Transparency International: Nàíjíríà wà nípò tó burú jùlọ nínú ìwà àjẹbánu láti ọdún méjì sẹ́yìn

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Orilẹ-ede Naijiria ja walẹ síi ninu awọn orilẹ-ede ti iwa ibajẹ ti pọ julọ lagbaye.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ Transparency International fi sita, Naijiria lo wa ni ipo keji ninu awon orilẹ-ede ti iwa ibajẹ ti pọju lapa iwọ- oorun ilẹ Afrika.

Ajọ naa ṣalaye pe atẹjade ọhun fihan pe iwa ibajẹ ti buru si ni Naijiria ju ti atẹyinwa lọ.

Ajọ Transparency International ni ipo ti Naijiria wa bayii lo buru julọ laarin ọdun meji sí asiko yii.

Orilẹ-ede Guinea Bissau ni iwa jẹgudu-jẹra pọ sí julọ ni ẹkun ìwọ̀-oòrùn ilẹ Adulawọ.

Àkọlé fídíò, Ilorin Conjoined Twins: Àwọn òbí ìbejì tó lẹ̀pọ̀ ní ọ̀kàn àwọn bàjẹ́ láti rí ibèjì wọn tó

Naijiria ti wa ni ipo 149 bayii ninu orilẹ-ede 183 ti ajọ Transparency International ṣe agbeyẹwo wọn.

Orileede Sudan lo buru julọ ninu iwa ibajẹ nilẹ Afrika.

Somalia lo wa ni ipo keji nigba ti orilẹ-ede South Sudan ṣe ipo kẹta.

Amọ, orilẹ-ede Seychelles lo gba ipo kinni ninu awọn orilẹ-ede to ṣe daadaa julọ nilẹ Adulawọ.

Àkọlé fídíò, Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

Ki ni ero aarẹ Buhari lori ikede yii?

Ẹwẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe irọ nla ni iroyin ti ajọ Transparency International gbe jade nipa orilẹ-ede Naijiria.

Oluranlọwọ fun aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu lo fọrọ naa lede loju opo Twitter rẹ.

Ọrọ ti Garba Shehu sọ loju opo Twitter rẹ

Oríṣun àwòrán, @GarShehu

Shehu ṣalaye pe lai ṣe ani-ani, ijọba Aarẹ Buhari n ṣe aṣeyọri lori akitiyan lati gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria.

"Iroyin ti ajọ Transparency International gbe jade kudiẹ kaato, ati pe niṣe lo yẹ ki wọn gboriyin fun Buhari lẹyin to ti dẹkun iwa ibajẹ laarin awọn oṣiṣẹ ọba," Shehu lo sọ bẹẹ.

Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka

Wole Soyinka ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Wole Soyinka

Akọni onkọwe nni, Ọjọgbọn Wole Soyinka kede pe ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari n pin orilẹede Naijiria si yẹlẹyẹlẹ pẹlu ilana to n gba se ijọba rẹ.

Ọjọgbọn Soyinka sọrọ naa lori ẹrọ amohunmaworan kan nilu Eko l'Ọjọru.

"Laisi ani àní, orilẹede Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ, ijọba to wa lode yii lo si faa," Soyinka lo sọ bẹẹ.

Ọjọgbọn Soyinka wa di ẹbi gbogbo isẹlẹ yii ru ijọba Buhari nitori bi ijọba rẹ ṣe n ṣegbe lẹyin awọn ẹya kan ju awọn kan lọ.

Soyinka ni ijọba ẹlẹnu meji ni ijọba to wa lode, "ohun to ba ṣẹlẹ tabi ẹni to ba ṣẹlẹ si lo maa sọ bi ijọba Buhari yoo ṣe woo."

Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Wole Soyinka

Soyinka sọ pe ọpọ awọn ọrọ to n jade lati ileeṣẹ aarẹ buru jai, "ọrọ imọtara ẹni nìkan ni, koda o yẹ ki oju gba awọn to n sọ iru ọrọ bẹẹ ti, o si ti yẹ ki wọn dawọn duro lẹnu iṣẹ wọn tipẹ."

Ọjọgbọn Soyinka ni ko si ẹni to ni igbagbọ ninu ijọba yii mọ.

"O ṣeni laanu pe ọkan lara ohun ti ijọba to wa lode yoo fi silẹ lọ ni yii," Soyinka lo woye bẹẹ.

Ọjọgbọn Soyinka ni ijọba Buhari ko gbogun ti iwa ibajẹ kankan mọ, o ni iwa ibajẹ ti gbalẹ debi pe awọn ileẹjọ ko tete dajọ mọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

"Ọpọ eeyan lo yẹ ko ti dero ẹwọn ti ijọba yii ko baa tii maa kaarẹ lori igbogun ti iwa ibajẹ ni," Soyinka lo sọ bẹẹ.

Soyinka ni ọrọ ajọ EFCC ti oun n ṣe atilẹyin fun lati igba ti Nuhu Ribadu ti jẹ alága rẹ, naa ko ye oun mọ.

Ki ni ero awọn Afenifere ati ẹgbẹ mii lori ọrọ ti Wole Soyinka sọ?:

Ẹwẹ, ẹgbẹ ọmọ Yoruba, Afenifere ati ẹgbẹ to n ri si ọrọ awọn eeyan agbegbe Niger Delta, PANDEF, ti kin ọrọ ti Ọjọgbọn Wole Soyinka sọ lẹyin.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afenifere, Yinka Odumakin ni otitọ lọrọ tí Ọjọgbọn Soyinka sọ pẹlu awọn akiyesi rẹ naa.

Odumakin ni baṣu baṣu ni Aarẹ Buhari n ṣe ìjọba orilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

O ni ohun to ti ni loju ni pe, ijọba Buhari lo ṣe okunfa ede-aiyede ẹlẹyamẹya to n lọ lọwọ lorilẹede Naijiria bayii nipa ṣiṣegbe lẹyin awọn eeyan kan.

Bakan naa ni agbẹnusọ ẹgbẹ PANDEF, Ọgbẹni Ken Robinson kin ọrọ Soyinka lẹyin.

Ọgbẹni Robinson ni lootọọ ni pe ijọba Buhari ti pin Naijiria yẹlẹyẹlẹ eleyi to si ti fa ikunsinu bayii.

"Ọpọ ọmọ Naijiria lo da bi alejo to n ṣatipo nilẹ abinibi wọn, ẹya ati ẹsin ni ijọba fi n pin ipo," Robinson lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Pangolin Covid-19: Ẹ wo ẹranko tó ṣeéṣe kó ní ǹkan ṣe pẹ̀lú à[rùn Coronavirus!

O ni yatọ si awọn olori ileeṣẹ ọmogun ti Buhari ṣẹṣẹ yan sipo, awọn eeyan lati apakan orileede Naijiria lo wa nipo olori awọn ọmọ-ogun tẹlẹ.

Robinson ni eyi lo jẹ ki ọpọ gbagbọ pe Naijiria ti pin yẹlẹyẹlẹ ju igba ti ogun abẹle bẹ silẹ lọ.