Sylvester Oromoni: Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú Sylvester Oromoni, akẹ́kọ̀ọ́ Dowen College to ku l'Eko fún àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn àyẹ̀wò 'Autopsy'

Oríṣun àwòrán, Rapid response/facebook/other
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti gbe oku akẹkọọ ilee ẹkọ girama aladani Dowen College, Sylvester Oromoni ti iroyin kiri kale kako pe o jade laye nipasẹ lilu ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa kan lu u fun awọn obi rẹ lati lọ sin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekun Ajiṣebutu ṣalaye pe niwọn igba ti wọn ti pari awọn ayẹwo ti wọn fẹ ṣe lara oku akẹkọọ naa lati mọ iru iku to paa lo faa ti wọn fi jọwọ oku rẹ fun awọn ẹbi rẹ.
Ni ọjọ Aje to kọja ni wọn gbe oku Sylvester kuro ni ipinlẹ Delta wa si ipinlẹ Eko fun ayẹwo naa ni ileewosan kan.
- Wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ṣiṣẹ́ awakọ̀ "taxi" kó tó di ààrẹ
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
- Ìyàwó Timothy Adedoge ké gbàjarè lórí èsì àyẹ̀wò ikú tó pa ọkọ rẹ̀
- Ọkọ mi ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò pa ara òun, àmọ́ ẹbí kò ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí - Ìyàwó ọkùnrin tó bẹ́ sí odò ọ̀sà
Gẹgẹbi o ṣe sọ awọn igun marun un lo ni aṣoju lasiko ti ayẹwo fi waye lara oku Sylvester Oromoni: Awọn ẹbi rẹ, awọn ẹbi awọn akẹkọọ ti wọn fi ẹsun kan, awọn aṣoju ile ẹkọ naa, awọn oluwadii lati ileeṣẹ ọlọpaa, , ti awọn aṣoju ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko si ṣoju fun ijọba ipinlẹ Eko.
Nigba to di ọjọru ni wọn gbe oku rẹ pada si ipinlẹ Delta nii ti wọn yoo ti sinku rẹ.
Amọṣa o, ko tii si ẹni to lee sọ ohun ti esi ayẹwo oku ọmọdekunrin naa jẹ, bi o tilẹ jẹ pe iwaadi awọn ọlọpaa ṣi n lọ lọwọ lori rẹ.
Lara awọn iroyin to jade lori ohun to ṣokunfa iku Oromoni ni pe awọn marun lawọn akẹkọọ to luu nigba ti wọn gbiyanjuati faa wọ inu ẹgbẹ okunkun kan nibẹ.
Kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumoṣu ṣalaye lawọn ọsẹ diẹ sẹyin pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ lara awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan.













