Vladimir Putin: Ààrẹ orílẹ̀-èdè Russia wa ọkọ̀ "taxi" láti pèsè fún ìdílé rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoruba bọ, wọn ni ti a ba pé laye, a o jẹ ẹran to ju erin lọ.
Ojo si ti n pa igun bọ lati ọjọ to ti pẹ.
Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin lo sọ nipa bi o ṣe ṣiṣẹ awakọ gẹgẹ bi aṣekun iṣẹ nigba ti ọrọ aje Russia dẹnu kọlẹ lẹyin ti ijọba USSR wo lulẹ lọdun 1991.
Aarẹ Putin ranti bi USSR ti tuka pẹlu ẹdun ọkan.
- Àbọ̀dé Buhari: Ọ̀nà tí Turkey yòó gbà ràn wa lọ́wọ́ kójú ìṣòro àbò Nàìjíríià nìyìi
- Àmọ̀tẹ́kùn rápálá wọ àdúgbò láti bá ìdílé kan lálejò, Ọwọ́ òfin tẹ̀ ẹ́
- Lẹyìn tí UK yọ Nàìjíríà kúrò lórí ''red-list'', wo ìlànà tuntun t'ọ́mọ Nàìjíríà lè fi gba Visa
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
Putin ni nkan le koko lẹyin ti USSR wo eyi to mu ki ọpọ ọmọ orilẹede Russia wa iṣẹ kun iṣẹ ki awọ le ka oju ilu.
Putin ni bi USSR ṣe wo lulẹ ṣakoba fun Russia nigba naa.
Ọrọ ti Putin sọ yii le fa ibẹrubojo ni Ukraine pẹlu bi Russia ṣe ko nkan ijagun ologun si ibode laarin Russia ati Ukraine to wa lara orilẹ-ede USSR tẹlẹ.
Ọmogun ẹgbẹrun lọna aadọrun Russia lo wa ni eti ibode Ukraine, ẹru si ti n ba awọn eeyan Ukraine pe Russia le ṣe ikọlu si orile-ede naa.
Amọ, orilẹede Russia ti sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ .
Nigba to n sọrọ ninu fidio apilẹṣe kan lori ẹrọ amohunmaworan, Putin ni nkan o rọrun lẹyin ti USSR wo lulẹ.
"Mo ni lati wa ọna mii lati wa owo nipa wiwa ọkọ takisi.
Kii ṣe nkan to dun lẹnu lati maa sọ ṣugbọn ohun to ṣẹlẹ niyẹn.
Ọpọ eeyan ni ko lowo lati wọ ọkọ taksi gan an nigba naa.
Ọpọ eeyan lo maa n seranwọ fawọn eeyan ti wọn ba ri loju popo ti wọn yoo si gbe wọn ni ọfẹ tori aisowo niluu.
Awọn mii tiẹ maa n lo ọkọ ileeṣẹ bi anbulansi lati fi ṣe taksi gbero," Putin ṣalaye.
Ileeṣẹ ẹṣọ eleto abo ijọba USSR ki o to wo lulẹ.
Putin ni o fẹ jẹ wí pe gbogbo eeyan to ni ọkọ nigba naa lo maa n fi ọkọ wọn gbe ero bi takisi.













