Insecurity in Nigeria: Lára àwọn tí agbébọn jí gbé ni ọ̀dọ́ 25 tó ń ti ayẹyẹ ìgbeyàwó bọ̀ ní Taraba

Oríṣun àwòrán, @crimefightersng
Awọn ajinigbe gba owo yari lọjọbọ lorilẹede Naijria, ti wọn si sọsẹ ti ko lonka kaakiri awọn agbegbe kan.
Lẹyin isẹ ibi wọn ọhun, eeyan marundinlọgọrin lo sun ni akata awọn ajinigbe naa lalẹ Ọjọbọ, ti wọn si ran eeyan mejidinlogun sọrun ọsan gangan.
Nipinlẹ Niger, ko din ni aadọta eeyan ti wọn ji gbe ni idaji ọjọbọ nigba ti awọn janduku naa gba ijọba lagbegbe Bussa, to wa ni ijọba ibilẹ Shiroro.
- Ó wù mí kí ń padà sí Igangan, tí wọn bá fún mi láàyè - Seriki Fulani
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
- 'Bí a ṣe rí ibi ti ọ̀gágun olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ti kú kówó pamọ́ sí.'
- Ewu ń bẹ pẹ̀lú kíkó Amotekun lọ Ibarapa lórí ọ̀rọ̀ Fulani - Baajigan Ilaji Ile
- Sunday Igboho ṣọ́ra ṣe, jẹ́ kí Seyi Makinde ṣiṣẹ́ tí òfin gbé le lọ́wọ́ - Ooni Ife
- Ẹlẹ́nu méjì ni ìjọba Buhari, òun ló ń pín Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ - Wole Soyinka
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
Bakan naa, eeyan mẹsan lo jẹ Ọlọrun nipe nidaji ọjọbọ nigba tawọn atilawi yii tun kọlu abule Sarki Sheme nipinlẹ Katsina.
Bakan naa nipinlẹ Taraba, awọn ọdọ mẹẹdọgbọn, ti wọn n ti ayẹyẹ igbeyawo bọ ni wọn ji gbe loju ọna Wukari si Takum,
Awọn janduku naa tun sọsẹ nijọba ibilẹ mẹta ọtọọtọ nipinlẹ Kaduna, ti wọn si pa eeyan mẹrin, to fi mọ ọkunrin meji ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa.
Nipinlẹ Delta, awọn agbebọn naa tun pa eeyan marun mii nijọba ibilẹ guusu Warri.
Gbogbo awọn isẹlẹ naa lo si n waye ni ọjọbọ, ti awọn olori tuntun fawọn ẹka ileesẹ alaabo lorilẹede Naijiria n wọ isẹ lẹyin iyansipo wọn.
Sọọṣi ni wọn ti ji mi gbe, ki wọn to ta mi fawọn ajinigbe - osisẹ aj NIS

Oríṣun àwòrán, Bridget Esene
Agbẹnusọ fun ileesẹ to n ri si wọle-wọde awọn eeyan ni Naijiria, NIS, ẹka ti ipinlẹ Edo, Arabinrin Bridget Esene ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ awọn ajinigbe.
Esene ṣalaye pe, awọn ajinigbe ọhun fẹ gbẹmi oun tẹlẹ ni, kí wọn to ta oun fawọn afurasi Fulani darandaran.
Agbẹnusọ ajọ NIS naa sọ pe, awọn ajinigbe agbebọn marun un ọhun tẹle oun titi ti oun fi wọ inu ṣọọṣi, nibi ti won ti ji oun gbe niluu Benin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wò ó bí Afọnja ṣe finú wénú pẹ̀lú Fulani ní Ilọrin títí tó fi jẹ iwọ
- Àwọn ọ́ba yari mọ́ gómìnà Abiodun lọ́wọ́ lórí ìwé ẹ̀hónú nípa darandaran tó pòórá
- Ògo ilẹ̀ Yorùbá ní Sunday Igboho jẹ́, ẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ìràwọ rẹ̀ wọlẹ̀ - OPC
- Àwọn olóṣèlú ti ń fowó bẹ̀ mí kí n má bá Fulani jà torí ìbò 2023, àmọ́ o ti bọ́ - Sunday Igboho
- Àwọn jàǹdùkú yìnbọn sókè lọ́pọ̀ ìgbà kí wọn tó jó ilé Sunday Igboho - Ọlọ́pàá Oyo
- Sunday Igboho kò lẹ́tọ̀ọ́ láti lé Fulani nílùú, wọ́n sì le pè é lẹ́jọ́ - Femi Falana
"Wọn fi tipa tipa gbe mi sinu ọkọ wọn, ti wọn si gbe mi lọ lati inu ṣọọṣi, lẹyin naa ni wọn ta mi fawon ajinigbe miran," Esene ṣalaye.
Oṣiṣẹ ajọ NIS ni ohun ti oju oun ri lakata awọn ajinigbe, oun ko gbàdúrà rẹ fun ọta oun gan an.
Arabinrin Esene ṣalaye pe, oun gbiyanju lati sa asala fun ẹmi oun, amọ ibọn lawọn ajinigbe ọhun fi ṣẹburu oun.
Esene ni lẹyin ti oun lo ọjọ meji lakata awọn ajinigbe ninu igbo, lawọn ọlọpaa ati awọn fijilante doola ẹmi oun.
'Àǹfààní ńlá ni yóò jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria tí a bá ta dúkìá ìjọba'

