Sani Abacha - Bí aṣe ṣe àwárí owó bílíọ̀nù tí olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí jí kó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ẹyin ti olori orilede Naijiria nigba kan ri Sanni Abacha ṣe jí ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu Nairia owo Naijiria tan lo gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra ko to bẹrẹ si ni naa owo to ji.
O le lo gun àwọn kan ni kẹsẹ inu lati maa ṣe awari ibi ti owo naa wa fun ọpọlọpọ ọdun
Ọkunrin ti wọn bẹ lọwẹ lati se awari owo naa sọ fun akọroyin BBC Clare Spencer bi iṣẹ naa ṣe gbakoso aye oun.
- Kọ̀ láti lo ìbòmú níta gbangba, ko fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura - Ìjọba àpapọ̀
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Nkan márùn ùn nípa Ọgágun Attahiru, òkúta tí Burati kọ̀ sílẹ̀, tó padà di igun ilé
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
Ni oṣu késan ọdun 1999 agbẹjọro ọmọ Swiss naaa Enrico Monfrini gba ipe to yi aye rẹ pada fun ogun ọdun.
" O pe mi laarin oru, o bere pe se mo le wa si yara oun nile itura , o ni nkan pataki to fẹ ba mi sọ. Mo ni 'ilẹ ti ṣu sùgbọ́n mo n bọ'
Ohun ti mo gbọ ni idakeji foonu lọhun jẹ ti eniyan pataki kan ninu ijọba ni Naijiria.
'Se o le se awari owo'?
Ọgbẹni Monfrini salaye pe aarẹ Naijiria nigba naa Olusegun Obasanjo lo ran ọkunrin naa wa si Geneva lati wa gbe iṣẹ naa fun , ṣiṣe awari owo ti Abacha ji lasiko to wa nijọba laarin ọdun 1993 titi di igba to ku lọdun 1998.
Gẹgẹ bi agbẹjọro, ọgbẹni Monfrini ti n ni ajọsepọ ni Naijiria lati ọdun 1980 to n ṣiṣẹ pẹlu awọnm oni Coffee, Cocoa àti awọn nkan miran
O ní oun fura pe awọn ti oun ba ṣiṣẹ yii lo tọkan oun si ijọba.
" O bere lọwọ mi: 'Se o le ri owo ki o si gbegi dina owo naa ? Se o le wa ọna bi owo yii yoo se pada si Naijiria?'
" Mo ni: 'bẹẹ ni. 'Sugbọn botilẹ jẹ pe mi o mọ bi iṣẹ naa ṣe lagbara to lasiko naa. Ati pe o ṣe pataki lati mọ nipa rẹ kiakia nitori naa eyi ni mo se."

Oríṣun àwòrán, AP
Lati bẹrẹ ile iṣẹ ọlọpaa Naijiria fun ni awọn koko nkan to yẹ ki o mọ nipa awọn apo ikowo pamọ ile ifowopamọ Swiss to jọ pe owo ti Abacha ati àwọn isọmọgbe rẹ ji gbe ni Naijiria. Ọgbẹni Monfrini kọ sinu iwe kan to se to pe akọle rẹ ni "Recovering Stolen Assets.
O ní àwọn ereefe iwadii ni awọn ọlọpaa gbe jade ninu oṣu kọkanla ọdun 1998 ti wọ sọ pe o le ni Biliọnu kan abọ dọla ni Abacha ji àti awọn ẹmẹwa rẹ ji ko.
'Dọla ti wọn n fi ọkọ ajagbe ko'
Ọkan lara ọna ti wọn gba lati ko aduru owo naa pamọ gbénutan, o si tini loju gidi, iwa ainitiju gidi ni.
Abacha yoo sọ fun awọn olubadamọran ki wọn bere fun owo ọrọ abo ti ko ni'tumọ.
Yoo wa buwolu ẹbẹ owo naa, àwọn olubadamọran naa yoo mu lọ si Banki apapọ Naijiria (CBN) ti wọn yoo si ko owo tabua fun wọn.
Owo yii ni awọn olubadamọran Abacha yoo ko lọ si ile rẹ
Koda nigba miran dọla ni wọn maa n gba owo naa ti wọn yoo si fi ọkọ ajagbe ko lọ si ile rẹ gẹ́gẹ́ bi Monfrini se kọ.
Ọna kan ree bi Ababcha ati awọn ẹmẹwa rẹ ṣe ko owo Naijiria to pọ to bẹẹ. Awọn ọna miran ni fifun awọn ọrẹ rẹ ni kọngila ti wọn yoo si bu owo gọbọi lee. Bakan naa ni wọn ni wọn maa bere owo iyebiye lọwọ awọn ile isẹ to ba fẹ da iṣẹ silẹ ni Naijiria ati aoniruuru owo ẹyin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bí ǹkan ṣe n lọ rèé fún ọdún mẹ́ta afi lójiji ti Abacha kú ni ẹni ọdún mẹ́rìnléláádọ́ta ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfa ọdún 1998
Bóya ó ti wá ni ààrun ọkan tẹ́lẹ̀ ni o tàbí wan fún ni majele jẹ, ààrín náà kò yénítorí pé kò sí ẹni tó ṣe àyẹwò ikú tó paá.
Abacha kú ko tó bẹ̀rẹ̀ sí ni ná owó tó kó pamọ, àwọn àsírí díẹ̀ nípa bnki tó n fowopamọ si ṣerànwọ́.
" Àwọn iwe ti wọ́n fún mi naka awọn nkankan to ran mi lọwọ fun mi ti mo fi mọ ibi ti awọn owo naa wa, ọrọ yii ni Monfrini sọ.
Lẹyin gbogbo asiri to wa lọwọ rẹ yii lo fi lọ ba agbẹjọro agba orilẹede Switzerland, ibẹ̀ si ni ọ̀rọ̀ ti niyanju.
Ọgbẹni Monfrini ri alaye ṣe lori ọrọ naa pe ẹbi àti àwọn ọrẹ Abacha pamọ pọ lati ja Naijiria lole ni.

Oríṣun àwòrán, AFP
Bayiìí ni agbéjọro àgbà orílẹ̀-ede naa ṣe fi ikede sita si gbogbo awọn Banki Switzerland pe ki wọn kede oruko apo ifowopamọ ti wọn si pẹlu orukọ Sani Abacha tabi apejẹ rẹ̀.
Laarin wakati mejidinlaadọta ìdámarundinlọgọrun baki lo ti fi orukọ awọn apo owo to jọ ti Abacha ati ẹbi rẹ jade.
Eyi si lo sina oniruuru banki miran lagbaye. Bi àwọn Banki yii ṣe n mu iwe ẹri wa, sí ọdọ agbẹjọro agba ni ẹmi naa n ṣe iṣẹ rẹ nitori ko ráye gẹ́gẹ́ bi Monfrini ṣe sọ fun BBC.
A ri owo ni Bahams Nassau Cayman Island wa lara awọn ilu miran ti wọn ti ri owo naa.











