Opeyemi Ayeola: Gbàjúmọ̀ òṣèré tíátà sọ̀rọ̀ sókè lórí ìlera rẹ̀, ó ní Ọlọ́run ló kó òun yọ

Opeyemi Aiyeola wanile iwosan ti wọn n fa omi si lara

Oríṣun àwòrán, opeyemi_aiyeola1

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn agba bọ wọn ni a kii ro kadun, ko sisi ẹni ti kii rẹ, se kẹnimani ara ko si, apọju rẹ ni ko sunwọn.

Gbajumọ oṣere tiata, Ọpẹyẹmi Ayeọla ti sọrọ sita lori ilera rẹ ati ipenija ti o n koju lori aisan to da a wolẹ ninu fidio kan to gbe soju opo ayelujara rẹ.

Ọpẹyẹmi Ayeọla ṣalaye loju opo Instagram rẹ pe, ọwọ rere ni ọdun 2022 fi bẹrẹ fun oun pẹlu oniruuru idokoowo to dantọ, ipe sawọn iṣẹ tiata loriṣiriṣi atawọn iṣẹ to mowo dani miran bẹẹ.

Amọṣa o ni oṣu keji n sun kẹrẹkẹrẹ wọle ni ipenija ilera de ba oun, ki Eleduwa to mu oun bori.

Ki lo se Opeyemi Ayeola to fi dubulẹ aisan:

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Nigba to n ohun to se to fi di ero ile iwosan, osere tiata naa ni lojiji ni esu gbe ise rẹ de, ti aisan naa si wọle wa.

Amọ o ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun to da si isẹlẹ naa, to si fun oun ni isẹgun ati idapada ilera oun.

O wa n kan saara si Oluwa ti o seun lori ilera rẹ naa, to si ni ko maa jọba lọ ninu aye oun nitori Ọlọrun ti kii se eniyan ni.

Ohun ti Opeyemi Aiyeola gbe soju opo Instagram rẹ

Oríṣun àwòrán, opeyemi_aiyeola1

Opeyemi Ayeola wa dupẹ lọwọ awọn ejika ti ko jẹ ki asọ bọ:

Ni kete ti ara le pada yii ni osere tiata naa n fi ẹmi imoore rẹ han si awọn eeyan to duro ti i, lasiko ti oju ogun le, ti aisan si da wolẹ.

Ko ṣai dupẹ lọwọ iya rẹ, ọkọ rẹ, awọn ọmọ atawọn mọlẹbi rẹ gbogbo, titi kan awọn akẹgbẹ rẹ lẹnu iṣẹ tiata fun aduroti wọn.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni nnkan bii oṣu kẹrin si ikarun ọdun 2021 ni iroyin kan pe, ara gbajumọ oṣere yii ko ya, o ṣi ogun lo fun ara rẹ ti o si daku rangbọdan.

Ta ni Opeyemi Ayeola:

Opeyemi Aiyeola, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogoji, jẹ gbajumọ osere tiata ni ede Yoruba, to si tun jẹ oludari ere pẹlu.

Ọdun 1998 lo darapọ mọ ere tiata, ọmọ bibi ilu Sagamu nipinlẹ Ogun nii se, amọ ilu Eko lo gbe dagba.

Ọmọ mẹta ni awọn obi Opeyemi bi, osu si ni ọmọ keji.

O se igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, Babatunde Olayiwola Owolomose, ti Ọba oke si fi ọmọkunrin meji ta wọn lọrẹ.

Gbajumọ osere tiata naa si ti gba ọpọ ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si n gbe ni Amẹrika pẹlu ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Kwara Hijab Crisi: Èdè àwọn Krìsítẹ́nì àti Mùsùlùmí kò yé ara wọn lórí lílo Hijab