Stray leopard captured: Ọwọ́ tẹ àmọ̀tẹ́kùn tó rìn wọ inú àdúgbò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ẹranko ni Kenya ti mu amọtẹkun to rapala wọ inu ile kan ni Guusu ila oorun orilẹ-ede naa.
Ileeṣẹ iroyin Daily Nation ti ṣafihan fidio bi awọn oṣiṣẹ naa ṣe gbe amọtẹkun ọhun jade lati inu ile naa.
Iroyin ni o ṣeeṣe ko jẹ pe inu ọgba awọn ẹranko, Tsavo National Park, ni amọtẹkun ọhun ti jade ko to rapala wọ inu ile ọhun.
- Amotekun fi ṣìkún òfin mú okùnrin tó jí àwọn olùjọ́sìn gbé lásìkò ìṣọ́ òru
- DSS fún mi ní omi kẹ́míkà mu látìmọ́lé, mi ò gbádùn láti ìgbà náà, wọ́n lù mú gan an- Lady K
- Ọ̀kùnrin to tú àṣírí ohùn Olóyè Sunday Igboho lórí fóònù ti bọ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Àtúntò Nàìjíríà ni mo tò fún o, ìdí tí ẹ ṣe ní láti gbọ́ sí àwọn tó ń jà fún Yoruba Nation lẹ́nu rèé - Sẹnetọ Olujimi
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
Awọn eeyan adugbo naa ya a bo ile ti ẹranko naa wọ lasiko ti wọn n gbe jade nibẹ.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti ẹranko yoo wọ ile awọn eeyan lagbegbe naa.
Ṣaaju ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ẹranko ti kọkọ kede pe ki awọn araalu pe nọmba kan ti wọn ba kofiri ẹranko to ba n rin gbere-gbere kiri ladugbo wọn.
Ninu oṣu Keje ọdun yii, awọn oṣiṣẹ naa ri kiniun kan to n rin ladugbo kan ti ọpọ eeyan n gbe nitosi olu ilu orilẹ-ee naa, iyẹn Nairobi.
Ireti w ape wọn yoo da amọtẹkun naa pada si ibi ti wọn n ko ẹranko naa pamọ si laipẹ.