Oríṣun àwòrán, Twitter/Buhari
Minisita eto iṣuna, Zainab Ahmed ti sọ pe yoo ṣe awọn ọmọ Naijiria lanfani ti ijọba apapọ ba ta awọn dukia rẹ kan.
Zainab lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ telefiṣọn abẹle Channels.
Minisita naa ṣalaye pe ọpọ awọn dukia ati ileeṣẹ ijọba lo ti dogun ti ko si wulo fun ara ilu, o ni anfani nla ni yoo jẹ f'awọn eeyan ti ijọba ba ta irufẹ awọn dukia bẹẹ.
- Lawal Ayankemi Oluwatoyin: Mo kọ̀ láti máa tọrọ owó nítorí ojú mi tó fọ́, iṣẹ́ ló wù mí
- Sunday Igboho wà lọ́nà Ibarapa, Seriki Fulani ní àwọn kó níbiì lọ, àrọ̀wà ló kù
- Ọlọ́pàá àti sọ́jà kó sí akóló ọlọ́pàá l'Ondo lórí ẹ̀sùn ìdigunjalẹ̀
- Ìyàwó Zakzaky lùgbàdì covid-19 lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, IHRC rọ Buhari kó tú òun àti ọkọ rẹ̀ sílẹ̀
Zainab ni "Awọn dukia ijọba kan wa to ti doku ṣugbon a le ta wọn fun awọn onileeṣẹ aladani ti owo to ba jade lati ibẹ yoo si wulo fun awọn ọmọ Naijiria."
"Mo wa lara igbimọ to n ri si tita awọn awọn dukia ijọba, a si ti n wo awọn dukia kọọkan ti ijọba ko le bojuto ki a le ta wọn fun awọn aladani."
Ọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2020 ni Zainab kede pe ijọba n gbe igbesẹ lati ta awọn dukia rẹ kan ko le fi owo rẹ kun owo eto iṣuna ọdun yii ti iye rẹ jẹ N13.58 tiriliọnu.
Minisita naa ṣalaye pe tita awọn dukia ọhun kii ṣe lati fi owo rẹ kun eto iṣuna ọdun 2021 nikan, ṣugbọn o jẹ lati sọ awọn dukia naa ji ko si wa ni ikawọ awọn aladani ti yoo lo fun anfani gbogbo ọmọ Naijiria.
- Wo àwọn sinimá mẹ́wàá tó gbé sinimá Yorùbá sáyé
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Ẹ̀yin èèyàn ìpínlẹ̀ Oyo, mìmì kan kò lè mì yín lónìí- Makinde
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Buhari buwọ́lu bílíọ̀nù N6.45b láti dá ibùdó afẹ́fẹ́ gáàsì sílẹ̀ fún ìtójú àwọn alárùn covid-19
- Ọkùnrin kan dèrò ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tó jí aago ọwọ́ tí iye rẹ̀ tó ₦33.8 mílíọ̀nù
O fi kun pe ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati ta awọn dukia to ti d'oku ni abala kinni ọdun 2021.
Ẹwẹ, ẹgbẹ ajafẹtọ, SERAP, ti ke si ile igbimọ aṣofin l' Abuja lati ma faye gba ijọba lati ta awọn dukia naa.
SERAP sọ pe kaka ki ijọba ta dukia rẹ, ni ṣe lo yẹ ko wa ọna lati din eto iṣuna ọhun ku, bii ṣiṣe adinku si iye owo oṣu ti awọn to wa ni ijọba n gba.


















