Presidency: Ààrẹ Muhammadu tún ti rìnrìn àjò lọ sí Daura

Presidency: Ààrẹ Muhammadu tún ti rìnrìn àjò lọ sí Daura

Oríṣun àwòrán, Presidency

Ààrẹ Buhari Muhammadu tú ti rin ìrìn àjo ọlọ́jọ́ mẹ́rin lọ sí Daura ní ìpínlẹ̀ Katsina tó jẹ́ ìlú abínibi rẹ̀.

Ààrẹ kúro nílé ìjọba lọ́nìí ọjọ́ Ẹtì láti, pápákọ̀ òfurufú Umar Musa Yar'adua ni gómìnà ìpińlẹ̀ Katsina Aminu Masari ti kíi káàbọ̀.

Ìròyìn sọ pé, ààrẹ Muhammadu Buhari yóò kópa nínú ìfórúkọsílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) àti fífi han dájú pé ọmọ ẹgbẹ́ sì ni wọ́n, ètò yìí ni ààrẹ ti sọ sáájú pé ó ṣe pàtàkì fún ìṣejọba àwa ara wa Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Ilorin Conjoined Twins: Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó

Ilé iṣẹ́ ààrẹ nínú àtẹjáde tó fi síta, sàlàyé pé :"lásìkò tí ààrẹ bá wà ní Daura, yóò se àwọn peju sinbi ètò ìforúkọ sílẹ̀ ẹgbẹ APC"

" Ó yẹ kí ààrẹ Buahri padà dé sí ìlú Abuja ni ọjọ́ Iṣẹgun tó n bọ̀"

Ààrẹ Muhamadu Buhari ti rìnrìn àjò lọ sí Daura ní ọjọ́ kọkànla ọsu kejila ọdun 2020. Lásìkò yìí ni àwọn jànduku yabo ilé Ẹ̀kọ́ GSSS Kankara ti wọ́n sì jí akẹ́kọ̀ọ́ ọkunrin ọ̀ọ́dúnrún gbé ti wọn si túwọn sì padà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà nínú igbó kan ní ìpínlẹ̀ Zamfara