Buhari fro Turkey: Ọ̀nà tí Turkey yòó gbà bá wa kójú ìṣòro nìyìi

Oríṣun àwòrán, Presidency
Gẹ́gẹ́ bi aarẹ Muhammadu Buhari ṣe rinrinajo lọ orilẹede Turkey to ti lọ ba wọn kopa ninu ipade pataki ti ibanidọrẹ ati idowopọ nilẹ Afirika, ọ̀rọ̀ abo Naijiria ko fara pamọ lẹnu aarẹ Buhari rara o.
Gẹ́gẹ bi Buhari ṣe sọ ọ, ibanidọrẹ laarin Turkey ati Naijiria yoo tubọ mu ilọsiwaju ba akitiyan mimu Naijiria wa ni abẹ abo to peye.
Nigba to n sọrọ nibi ipade to ṣe pẹlu akẹgbẹ rẹ ni Turkey, aarẹ Recep Tayyip Erdogan ki wọn to ṣide eto ipade apero naa, aarẹ Buhari ni Turkey ti ni ọpọlọpọ iriri nipa kikoju ipenija abo eyi ti Naijiria yoo si jẹ anfani nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Presidency
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Ṣé lóòtọ́ ni ọlọ́pàá Osun fẹ́ fi panpẹ́ mú ọmọ Adedoyin tó ni Hòtẹ́ẹ̀lì tí Timothy Adegoke kú sí? Ọ̀rọ̀ ń rùn bọ̀ o
- 'Lójú mi, ọmọ ìyá mẹ́fà jóná, ọkàn kú nínú iná gàásì nílùú Abuja'
- Arákùnrin kan r'ẹ́wọ̀n ọdún 24 he lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹlú ọmọ ìkókó
Aarẹ Buhari ati Aarẹ Erdogan ti wa pawọpọ ṣe adehun pe orilede Turkey yo ṣeranwọ fun orilẹede Naijiria lori iṣoro aabo to n koju eyi to n peleke sii lojoojumọ.
"Turkey ni iriri ojukoju nipa didoju kọ ipenija fun ọpọlọpọ ọdun eyi ti Naijiria si le jẹ anfani pupọ nibẹ".
O fi idaniloju han pe ibaṣepọ laarin orilẹede mejeji yii yoo tubọ maa gbooro sii fun oniruuru anfani to wa fun awọn mejeeji.

Oríṣun àwòrán, Presidency
Buhari ni inu oun dun si ọwọ iranwọ ti Turkey na si Naijiria lati ṣeranwọ ni ẹka aabo ati ipese alafia ni orilẹede Naijiria.
"Mo fẹ fi ẹmi imoore mi han fun ipe pataki lati wa fun ipade yii ati lati fi idunu mi han si iranwọ ti ẹfẹ ṣe lati koju ipenija to n doju kọ wa".
Aarẹ ni oun n reti abajade ipade ti awọn minisita orilẹede mejeji ti o si n fi aridaju han pe gbogbo nkan eleso ire ti wọn ba ba jade nibi ipade naa ni oun yoo fọwọ si.















