timz se bẹrẹ orin kikọ?

Timz ni inu ẹjẹ oun ni orin kikọ wa nitori baba oun maa n kọ orin Tungba.

Lati kekere si ni oun ti maa n tẹle baba oun lọ kọrin, idi si ree ti orin kikọ se di ajẹbi fun oun.

Bakan naa lo mẹnuba awọn agba akọrin to wa niwaju bii Nice, Sunny Ade, Mohits gẹgẹ bii awọn awokọse to wo, to fi pinnu lati gbe igba orin kikọ.

Orin wo lo sọ Bad Boy di ilumọọka?

Gbajumọ akọrin naa ni orin ‘Gbẹsẹ lọkọọkan’ lo sọ oun di ilumọọka, eyi ti tọmọde tagba tẹwọ gba.

“Igba ti mo wa nile ẹkọ fasiti ni orin naa di itẹwọgba amọ lẹyin ti arun Coronavirus de, ile ni orin ti n lọ sile iwe, titi ti oun fi setan.

Awọn ipenija ti mo ri nidi isẹ orin kikọ ree:

Nigba to n mẹnuba ọpọ ipenija to ti koju rẹ nidi isẹ orin kikọ, Bad Boy ni owo lo kọkọ jẹ ipenija fun oun lati gbe awo orin jade.”

O wa fi ọwọ gbaya pe oun si maa tobi si, ti ọpọ ipenija miran yoo si tun wa.

Ta ni Bad Boy Timz?

Ọjọ Kẹtala osu Kẹjọ ọdun 1999 ni wọn bi akọrin Bad Boy Timz silu Ikorodu nipinlẹ Eko amọ ọmọ bibi ilu Ondo ni awọn obi rẹ.

Orukọ abisọ rẹ ni Olorunyomi Oloruntimileyin Timothy, to si yan isẹ orin kikọ laaye lati kekere nitori baba rẹ naa jẹ akọrin.

Ẹkọ nipa imọ ẹrọ ayarabiasa (Computer Engineering) lo kọ jade nile ẹkọ fasiti aladani Bells amọ idi isẹ orin kikọ lo ti di gbajumọ.

Oun lo kọ awo orin Gbẹsẹ lọkọọkan, to si gba ami ẹyẹ lorisirisi nidi isẹ orin kikọ.