Sunday Igboho: Oba Ogunwusi rọ Igboho láti máṣe dá òfin ṣe lọ́wọ́ ara rẹ̀

Ooni ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi

Ooni tilu Ile Ifẹ, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi naa ti da si ọrọ Sunday Igboho atibo se lọ fun awọn afurasi ọdaran Fulani ni gbedeke lati ko aasa wọn kuro lagbegbe Ibarapa.

Oba Ogunwusi gbe imọran yii kalẹ lasiko to n kopa lori eto ori mohunmaworan kan nilu Eko laarọ Ọjọbọ.

Ooni, ẹni to rọ Sunday Igboho lati mase da ofin se lọwọ ara rẹ, tun salaye pe ajijagbara naa ni ẹtọ labẹ ofin lati sọrọ sita lorukọ awọn eeyan ti iya n jẹ.

Amọ ọba alaye naa gba Igboho niyanju lati jẹ ki gomina ipinlẹ Oyo atawọn alasẹ yoku se ojuse wọn nidi kikoju ipenija eto aabo to n ba ipinlẹ naa finra.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

"Ẹ jẹ ka sọ tootọ, Igboho lo n gba ẹnu awọn mẹkunnu sọrọ. O jade sita, gbogbo eeyan si n gbọ ọrọ to sọ amọ imọran mi si gẹgẹ bi ọba alaye ni pe ko sọra se.

Awọn oloselu le gba ijijagbara yii mọ lọwọ, eyi to le mu ewu dani fun."

Ooni tun fikun pe Sunday Igboho ti se daadaa, ti gbogbo eeyan si n kan saara si fun iwa akọni to hu amọ ko gbọdọ maa da ofin se laaye ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho fulani ultimatum: Àwọn ará Kebbi àti Zamfara ló n jínígbé ní Oke Ogun- Serik

"A ni gomina nipinlẹ naa, ẹni ti ipese eto aabo to peye gberu julọ, bẹẹ ni aarẹ Buhari ti ransẹ si lati wa foju kan oun.

Nitori naa, o yẹ ki Igboho gba awọn eeyan ti wọn yan sipo asẹ laaye lati se ohun to tọ nitori iwọntunwọnsi ni ohun gbogbo yẹ.

Buhari ṣèpàdé pẹ̀lú Ọọni, Makinde, Akeredolu lórí àwọn darandaran nílẹ̀ Yorùbá

Fulani herdsmen: Buhari ṣèpàdé pẹ̀lú Ọọni, Makinde, Akeredolu lórí ọrọ ètò àbò nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Punch

Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ipade pọ pẹlu Ooni Ile Ife, Oba Enitan Ogunwusi lori aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ilẹ Yoruba at'awọn darandaran.

Oluranlọwọ Ooni ṣalaye fawọn akọroyin pe Kabiyesi ṣalaye fun Aarẹ Buhari iha ti awọn lọbalọba ilẹ Yoruba kọ sí ọrọ naa.

Gẹgẹ bi amugbalẹgbẹ Oba Ogunwusi ti ṣalaye fáwọn akọroyin, Ooni sọ fun Buhari nipa ijamba tawon darandaran n ṣe nilẹ Yoruba.

Fulani herdsmen: Buhari ṣèpàdé pẹ̀lú Ọọni, Makinde, Akeredolu lórí ọrọ ètò àbò nílẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, Punch

Bakan naa ni Kabiyesi tun sọ fun Buhari igbesẹ ti awọn lọbalọba ti gbe lati ri pe alaafia jọba.

Ipade miiran yoo tun waye laarin Ọọni ati Aarẹ Buhari.

Ẹwẹ, Aarẹ Buhari tun ṣepade pọ pẹlu Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ati Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu lori ọrọ kan naa.

Laipẹ yii ni ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho sọ fawọn Fulani to wa lagbegbe Ibarapa nipinlẹ Oyo pe ki wọn kuro lori ilẹ Oyo lori ẹsun ijinigbe ati ipaniyan.

Àkọlé fídíò, Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

Lẹyin naa ni Igboho toun tero lẹyin rẹ lọ yabo ibugbe awọn Fulani gẹgẹ bi o ṣe sọ eleyi to da rogbodiyan silẹ.

Lẹyin aawọ yii lawọn janduku kan lọ fi ina Si ile Igboho to wa lagbegbe Soka n'Ibadan.

Bakan naa, Gomina ipinlẹ Ondo ti fawọn darandaran to wa ninu Igbo ijọba pe ẹnikẹni ti ko ba forukọsilẹ pẹlu ijọba gbọdọ fi igbó naa silẹ laarin ọjọ méje.

Ọrọ yii lo mu ki ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Miyetti Allah ṣepade pọ pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba lọjọ Iṣẹgun.

Ẹwẹ, Aarẹ Buhari tun ṣe ìpàdé pẹlu awọn olori awọn ileeṣẹ ologun mẹrẹrin to ṣẹṣẹ yan sipo.

Olori ologun, Maj-Gen Leo Irabor, olori ọmogun oriilẹ, Maj-Gen Ibrahim Attahiru, olori ọm'ogun oju omi, R.Admiral A.Z Gambo ati olori ọm'ogun ori afẹfẹ, Air-Vice Marshal I.O Amao, gbogbo wọn lo peju síbi ipade ọhun.