Sylvester Oromoni: Onímọ̀ ìwàdìí míì ní àyẹ̀wò òkú Sylvester Oromoni tẹ́lẹ̀, kìí ṣe ojúlówó

Oríṣun àwòrán, Oromoni Family
Onimọ kan nipa ẹ̀yà ara, ti sọ fun ile ẹjọ pe ayẹwo ti wọn ṣe si oku Sylvester Oromoni, akẹkọọ Dowen College to ku, nipinlẹ Delta ni ọwọ magomago ninu.
Iroyin iku Sylvester di ilumọọka nigba ti ibatan rẹ kan fi si ori ayelujara pe àwọn akẹkọọ kan ni ile ẹ̀kọ́ Dowen College, ti ọmọ naa n lọ, lo lu u, nitori pe o kọ̀ lati darapọ mọ ẹgbẹ́ okunkun.
Àmọ́, awọn alasẹ ile ẹ̀kọ́ naa sọ pe irọ ni. Wọn ni ẹsẹ ni ọmọ naa sọ pe o n dun oun, lẹyin to farapa nibi ere bọọlu.
- Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nìyí nínú ìrọra kí ó tó kú, òní ni ọjọ́ ìbí rẹ̀!
- "Kí ló dé tó jẹ́ orúkọ ẹbí Kashamu nìkan lẹ mú bọnu nínú àwon ọmọ Marun ti Oromoni Jnr dárúkọ?"
- Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró rèé lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Sylvester Oromoni tí wọ́n ní àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ní Dowen College lù pa
- Wo ohun tí àwọn ọmọ Naijiria sọ lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College, Sylvester Onoromi
- Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú Sylvester Oromoni, akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College to ku l'Eko fún àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò 'Autopsy'
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
Eyi si lo mu ki ijọba ipinlẹ Eko gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii iku ọmọ ọdun mejila naa.
Ki lo sẹlẹ niwaju igbimọ oluwadii lọ́jọ́ Isẹgun?
Ọjọ kẹjọ, oṣù Keji, ni igbimọ oluwadii nipa iku Sylvester Oromoni joko ni agbegbe Ikeja.
Lasiko to n jẹri niwaju igbimọ naa, onimọ nipa ẹ̀yà ara lati ileewosan ìjọba, LASUTH, sọ pe ayẹwo akọkọ ti wọn ṣe si oku Sylvester nipinlẹ Delta, ko poju owo.
Dokita Soyemi sọ pe ẹni to kọkọ ṣe ayẹwo oku ọmọ naa, lati wadii nkan to pa a, ko ṣe daada.
O ni esi ti dokita naa fi sita ni pe kẹmika oloro lo pa Oromoni, ko poju owo to.
Soyemi ni sugbọn oun sakiyesi pe dokita naa ko la inú awọn ẹ̀yà ara ti ounjẹ ati afẹfẹ n gba wọnú ara.
- Àbùkù ńlá ni ikú Sylvester Oromoni jẹ́ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó- ìyàwó Gómìnà Sanwo-Olu
- Mi ò ní sin òkú ọmọ mi títí màá fi rí ìdájọ́ òdodo gbà, kò báà jẹ́ ọgbọ̀n ọdún - Baba Sylvester Oromono
- Wó ìgbésẹ̀ táwọn ọlọ́pàá gbé níwájú iléẹ̀kọ́ Dowen College tí Sylvester Oromoni tó kú lọ
- Gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú Sylvester Oromoni kò ní lọ láì jìyà lábẹ́ òfin - Buhari
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College márùn ún tó ń jẹ́jọ́ lórí ikú Sylvester Oromoni
- Mẹ́ta lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College tí Sylvester dárúkọ ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá - Kọmisanna ọlọpaa Eko
O salaye fun ile ẹjọ pe ti eeyan ba jẹ kẹmika, dandan ni ko gba ọna ti oúnjẹ n gba wọ inu ara.
"Ṣùgbọ́n ti a ko ba la àwọn ẹ̀yà ara yii, ko si ẹri pe kẹmika lo pa ọmọ naa."
Soyemi ni to ba jẹ pe dokita naa ṣe nkan ti oun sọ ni, tabi to ṣe odiwọn ẹ̀yà ara ti eemi n gba wọ agọ ara ọmọ naa, yoo ni abọ iwadii to jẹ ojulowo.
Dokita Soyemi sọ pe ọjọ kẹtala, oṣù Kejila, ọdun 2021, ni oun gba oku Sylvester, ni ileewosan LASUTH nipinlẹ Eko, ati pe niwaju onimọ ẹ̀yà ara meje ni oun ti pada ṣe ayẹwo oku ọmọ naa.
Agbẹjọro ẹbi Oromoni, Femi Falana tako nkan ti Dokita Soyemi sọ:
Sugbọn agbẹjọro to n soju ẹbi Oromoni, Femi Falana, sọ pe ọrọ ti Soyemi sọ ko nitumọ rara, nitori pe, ile ẹjọ ko tii bere esi ayẹwo oku ti Soyemi sọ̀rọ̀ nipa rẹ, gẹgẹ bi ẹri.
Agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Eko, sọ pe ko si nkan to buru ninu bi Dokita Soyemi ṣe sọrọ nipa esi ayẹwo ti wọn kọkọ ṣe si oku ọmọ naa.
O ni o ṣe pataki pe ko sọ ipo to ba oku naa nigba ti wọn gbe fun.
Lẹyin eyi ni alaga igbimọ oluwadii, Ọgbẹni Mikhail Kadiri gba ẹri ti Dokita Soyemi sọ wọle.
Dokita naa sọ pe kokoro aifojuri ninu ẹ̀dọ̀ ati ẹ̀dọ̀fóòró lo pa Sylvester.
Soyemi sọ pe ayẹwo ti oun ṣe tun fihan pe ọmọ naa ni kokoro aifojuri ninu kíndìnrín rẹ, ati ẹran to bo ọrùn ẹsẹ̀.
Awọn nkan yii lo si parapọ to ṣe okunfa iku Sylvester.
Ki ni nkan dudu ti wọn ba ninu lasiko ayẹwo akọkọ?
Ile ẹjọ ti sun igbẹjọ si ọjọ Kẹrinla, osu Keji.
Ki lo ti sẹlẹ sẹyin lori iku Slyvester Oromoni:
Iroyin iku Sylvester di ilumọọka nigba ti ibatan rẹ kan fi si ori ayelujara pe àwọn akẹkọọ kan ni ile ẹ̀kọ́ Dowen College, ti ọmọ naa n lọ, lo lu u, nitori pe o kọ̀ lati darapọ mọ ẹgbẹ́ okunkun.
Àmọ́, awọn alasẹ ile ẹ̀kọ́ naa sọ pe irọ ni. Wọn ni ẹsẹ ni ọmọ naa sọ pe o n dun oun, lẹyin to farapa nibi ere bọọlu.
Ijọba ipinlẹ Eko ti ile ẹkọ naa pa, ti ọpọ obi si n tara poro lori iku akẹkọọ naa.
Ijọba gbe igbimọ oluwadii kalẹ lati se ayẹwo iku to pa ọmọ ọdun mejila naa, ti onimọ iwadi akọkọ si ni awọn kẹmika kan ti wọn ri ni inu rẹ lo gba ẹmi rẹ.




















