Buhari: Oko ni mò ń padà sí lẹ́yìn sáà ìjọba mi lọ́dún 2023

Aarẹ Buhari ni oko rẹ̀ nilu Daura

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Mo n foju sọna wo ọdun 2023 pe bi mo ba pari saa iṣejọba yii, ki n pada lọ sile lati lọ tọju oko mi".

Aarẹ Muhammadu Buhari lo fi ọrọ lede lọjọ Ẹti ninu ọrọ to sọ lati ṣaami ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kọkandinlọgọrin rẹ pe ohun toun yoo ṣe lọdun 2023 niyẹn.

Aarẹ orilẹede Naijiria ni oko iudo maalu ni ilu ibi rẹ, Daura nipinlẹ Katsina ni iha Ila Oorun-Ariwa Naijiria.

"Mo n foju sun ọdun 2023 nigba ti mo maa pari saa mi lati pada lọ sile lọ tọju oko mi", eyi wa loju opo Facebook ti aarẹ́ Buhari fi sita lara ọna to gba ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ".

Aarẹ Buhari ni oko rẹ̀ nilu Daura

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán, Buhari gbọ faari

Eyi n waye lẹyin ti aarẹ lọ ṣepadape ibanidọrẹ orilẹede pẹlu aarẹ Tayyip Recep Erdogan ti orilẹede Turkey.

Gẹgẹ bi atjade ti awọn agbẹnusọ aarẹ fi sita lati ọfiisi rẹ, lẹyin ti wọn ṣe ayẹsi ranpẹ fun un lowurọ̀ lo tẹsiwaju lọ dari ipade eto kan pẹlu awọn ikọ to ba a lọ lati ibẹ lo si tun ti lọ fun ipade miran pẹlu akẹgbẹ rẹ, Erdogan ni Dolmabahce Palace.

"Mo ti ro pe mo maa yẹ ṣiṣe ayẹyẹ niwọn igba ti mi o si ni Abuja. Awọn ikọ ẹṣọ mi ti kọwe ranṣẹ si mi nipa ohun ti wọn fẹ ṣe lonii, iẹ la de bayii o.

Ni jina jina orilẹede Turkey, mi o tun ribi sa fun wọn".

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ

Aarẹ wa ṣeleri pe lati asiko yii titi di igba ti oun yoo kuro lori oye, oun yoo ṣa akitiyan oun lati ṣe ohun ti yoo tẹ ifẹ awọn araalu lọrun oun yoo si ṣe iṣẹ oun gẹgẹ bi ilana ofin orilẹede.

"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba fun ọjọ yii. Nibayii, iṣẹ n tẹsiwaju".

Iṣejọba aarẹ Muhammadu Buhari ti n ni ipenija abo to lagbara lati igba pipẹ ti wọn ṣe akitiyan lati bori rẹ. Boko Haram jẹ kan gbooki lara ipenija Naijiria paapaa ni iha Ila Oorun-Ariwa, ijijagbara Biafra naa n yọju ni iha Guusu-Ila Oorun to fi mọ ijinigbe lati gba owo ati ipaniyan kaakiri orilẹede.