COVID-19 Health Protection Regulations 2021: Ìjìyà ẹ̀wọ̀n àti owó ìtanràn ń dúró de ẹni tó bá tàpá sófin

Awọn eeyan to lo ibomu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Aarẹ Muhammadu Buhari fi buwọlu aba ofin eto ilera to n pese aabo lori arun Coronavirus tọdun 2021 nilu Abuja.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ilana to tuntun ninu ofin naa nitori ọpọ ilana to wa ninu rẹ lawọn eeyan ti n mu lo amọ atilẹyin ofin ti wa bayiii lati foju ẹni to ba tẹ ofin naa loju baile ẹjọ.

Gẹgẹ bi ofin isera ẹni naa ti salaye ni ori kẹrinlelọgbọn rẹ, ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ si ofin naa yoo san owo itanran tabi ko ri ẹwọn he tabi ko jiya mejeeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ofin naa tun mẹnuba asa tita kete sira ẹni, eyi ti gbogbo eeyan awujọ gbọdọ tẹle, wiwọ iboju, fifọ ọwọ loore koore, ko si jọwọ ara rẹ lati jẹ ki wọn se ayẹwo bi ara rẹ se gbona si.

Aarẹ Muhammadu Buhari n kọ iwe

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Bakan naa ni ofin yii ni ero to gbọdọ pejọ sinu ibudo kan ju aadọta lọ ayafi awọn ibudo ijọsin, bẹẹ si ni ero ibudo ijọsin naa ko gbọdọ gba ju ero idaji iye to yẹ ko lọ gba lọ.

Bakan naa ni ofin yii ro awọn ile ẹkọ, ile ifowopamọ atawọn ibudo ijọsin lagbara lati fidi ofin naa mulẹ, eyi ti yoo dena arun Covid-19

Ko tan sibẹ o, ẹsẹ nla ni fun ẹnikẹni to ba tapa si ofin yii, to si ro awọn agbofinro lagbara lati gbe iru ẹni bẹẹ, ko le foju wina iya ẹsẹ rẹ.

Ijiya ẹsẹ iru ẹni bẹẹ ni pe yoo san owo itanran tabi ko fi ẹwọn osu mẹfa jura tabi ko se mejeeji papọ.